Kí ló ń fa ìwà ìṣekúpa ẹnìkejì ẹni tó ń wáyé lójúmọ̀ ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, KANO POLICE COMMAND/FACEBOOK
Ọpọ agbegbe ni apa ariwa orilẹede Naijiria ni wọn n la ohun to kọja oye wọn lọ lasiko yii pẹlu bii iroyin nipa iṣekupani ṣe gbode.
Pupọ ninu awọn iṣẹlẹ yii lo wa lati ọwọ mọlẹbi awọn oloogbe.
Ipinlẹ Jigawa, Kano ati Bauchi ni ọpọ awọn iṣẹlẹ yii ti waye ti ibeere kan si n jẹyọ lẹnu awọn araalu pe ki gan an lo n ṣẹlẹ?
BBC ṣe akojọpọ awọn iṣẹlẹ yii to waye laarin oṣu kan ni awọn ipinlẹ wọnyii.
Iyawo to ṣekupa ọkọ rẹ nipinlẹ Kano
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano ti tẹ iyawo kan to ṣekupa ọkọ rẹ lọjọ Isẹgun to jẹ ọjọ Kẹsan an lẹyin igbeyawo wọn.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede, Saudat Jibril, ẹni ọdun mejidinlogun gun ọkọ rẹ, Salisu Idris, ẹni ọgbọn ọdun lọbẹ ni aya.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Faraw ani ijọba Tarauni nipinlẹ Kano.
"Iṣẹlẹ naa waye ni ago mejila ooru ni ọjọ Kẹfa oṣu Karun un nigba ti afurasi naa gun ọkọ rẹ ni ọbẹ ni aya," SP Kiyawa ṣalaye
Iku ọkurin kan ti wọn ṣekupa ni owurọ
Ni ipinlẹ Kano kan naa, ileeṣẹ ọlọpaa kede iku ọkunrin Ọgbọn ọdun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Shehu Muhammad ni agbegbe Danbare.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, SP Abdullahi Haruna Kiyawa ni afurasi meji lo ṣadede yawọ ile oloogbe naa lọjọ Isẹgun, ti wọn si bẹrẹ si ni ma saa lada pa.
Ọkan ninu awọn afurasi naa, Aliyu Umar, ẹni Ogun ọdun, ni ọwọ tẹ pẹlu ada lọwọ rẹ.
Iwe iroyin Aminiya ni awọn afurasi naa yawọ ile oloogbe lasiko to n gbaradi fun irun owurọ.
Ọwọ tẹ ọkan lara awọn afurasi naa, ti wọn si fa le ileeṣẹ ọiọpaa lọwọ.
Ọmọ to ṣekupa Baba ni Gwaram
Ni ọjọ Aje, ọjọ Karun un, oṣu Karun un, ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ ẹni Ogun ọdun, Muhammad Salisu lẹyin to kọlu Baba rẹ pẹlu ada.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Jigawa, Lawan Shiisu Adam ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Bakin Kasuwa ni ijọba Gwaram.
Gẹgẹ bii o ṣe sọ, awọn Dokita kede iku Mallam Salisu Abubakar ni ile iwosan to w ani Birnin Kudu.
Oloogbe naa lo jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta
Iku alaga ijọba ibilẹ
Ni ọjọ Keji oṣu karun un, ileeṣẹ ọlọpaa Bauchi kede iku baba ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin, Mallam Isa Muhammad Wabi.
Ileeṣẹ ọlọpaa tọka iṣẹlẹ si awọn ọdọ kan to kọlu baba naa, ti wọn si lu ni alubami ni agbegbe Fadaman Mada nipinlẹ Bauchi.
Ọlọpaa ni awọn ọdọ to kọlu Mallam Isa Wabi lo jẹ ọrẹ Abdulgafer Is Mohb, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to jẹ ọmọ oloogbe
Ọkọ to ṣekupa iyawo rẹ
Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin, iyawo aṣẹsẹ gbe kam padanu ẹmi rẹ sọwọ ọkọ to fi tipatipa fẹ gẹgẹ bii aya ni agbegbe Tung oni ijọba ibilẹ Sule Tankarkar .
Ọlọpaa ni afurasi naa ransẹ pe awọn ọrẹ mẹta mii, Nura Basiru, Muttaga Lawan ati Hamisu Musa, ti wọn jẹ ọmọ Ogun ọdun lati wa si ile rẹ, di iyawo rẹ lati le ni anfani ibalopọ.
Ariwo iyawo ni awọn ara adugbo gbọ,ti wọn si suure lọ ba, ti wọn si tun gbe lọ si ile iwosan nibi to dakẹ si.
Ọwọ ti tẹ ọkọ iyawo ati awọn ọrẹ rẹ
Ìyàwó gun ọkọ lọ́bẹ pa lẹ̀yìn ọjọ́ kẹsàn-án ìgbeyàwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin nipa bi ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano ti tẹ iyawo kan to ṣekupa ọkọ rẹ lọjọ Isẹgun to jẹ ọjọ Kẹsan an lẹyin igbeyawo wọn.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede, Saudat Jibril, ẹni ọdun mejidinlogun gun ọkọ rẹ, Salisu Idris, ẹni ọgbọn ọdun lọbẹ ni aya.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Faraw ani ijọba Tarauni nipinlẹ Kano.
"Iṣẹlẹ naa waye ni ago mejila ooru ni ọjọ Kẹfa oṣu Karun un nigba ti afurasi naa gun ọkọ rẹ ni ọbẹ ni aya," SP Kiyawa ṣalaye.
Iṣẹlẹ yii lo ti fa ọpọ awuyewuye nipinlẹ Kano ati ni awọn apa ibi kan ni apa ariwa Naijiria paaapa lori ayelujara nibi ti ọpọ eeyan ti n fi ẹdun ọkan wọn han.
Aworan ati fọnran ṣafihan ọpọ eeyan to wa ni ile tọkọtaya naa ni ọjọ Isẹgun.
Ohun to tẹ wa lọwọ ni pe iṣẹlẹ naa waye lẹyin ọjọ mẹsan an ti wọn ṣe igbeyawo.
"A ti mu iyawo naa si ahamọ wa nibi ti a ti n fi ẹsun ipaniyan kan. Kete ti a ba pari iwadii wa, a yoo mu lọ si ile ẹjọ lati jẹjọ ẹsun ipaniyan." SP Kiyawa ṣalaye.
Bakan naa lo ni awọn gbe ọkọ naa lọ si ile iwosan Kano, nibi ti wọn ti fidi rẹ mule pe o ti jade laye.
Ohun pato to fa ija laarin tọkọtaya ni ko ti han si araaye ṣugbọn iya Salisu sọ fun ileeṣẹ iroyin Kano pe ifọmọlọkọ lo waye laarin tọkọtaya naa.
"Emi ati iya ọmọ yii ni a jẹ ọmọ Baba. Igbeyawo jẹ isopọ, ti Ọlọrun si so wọn pọ."
"O ri iyawo rẹ fun ara rẹ, o nifẹẹ ṣugbọn iyawo ni o ko kọkọ nifẹ rẹ."
Baba oloogbe naa ni oun ti forijin afurasi to jẹ iyawo ọmọ rẹ, ti ohun ko si ni pe lẹjọ.
















