Boko Haram ti gboró, bàálù Drone ló ń lò láti kọlu aráàlú ní Borno - Aṣojú-ṣòfin

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ahmed Jaha, ọmọ ile gbimọ aṣoju-aṣofin ti jẹ ko di mimọ pe ado oloro ofurufu ni ikọ agbebọn Boko Haram n lo fi kọ awọn eeyan ati agbegbe ipinlẹ Borno.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), to n soju ẹkun ijọba Damboa/Gwoza/Chibok nipinlẹ Borno lo ṣo eyi lọjọ Isẹgun nigba to ti aba ti Ọnarebu Ahmad Satomi gbe wa si ile igbimọ lori ikọlu to waye ni Giwa barracks ati bi ikọlu ṣe n waye lorekore nipinlẹ Borno ati Yobe.

Jaha ni awọn ohun ija to wa lọwọ awọn agbebọn Boko Haram ju eyi to wa lọwọ awọn ọmọ Ologun Naijiria lọ.

"Ni awọn apa ibi kan ni agbegbe mi, Boko Haram ṣekupa eeyan mẹwaa ti wọn jẹ agbẹ, ti eeyan marun un mii si di await, eeyan mẹta miiran wa ni ile iwosan bayii.

"Ni Chibok, awọn agbebọn yii kọlu agbẹ mẹrinla ni ilu wọn.

"Mo ti padanu ọpọ awọn eeyan mi sọwọ Boko Haram pẹlu ado oloro ofurufu. Ẹ jẹ ka mọ eyi.

"Wọn n lo ado oloro ti ileeṣẹ Ologun Naijiria gan an ko ri lo. Ohun t imo n sọ ni pe Boko Haram ni ohun ija to lagbara ju ti ileeṣẹ Ologun lọ," o ṣalaye.

Aṣofin naa ṣekilọ pe Boko Haram ti n ni agbaara ju ti ileeṣẹ Ologun lọ nipinlẹ Borno, ti eyi si n fa ọpọ ibẹru boju ju ti tẹlẹ lọ.

"Boko Haram, ISWAP tabi eyikẹyi orukọ ti ẹ ba pe wọn, wọn n pada bọ.

"Ẹ jẹ ka gbe igbesẹ nla lati ma jẹ ohun to ti waye tẹlẹ tun waye, Boko Harma gba akoso ijọba ibilẹ mejilelogun ninu mẹtadinlọgbọn.

Jaha ni ọpọ awọn irinsẹ ija Ologun ni ko yẹ ki wọn ma lo mọ lati koju awọn agbebọn.

O fikun pe ijọba ko n ohun to yẹ lati koju ija kọ awọn agbegbọn pẹlu bo ti jẹ pe wọn ya ọpọ owo sọtọ fun ileeṣẹ Ologun.

"Laarin ọdun 2016 si 2019, ijọba Naijiria tin a apapọ owo to jẹ trilọnu mọkandinlogun lori eto aabo."