Ọ̀ná là ní ẹnu ibodè Seme àti Badagry bí Tinubu ṣe fagilé ìgbégidínà lójú ọ̀nà Nàíjíríà sí ilẹ̀ Benin

Ẹnu ibode Seme
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ idasilẹ ẹgbẹ awọn asọbode ijọba orilẹede kọọkan to wa ninu ajọ ECOWAS, ki wọn le lọ wo gbogbo igbegidina to wa laarin awọn orilẹede naa.

Musa Nuhu, aṣoju Naijiria ninu ajọ ECOWAS lo kede eyi lasiko abẹwo rẹ si ẹnubode orilẹede Naijiria ati ilẹ Benin ni Seme.

"A fẹ bẹrẹ pẹlu ẹnu ọna ibode Seme ati Badagry. Ijọba ti da igbimọ silẹ lori ọrọ yii, ti a o si bẹrẹ si ni gbe igbesẹ laipẹ.

"Fun idi eyi, a o moju to gbogbo nnkan to n lọ, mo si fi n da yin loju pe ijọba Naijiria yoo wa ojutu si awọn ọrọ yii."

Ọpọ igba ni ọrọ ti jẹyọ pe awọn igbegidana wa ni ọna morosẹ Badagry Seme, eyi to n ṣe akoba nla fun igbokegbodo awọn araalu ati okoowo wọn.

Nuhu ni, "Ọna yii ni ọpọ n gbe loorekoore ni apa iwọ oorun Afrika, ni pe ki a gbe ọja lati ibi kan si ibi kan.

Ti a ko ba le rin pẹlu alaafia ni apa iwọ oorun Afrika, yoo ṣe akoba nla.

Ọpọ awọn awakọ to ba awọn akọroyin sọrọ bu ẹnu atẹlu awọn igbegidina to wọpọ loju ọna marosẹ naa.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ ajọ ECOWAS, Omar Alieu Touray ni eyikeyi owo ti awọn awakọ ba san, ni wọn gbudọ ba ẹri fun.

Touray ni bi igbegidina ati gbigba owo riba lọwọ awọn awakọ yii loju ọna marosẹ Naijiria si Benin ni ko bojumu, ti ko si wa ni ilana idasilẹ ECOWAS.

"Ti wọn ba da ọkọ duro lati gba owo lọwọ wọn, ẹ gbọdọ fun wọn ni ẹri lori iye owo ti wọn ba san.