Joe Biden korò ojú pé Donald Trump ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà, kò sọ̀rọ̀ bíi Ààrẹ Amẹ́ríkà

- Author, Nick Robinson
- Role, Today programme presenter
- Reporting from, Delaware
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ninu ifọrọwerọ kan to jẹ akọkọ iru rẹ lẹyin to fi ipo Aarẹ silẹ, Aarẹ Joe Biden ti sọrọ lori ero rẹ nipa Donald Trump to gba ipo lẹyin rẹ lẹyin ọgọrun ọjọ Trump akọkọ lori oye.
Lara awọn nnkan to sọ ni bo ṣe kọkọ pade Trump nile itura kan ni Deleware titi to fi di ẹni to n tukọ ilẹ Amẹrika bayii.
Gẹgẹ bii asiko to ṣiwa lori ipo Aarẹ, Biden ṣi ni ọpọ awọn ẹṣọ alaabo layika rẹ pẹlu awọn ọkọ SUV dudu to wa fun eto abo rẹ.
Lẹyin ti Trump gori oye lo ti n bẹrẹ si n darukọ Biden ninu ọpọ ifọrọwanilẹnuwo rẹ ati asiko mii to ba n sọrọ nipa ijọba to jẹ ṣaaju rẹ.
Awọn onimọ sọ pe igba 580 ni Trump ti darukọ Biden laarin ọgọrun ọjọ rẹ akọkọ ni ọfisi Aarẹ.
Biden sọ pe awọn Aarẹ to ba gori oye kii sọrọ kobakungbe nipa ẹni to ba gbe ijọba fun wọn amọ kii ṣe bii ti Trunmp.

Ninu ifọrọwerọ ọhun, ohun to n dun Biden julọ ni iha ti Trump kọ si awọn ọrẹ ilẹ Amẹrika bo ṣe n sọrọ ṣakaṣaka si wọn, bii Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky.
O ni "O dun mi fun Amẹrika pe irufẹ nnkan bẹẹ ṣẹlẹ" ni idahun rẹ si ọwọ ti Trump fi sọrọ si Zelensky ninu oṣu keji ọdun yii.
Biden tẹsiwaju pe "Iru Aarẹ wo ni ẹ ri to n sọrọ ṣakaṣaka bẹẹ? Kii ṣe bi a ṣe n wuwa niyẹn. A wa fun ominira, ijọba awarawa ati anfani fun awọn eeyan - kii ṣe ki a maa gbẹsẹle nnkan.
Lẹyin ọgọrun ọjọ ti Trump gori alefa, o ṣoro fun Biden lati mẹnuba aṣeyọri pato ti Trump ti ṣe.
Yatọ si ohun to n ṣẹlẹ abẹle l'Amẹrika, ohun to ka Biden lara julọ ni ipo ti ilẹ naa wa lagbaye, paapaa ibaṣepọ rẹ pẹlu ilẹ Europe lasiko ijọba Trump.
Ibaṣepọ Amẹrika pẹlu ajọ Nato

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ti a ba n sọrọ nipa ibaṣẹpọ Amẹrika ninu Atlantic Alliance – iyẹn ajọ Nato, Aarẹ Trump ti sọ pe niṣe lawọn to wa ninu ẹgbẹ naa n lo ori ijọba Amẹrika.
Bẹẹni igbakeji rẹ, JD Vance \naa ni awọn yoo fi ẹgbẹ naa silẹ, nigba ti minisita eto abo Amẹrika naa tun ni niṣe lo dabii igba ti ilẹ Europe n mọọmọ lo Amẹrika fun anfani ara rẹ nikan.
Biden ṣalaye pe majẹmu aarin gbogbo ọmọ ẹgbẹ Nato lati daabo bo ara lọwọ awọn ọta to ba fẹ gbogun ti wọn jẹ eyii ti wọn gbọdọ mu ni pataki.
O ni "Ẹru n ba mi pe awọn alabaṣepọ wa kaakiri agbaye ko ni ni igbagbọ ninu wa mọ ninu ẹgbẹ ti a ti darapọ mọ lati nnkan bii ọgọrin ọdun sẹyin."
Lasiko ijọba Biden ni orilẹede Finland ati Sweden darapọ mọ Nato eyii to gbagbọ pe o mu ki ajọṣepọ naa tunbọ lagbara si.
Biden ti wa sọ pe "Mo n kọminu pe Europe ko ni ni igbagbọ ninu Amẹrika mọ to fi mọ bi Amẹrika ṣe jẹ aṣaaju lagbaye, kii ṣe lori ọrọ Nato nikan amọ nipa awọn nnkan mii to ṣe pataki."
Biden: Oloṣelu to pẹ julọ ninu ijọba Amẹrika
Akọroyin wa pade Biden niluu Wilmington, ni Delaware, nibi to ti n gbe lati kekere.
Ẹni ọdun mejilọgọrin ni Biden lasiko to kuro ni ijọba amọ oun lo lo asiko to pẹ julọ ninu ijọba Amẹrika.
Ẹni ọgbọn ọdun ni Biden wa lasiko to kọkọ di sẹnetọ l'Amẹrika, o si n goke agba ninu oṣelu Amẹrika titi to fi de ipo Aarẹ orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lonii, Biden ṣi ji pepe, bẹẹ lara rẹ si mokun daadaa bo tilẹ jẹ ko ja fafa bii ti atijọ mọ bẹẹ ni kii sọ ọrọ pupọ mọ.
Ninu ipade akọroyin wa pẹlu rẹ, o jabọ pe yoo ṣoro fun un lati tun lo ọdun mẹrin mii si gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika.
Asiko ti eto idibo Amẹrika ku ọgọrun ati ọjọ meje pere lo sọ pe oun ko ṣe mọ, eyii to mu ko ṣoro fun Kamala Harris lati tete ṣeto ipolongo ibo rẹ.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa, Biden sọ pe asiko ti oun kede ko ba nnkan jẹ nitori owo gọbọi ni ẹgbẹ gbe fun Kamala lati ṣe ipolongo ibo rẹ.
O fi kun pe oun ko kabamọ pe oun ko tete kede pe oun ko ṣe mọ lasiko ti oun kede.
O ni "Rara o, mo gbagbọ pe asiko to yẹ ki n kede ni mo kede… amọ ṣa, igbesẹ to le ni."
Trump ko ṣe bii Aarẹ Republican
Biden sọ pe oun darapọ mọ oṣelu lati ṣegbe lẹyin idajọ ododo, titi di oni, oun ko si tii dẹyin lẹyin afojusun naa.
O ni "Kaka ki ijọba awarawa maa gboro si kaakiri agbaye, niṣe ni ina rẹ n jo ajorẹyin, gbogbo iran lo si gbọdọ ja fun un."
Nigba to n sọrọ niluu Chigaco laipẹ yii, o ni ko si "Ọba" kankan l'Amẹrika.
Nigba ti akọroyin wa ere lọwọ rẹ boya Trump n ṣe bii Baṣorun Gaa, o ronu daada ko to fesi.
Nigba ti yoo fesi si ibere naa, o ni Trump "Ko ṣe bii Aarẹ ti wọn yan ninu ẹgbẹ Republican."
Lẹyin naa lo ni ẹru ko ba oun mọ nipa ọjọ ola ijọba awarawa l'Amẹrika nitori awọn ọmọ ẹgbẹ Republican funra wọn ti n mọ irufẹ eeyan ti Trump jẹ bayii.
"Oponu ni ẹnikẹni to ba lero pe Putin yoo jawọ"
Lasiko to n sọrọ nipa asiko rẹ gẹgẹ bii olori ẹgbẹ Nato, o ranti bo ṣe kilọ pe Aarẹ Russia, Vladimir Putin yoo kọlu Ukraine.
Amọ lẹyin ti Trump gori alefa, ọna mii lo gba ni bo ṣe jẹ ko ye ijọba Ukraine pe o gbọdọ fi awọn ilẹ kan silẹ fun Russia to ba n fẹ ki ogun to n lọ lọwọ nibe wa sopin.
O ni "Putin ni oun n ri Ukraine bii ọmọ iya kan naa pẹlu Russia ati pe ẹtọ oun ni Ukraine jẹ.
"Ẹnikẹni to ba ro pe Putin yoo jawọ ninu ohun to n ṣe lọwo yii n tan ara rẹ jẹ ni o."
Biden ni ẹru n ba oun pe igbesẹ ti Trump n gbe lori ọrọ naa le maa paroko si awọn orilẹede mii ni Europe pe asiko ti to lati gba fun Russia.

Amọ ṣa awọn kan ti n bu ẹnu atẹ lu Biden fun ipa to ko ninu ogun to n lọ lọwọ ni Ukraine.
Awọn eeyan kan ni Kyiv gbagbọ pe lootọ ni Biden gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika ṣatilẹyin fun Ukraine lati koju Russia amọ ko ṣe atilẹyin fun lati bori Russia.
Nigba ti a bere lọwọ rẹ boya lootọ ni ko ni igboya lati fun Ukraine ni gbogbo ohun ija ogun to nilo lati ṣẹgun Russia, o fesi pe "Gbogbo ohun ti Ukraine nilo lati gba ominira ni a fun wọn, a si ti ṣẹtan lati lo ohun ija oloro ti Russia ba tun gbe ori soke lẹẹkan si.
Biden pari ọrọ rẹ pe gbogbo ipa ijọba Amẹrika lo n sa ki ogun agbaye kẹta ma baa waye.












