Baálẹ̀ Yemi Ogunyemi, Baálẹ̀ Oluyole àti àgbà ọ̀jẹ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, jáde láyé

Baalẹ Yemi Ogunyemi

Oríṣun àwòrán, Yemi Ogunyemi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ ti o tun jẹ Baalẹ agbegbe Oluyọle nilẹ Ibadan, Oloye Yẹmi Ogunyẹmi, ti jade laye.

Ọjọ Iṣẹgun, tii ṣe ọjọ kẹfa oṣu Karun ni olokiki agbohunsafẹfẹ naa re iwalẹ aṣa lẹyin ailera oṣu meloo kan.

Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe, DSP Wale Ogunyẹmi ṣe alaye fun BBC Yoruba pe lati bii oṣu meloo kan sẹyin ni Oloye Ogunyẹmi ti n ṣe aisan.

O ni gbogbo ipa si ni awọn sa lati doola ẹmi baba awọn nipa gbigbe wọn lọ si ile iwosan.

Wale Ogunyemi ni amọ aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se, ninu igbiyanju wọn lati doola ẹmi rẹ si ni ọlọjọ ti de ba a nile iwosan UCH to n bẹ nilẹ Ibadan.

Oloogbe Yemi Ogunyemi n seto lori afẹfẹ gẹgẹ bii Baalẹ nigba aye rẹ

Oríṣun àwòrán, Yemi Ogunyemi

Ọmọ oloogbe sọrọ nipa ohun to pa baba rẹ, Yemi Ogunyemi

DSP Ogunyẹmi ni, "Abiyamọ tootọ to nifẹ ọmọ ni baba wa.

O si ko gbogbo ẹbi ati araalu mọra, eeyan takuntakun ati eeyan daadaa ni baba wa.

Ki Ọlọrun fi ori jin wọn, a o ṣe afẹri wọn lọpọlọpọ"

Lati igba ti iroyin ipapoda Baalẹ Yemi Ogunyemi naa ti lu sita ni ọkanojọkan ariwisi ti n waye lori itakun ayelujara.

Ọpọ awọn ololufẹ wọn si lo n fi aworan wọn lede, ti wọn si n kọ oriṣiriṣi ọrọ ibanikẹdun.

Lara wọn ni Ademọla Babalọla ti o jẹ alaga ẹgbẹ akọroyin, NUJ ipinlẹ Ọyọ.

Eto ‘Ẹ n ba laya’ ati ‘Agbọrandun’ lo sọ Yemi Ogunyemi di olokiki lẹnu iṣẹ igbohunsafẹfẹ lọpọ ọdun sẹyin

Ni gbogbo ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun ni Oloye Ogunyẹmi maa n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi.

Saaju ọrọ oye jijẹ, iṣẹ igbohunsafẹfẹ ati atọkun eto gan an ni Oloye Ogunyẹmi yan laayo.

Ọkan gboogi lari awọn eto to sọ Oloogbe naa di olokiki lẹnu iṣẹ igbohunsafẹfẹ ni eto kan ti wọn pe ni 'Ẹ Ń BÁ LÁYÀ' nile iṣẹ tẹlifisan NTA ilẹ Ibadan ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Bakan naa ni Oloye Ogunyẹmi tun jẹ atọkun eto kan ti wọn pe 'AGBỌRANDUN' nibi ti wọn ti n yanju oriṣiriṣi aawọ.

Yatọ si eto ṣiṣẹ lori afẹfẹ, Alagba Ogunyẹmi fi igba kan jẹ alakoso NTA ilu Ọyọ nigba aye wọn.

Awọn si ni igbakeji aarẹ awọn Baalẹ ilẹ Ibadan titi ti ọlọjọ fi de.