Àlàyé rèé lórí ìdí tí aáwọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ṣe ń le koko sí, bí igun Abure àti Usman se dojú ogun kọ ara wọn

Julius Abure, Nenadi Usman àti Alex Otti

Oríṣun àwòrán, Julius Abure/Nenadi Usman/Alex Otti

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kàkà kí ewé àgbọn nípa aáwọ̀ tó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour dẹ̀, ko ko ko ló tún ń le sí i.

Ìdí ni pé igun ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour kan, tí Julius Abure ń darí, ti kéde pé oun ti ní ki gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti àtàwọn márùn-ún míì lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná.

Àwọn míì tí igun Abure náà tun ní kí wọ́n lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná ni Sẹ́nétọ̀ Ireti Kingibe, Darlington Nwokocha, Victor Afam Ogene, Amobi Ogah àti Seyi Sowunmi.

Wọ́n ní ìgbésẹ̀ yìí ń wáyé lẹ́yìn ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí tí ìgbìmọ̀ aláṣẹ náà gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kejì, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 láti ṣe ìwádìí ìwà ṣèyìí-ṣọ̀hún táwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà ń hù.

Wọ́n ní ohun tí ìrọkún nílé yìí túmọ̀ sí ni pé àwọn èèyàn náà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fi ara wọn hàn tàbí ṣe ohunkóhun ní orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn mọ́.

Àtẹ̀jáde tí àkọwé ẹgbẹ́ ikọ̀ náà fi síta pé àkíyèsí àwọn iléeṣẹ́ tó fi mọ́ egbẹ́ pawọn gómìnà, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, àjọ INEC àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sí ìgbésẹ̀ náà.

Ikọ̀ náà lábẹ́ ìdarí Abure ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn pé ikọ̀ tí Nenadi Usman ń darí, ń ṣe ìwádìí ìwà àjẹbánu nígbà tó jẹ́ pé Usman fúnra rẹ̀ ṣì ń jẹ́jọ́ ìwà àjẹbánu lọ́dọ̀ àjọ tó ń rí ìwà jẹgúdújẹrá ní Nàìjíríà, EFCC.

Àtẹ̀jáde náà àwọn kò mọ Nenadi Usman, tó figbà kan rí jẹ́ mínísítà fún ètò ìsúná Nàìjíríà, bí i ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party.

Ó ní "ó máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fáwọn ọmọ Nàìjíríà àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ tọkàntọkàn pé orúkọ Nenadi Usman kò sí nínú orúkọ tí ẹgbẹ́ ní kí wọ́n lọ rọ́kún nílé. Àkọ́kọ́, a ti sọ́ lọ́pọ̀ ìgbà pé Nenadi Usman kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ Labour Party nítorí kò ní káàdì ẹgbẹ́ lọ́wọ́.

"A mọ̀ pé ọmọ ẹgbẹ́ Obidient Support Group, tó ṣiṣẹ́, yó ṣì tún ń ṣiṣẹ́ fún olùdíje ààrẹ fẹ́gbẹ́ wa lásìkò ìbò ọdún 2023. A ò ní fòfin kankan nítorí kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́.

"Nenadi Usman kò ní ipa kankan láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tàbí sọ̀rọ̀ lórí ìwà àjẹbánu."

Abure yan ìgbìmọ̀ olùwádìí láti ṣe ìwádìí àwọn ìwà ṣèyìí-ṣọ̀hún tí wọ́n fi kan gómìnà Alex Otti àti olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party níbi ètò ìdìbò ọdún 2023.

Yé pa ara à rẹ ní alága Labour Party mọ́, ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ti ní sáà rẹ ti parí - ikọ̀ Nenadi Usman fèsì

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, ikọ̀ aláṣẹ tí Nenadi Usman ń darí náà ti gbé ikọ̀ kan dìde láti ṣe ìwádìí àkókò tí Julius Abure lò gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Ikọ̀ ti Usman, tí Alex Otti àti Peter Obi faramọ́, ti fún Abure ní ọjọ́ méjì láti yé pe ara rẹ̀ ní alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party mọ́ nítorí sáà rẹ̀ ti parí.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú nílùú Abuja, Usman jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fòpin sí àwọn ìgbésẹ̀ Abure láti dá wáhàlá sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà ṣááj'ètò ìdìbò ọdún 2027.

Ó ní òun rò pé pẹ̀lú ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹrin, oṣù Kẹrin, tí wọ́n ti fòpin sí sáà Abure, yóò mú Abure ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ tuntun lójúnà àti mú àtúntò àti ìlọsíwájú bá ẹgbẹ́ àwọn.

Ó fi kun pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé káká kó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́, Abure ṣì ń pe ara rẹ̀ ní alága, tó sì ń ba àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ bíi Otti àti Obi lórúkọ jẹ́.

Ó wòye pé àwọn ìgbésẹ̀ Abure yìí kò kàn jẹ́ títẹ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ lójú mọ́lẹ̀ nìkan, ó ní ó ń kó ẹrẹ̀ bá ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn.

Bákan náà ní ikọ̀ Usman ní àwọn ní ìgboyà nínú gómìnà Alex Otti àti Peter Obi lòdì sí nǹkan tí Abure ń sọ nípa wọn.