Kí ni ìdí tí India àti Pakistan fi ń jà sí agbègbè Kashmir?

Fun ọpọ ọdun ni Kashmir ti n fa ija laarin India ati Pakistan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Fun ọpọ ọdun ni Kashmir ti n fa ija laarin India ati Pakistan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orilẹede meji ti wọn fẹgbẹkẹgbẹ ara wọn pẹlu agba ohun ija oloro nuclear, India ati Pakistan ti ja ogun meji ọtọtọ yatọ si awọn ija mii nitori Kashmir.

Amọ ki lo n fa ija yii ati pe bawo lo ṣe bẹrẹ?

Bawo ni ija yii ṣe pẹ to?

Kashmir jẹ agbegbe kan to rẹwa, to si gbajumọ fun awọn odo ati oke nla nla rẹ.

Ṣaaju ki India ati Pakistan to gba ominira wọn lọwọ ijọba ilẹ Gẹẹsi, ni wọn ti n ja si Kashmir yii.

Labẹ ofin tuntun Indian Independence Act, awọn eeyan agbegbe naa, ti ọpọ ninu wọn jẹ Musulumi, lanfani lati yan lati darapọ pẹlu India tabi Pakistan.

Hari Singh, to jẹ ọkan lara awọn adari agbegbe naa ni, oun kọkọ n fẹ ki Kashmir gba ominira tirẹ.

Amọ ninu oṣu Kẹwaa ọdun 1947, o yan lati jẹ ti India latari iranlọwọ rẹ lati gbogun ti awọn eeyan to n kogun ja a lati Pakistan.

Ogun bẹ silẹ nibẹ, India si ke si ajọ UN pe ko da si ọrọ naa.

UN damọran pe ki wọn jirororo lati mọ orilẹede ti agbegbe ọhun yoo darapọ mọ.

Ninu oṣu Keje ọdun 1949, India ati Pakistan tọwọ bọwe jogun-o-mi ni ilana pẹlu imọran UN, agbegbe naa si pin si meji.

Kashmir

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọdun 1965 ni ogun keji tẹle ogun akọkọ. Lọdun 1999 ẹwẹ, India tun ba Pakistan ja ogun mii.

Lasiko naa ni India ati Pakistan ti kede pe awọn ni ohun ija ogun nuclear lọwọ.

Lonii niluu Delhi ati Islamabad, awọn orilẹede mejeji lo sọ pe awọn lo ni Kashmir amọ awọn kọ lo n dari rẹ ni kikun.

Ki lo de ti ogun ko sinmi lagbegeb ti India n dari?

Awọn alatilẹyin Pasban-e-hurriyat Jammu Kashmir n fẹhonuhan ninu oṣu Karun un, ọdun 2025

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ẹsin wa lara nnkan to n fa ija ni Kashmir

Ninu Kashmir funra rẹ, awọn kan nibẹ ko fẹ ko wa labẹ India, wọn n fẹ ko da wa bii orilẹede olominira tabi ko wa labẹ Pakistan.

Ẹsin jẹ nnkan pato to n da ija silẹ nibẹ latari bi ida 60% awọn eeyan rẹ ṣe jẹ Musulumi, eyii to mu ko jẹ agbegbe ti awọn Musulumi pọ ju si ni India.

Lati ọdun 1989 ni awọn agbebọn ti n kọlu awọn agbegbe ni India, eyii to ti mu ọpọ ẹmi lọ.

India fẹsun kan Pakistan pe oun lo n ṣatilẹyin fun awọn agbebọn to n kọlu agbegbe oun amọ Pakistan ni ko si ootọ ninu ọrọ naa.

Ki lo ṣẹlẹ lẹyin awọn ikọlu akọkọ ni Kashmir?

Ni 2016, lẹyin ti wọn ṣeku pa ọmọ India mọkandinlogun ni Uri, India bẹrẹ si n kọlu awọn agbegbe ti awọn agbebọn wa laarin ala orilẹede mejeji.

Nigba ti yoo di 2016, ibugbamu to ṣeku pa ogoji eeyan ni Pulwama mu ki India kọlu awọn agbegbe kan titi de Balakot, eyii to jẹ igba akọkọ ti yoo gbe ogun wọ Pakistan lati 1971.

Wahala mii tun waye ninu oṣu Kẹrin ọdu 2025 lẹyin ti awọn agbebọn pa eeyan mẹrindinlọgbọn lagbegbe ti India n dari ni Kashmir.

Ikọlu naa lo buru julọ laarin ogun ọdun.

India fesi pẹlu ado oloro meji si Pakistan lagbegbe to n dari ni Kashmir, eyii to mu ibẹru dani pe ija tuntun yoo waye laarin orilẹede mejeji.

Kashmir ti a n sọrọ rẹ yii jẹ agbagbe ti ologun pọ si julọ ni gbogbo agbaye.

Ṣe ireti alaafia ṣi wa?

India ati Pakistan tọwọ bọwe adehun jogun-o-mi ni 2003.

Ni 2014 ti olootu ijọba to wa lori oye lọwọ, Narendra Modi gba ọpa aṣẹ, o ni oun ko ni gba fun Pakistan amọ o ti n tọ ipa ipade alaafia.

Nawaz Sharif ati Narendra Modi ni 2014

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Olootu ijọba Pakistan ati India lasiko adehun alaafian wọn ni 2014

Nawaz Sharif, to jẹ olootu ijọba Pakistan lọdun 2014 yọju si iburawọle olootu ijọba India niluu Delhi.

Ṣugbọn lẹyin ọdun kan ṣoṣo ni India fẹsun kan awọn agbebọn kan ni Pakistan fun ikọlu to waye ni papakọ ofurufu kan ni Pathankot ni ariwa Punjab.

Lati akoko naa ni ibaṣepọ orilẹeede mejeji ti dojuru.