Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ fún Gómìnà Adeleke ní gbèdéke ọjọ́ láti yanjú owó ilé tó ń fò lókè l'Osun

Oríṣun àwòrán, Gov. Ademola Adeleke/X
Ẹgbẹ kan, 'The Youth Assembly of Nigeria' (YAN), ti fi ẹjọ awọn baba ati iya onile, titi kan awọn abaniwale ti a mọ si ejẹnti, sun Gomina Ademola Adeleke nipinlẹ Osun.
Eyi n waye latari owo ile ti wọn lo ti wọn ju nipinlẹ Osun, ti ko si si ofin kankan to n ka awọn baba onile lọwọ kò.
Koda, gbedeke ọjọ meje ni ẹgbẹ naa fun Gomina Adeleke ati ile igbimọ aṣofin Osun, lati buwọ lu aba ti yoo gbogun ti idaamu tawọn ara Osun n koju lọwọ awọn onile ati ejenti.
Agbẹnusọ YAN, Hammed Fatomi, ṣalaye fun awọn akọroyin pe: " Ẹnu kan la fi n sọrọ, pe kijọba fopin si bawọn onile ṣe n ni araalu lara pẹlu owo ile gọbọi.
"Gbogbo ilu wa lo ti di ibi tawọn lanlọọdu ati ejenti fi n pawo gọbọi lai si ofin to le yẹ wọn lọwọ wo.
" Awọn akẹkọọ, oṣiṣẹ ijọba to ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ, awọn to ṣẹṣe gbeyawo atawọn ọdọmọde akọṣẹmọṣẹ gbogbo lo n kerora latari owo ile to pọju ti awọn onile n gba."
Agbẹnusọ naa sọ pe o ṣe ni laanu pe ijọba ko ṣe ohunkohun si ọrọ yii latilẹ, to fi di pe awọn onile n gbe owo rẹpẹtẹ le ile wọn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, igbesẹ kiakia ti yoo dẹkun ifijayẹni yii ni awọn ẹgbẹ naa sọ pe awọn n fẹ lati ọdọ ijọba.
YAN rọ Gomina Ademola Adeleke lati bẹrẹ iṣe lori rẹ laaarin ọjọ meje.
Wọn fi kun un pe ki iṣẹ bẹrẹ lori aba to wa nile igbimọ lori rẹ, ki wọn si gbe ẹka kan kalẹ ti yoo maa ri si ohun ti awọn onile ba n ṣe l'Osun.
"A n rọ ijọba ipinlẹ Osun lati ri si ọrọ yii laaarin ọjọ meje. Ki wọn mu un ni pajawiri.
"A fẹẹ ṣe iwọde wọọrọwọ tẹlẹ ni, ṣugbọn a sun un siwajunitori rogbodiyan oṣelu to wa lawọn ijọba ibilẹ wa."
Bẹẹ ni ẹgbẹ YAN ṣalaye.















