Tito Harrison, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà ṣàlàyé àìsàn tó sọ ọ́ di aláìní, tó ṣe ń gbé ilé àna rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Talk-To-B
Awọn ọmọde asiko yii le maa mọ ẹni ti a n pe ni Bolatito Harrison, awọn eeyan ti ki i ṣe ọmọ ana ni yoo mọ pe gbajumọ oṣere lagbo fiimu Yoruba ni nigba kan.
Awọn agba oṣere bii Ọga Bello, Yinka Quadri, Antar Laniyan, Saheed Balogun ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn jọ gbe ere tiata Yoruba ga.
Ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni Tito Harrison, iya rẹ lo wa lati Auchi, ipinlẹ Edo.
Ṣadeede ni awọn eeyan ko gbọ nnkan kan nipa Tito Harrison mọ, ko si ninu awọn iṣẹ to n jade mọ, bẹẹ ni iroyin ko sọ nipa rẹ.
Ọjọbọ ọsẹ yii ni Harrison yọju lori eto 'Talk 2-B', ti Biola Adebayo toun naa jẹ oṣere tiata maa n ṣe.
Lori eto naa ni Tito ti ṣalaye bi idaamu ṣe ba a nigba to ni aisan ẹdọ pẹlu ọgbẹ inu.
O sọ bi dukia rẹ ṣe tan, to di ẹni to n gbe ile iya iyawo rẹ ati bi nnkan ko ṣe ri i bii ti tẹlẹ mọ.
Ọdọ àwọn súfèé-tàka ni mo ti bẹ̀rẹ̀, mo gbìyànjú kiri títí

Oríṣun àwòrán, Talk-To-B
Ninu alaye agba oṣere naa lo ti ni agbo sufe-taka loun ti bẹrẹ. O ni ọdun 1987 loun bẹrẹ si i ṣe ohun to jọ mọ ariya.
O ni oun ba awọn oloyinbo naa ṣe ati awọn ẹya Igbo,ṣugbọn gbogbo ẹ ni ko bọ si i.
O ṣalaye bi awọn Igbo ṣe sọ pe nitori oun ki i ṣe Igbo, wọn ko le fun oun niṣẹ.
Ko too di pe oun de ọdọ ẹgbẹ oṣere awọn Yinka Quadri ti i ṣe Ọdunfa Caucus.
Yinka Quadri lo ni o ran oun lọwọ nibẹ, towo fi de.
''Ninu owo akọkọ ti Yinka Quadri fun mi fun ere ti mo kọ, mo gba ile, mo ṣegbeyawo pẹlu iyawo mi, ohun gbogbo si n lọ daadaa.
''Iyawo gidi ni mo ni, o fi ara tutu ṣe adura si owo yẹn fun mi, gbogbo nnkan si n lọ daadaa.
'' Awọn kan lo dide ogun si mi l'Odunfa ti mo fi kuro nibẹ, o jọ pe wọn fẹẹ ki n tun waa kọṣẹ lẹyin ti mo ti mọṣẹ. Bi mo ṣe kuro nibẹ fun wọn niyẹn.
Àdánwò irú èyí tó kan Joobu nínú Bíbélì dé

Oríṣun àwòrán, Tito Harrison/Facebook
Gẹgẹ bo ṣe ṣafiwe ohun to ṣẹlẹ si i, Tito Harrison to kẹkọọ nipa ede gẹẹsi, sọ pe bi Ọlọrun ṣe dan Joobu wo ninu Bibeli lo ṣe ṣẹlẹ si oun.
'' Mo kan ri i pe o maa n ṣe mi bii pe mo fẹẹ bì, o n rẹmi, mi o si le jẹun.
''Nigba ti mo de ọsibitu ni wọn ni mo ni aisan ẹdọ.
''Ọjọ mẹta ni mo fi wọ coma, ti mi o mọbi ti mo wa ti mi o si laju.
'' Ninu aarẹ naa ni mo ti ta awọn ilẹ ti mo ni, mo ta ile mi ti mo ti fẹẹ kọ tan, mo ta mọto mi mo tun ta ti iyawo mi naa.
''Ile iya iyawo mi la ko lọ, mi o mọ bawọn ọmọ ṣe n jẹun''
''Ile iya iyawo mi la ko lọ, a ko awọn ọmọ wa naa lọ sibẹ. ''
''Gbogbo eeyan lo kọ mi silẹ, iyawo mi nikan ni ko fi mi silẹ. Bawọn eeyan ṣe n sọrọ buruku si i to, ko da wọn lohun.
Oun ko mọ bawọn ọmọ ṣe n jẹun.
''O sọ fun mi pe ki n jẹ ka ta awọn dukia naa, ki n ṣaa ti wa laye lo ṣe koko.''
Tito to n fomije sọrọ yii, sọ pe Musulumi loun, oun ni anfaani lati fẹ iyawo ju ẹyọkan lọ.
O ni ṣugbọn pẹlu awọn nnkan to ti ṣẹlẹ, toun ko si ronu iyawo pupọ ri, oun yoo duro ti iyawo naa ni.
''Taye, ti mo ba tun wa sile aye nigba mi-in, iwọ ni maa fẹ . ''To ba tiẹ jẹ ki n le tọju ẹ nikan ni, Oluwa yoo wo ọla bẹẹ, yoo da igba pada fun mi. Oluwa yoo bu kun fun ọ, Taye.''
Ọgbẹni Harrison sọ pe oun ko ni mọto mọ, ẹsẹ loun fi n rin kiri.
O ni oun di tẹnanti pada, ṣugbọn oun mọ pe adanwo toun yoo bori ni gbogbo rẹ.
Gbajumọ oṣere naa sọ pe ẹmi loju, o ni boun ba ti ku nkọ, ṣe oun yoo le wa mọto ninu iboji ni.
Tito sọ pe oun kẹkọọ ninu ohun to ṣẹlẹ soun, itumọ rẹ ni pe bo ti wu ki eeyan sare to, Oluwa le pinnu lati fa a sẹyin,ko le kọ ẹkọ kan.
Ọpọ eeyan n iriri Tito Harrison yii ṣe laaanu, kaluku si n tọrọ ayipada si rere igba fun un.














