Ìdí tí ọlọ́pàá South Africa fi mú pásítọ̀ ọmọ Naijiria padà, lẹ́yìn tí iléẹjọ́ tú u sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ ọlọpaa orilẹede South Africa ti fọwọ ofin mu Pasitọ Timothy Omotoso, ọmọ Naijiria, pada lẹyin ti ileẹjọ tu u silẹ tan lọgba ẹwọn lori ẹsun ifipabanilopọ atawọn ẹsun mii ti wọn fi kan an.
Kọmiṣọna ọlọpaa, Fannie Masemola, to fi iroyin naa lede lọjọ Abamẹta ọjọ kẹwaa oṣu Karun un yii sọ pe ajọ to n ri si wiwọle ati jijade lorilẹede South Africa, atawọn ajọ mii bii NIU ati TRT lo mu Pasitọ Omotoso lori ẹsun to ni ṣe pẹlu ofin ijọba lori jijade ati wiwọle si South Africa.
Awọn alaṣẹ ajọ to n ri si wiwọle ati jijade kuro lorilẹede South Africa mu Pasitọ Omotoso ni East London laarọ Satide kete lẹyin isin ni ṣọọṣi.
''Ẹsun to da lori rirun ofin jijade ati wiwọle si South Africa ni wọn fi kan Ọgbẹni Omotoso, yoo si foju ba ile ẹjọ lọjọ Aje to n bọ,'' Ọga ọlọpaa lo sọ bẹẹ.
Loṣu Kẹrin to kọja ni ileẹjọ kan lorilẹede South Africa paṣẹ itusilẹ Ọgbẹni Omotoso lẹyin to lo ọdun mẹjọ lọgba ẹwọn lori ẹsun ifipabanilopọ ati iyọnilẹnu fun ibalopọ pẹlu awọn ọmọbinrin ijọ rẹ.
Gbogbo ẹsun onikoko mejilelọgbọn to da lori ifipabanilopọ, iyọnilẹnu fun ibalopọ ati ifiniṣowo ẹru ti wọn fi kan an ni adajọ naa yi danu ti o si paṣẹ pe ki o maa lọ ni alaafia.
Adajọ naa sọ pe loootọ ni ọrọ ẹnu pasitọ naa ko fẹsẹ mulẹ to, amọ, adajọ ni igbimọ olupẹjọ gan an ko ṣe agbekalẹ ẹjọ naa bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Pasitọ Omotoso sọ fawọn akọroyin lẹyin idajọ naa pe inu oun dun fun idajọ to waye.
Ọdun 2017 ni wọn mu pasitọ Timothy Omotoso lori ẹsun onikoko mejilelọgbọn to da lori ifipabanilopọ
Ileẹjọ tun paṣẹ wi pe kawọn eeyan to n jẹjọ pẹlu Pasitọ Omotoso, Lusanda Sulani ati Zikiswa Sitho naa maa lọ ni alaafia.
Ọdun 2017 ni wọn mu Ọgbẹni Omotoso, pasitọ ijọ Jesus Dominion International (JDI) ni South Africa lori ẹsun onikoko mejilelọgbọn to da lori ifipabanilopọ, iyọnilẹnu fun ibalopọ ati ifiniṣowo ẹru.
Pasitọ Omotoso loun o jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun, koda, wọn gbe igbẹjọ naa sori afẹfẹ eyi ti ọpọ eeyan lanfaani lati wo kaakiri orilẹede South Africa.
Ọpọ awọn ọdọbinrin lo jẹri tako Pasitọ Omotoso wi pe ni ṣe lo maa n mu awọn lọkọọkan, ti yoo si pada tọrọ idarijin lẹyin to ba ti ri awọn tan.
Amọ, Adajọ Irma Schoeman ileẹjọ giga Eastern Cape tako bi igbimọ olupẹjọ ṣe ṣe ẹjọ naa.
Adajọ ni igbimọ olupẹjọ kuna lati fidi awọn ẹsun ti wọn fi kan Pasitọ naa atawọn meji mii mulẹ daadaa.
Igbẹjọ Pasitọ Omotoso ni akọkọ iruẹ ti wọn yoo kọkọ gbe sori afẹfẹ ni South Africa nibi ti iwa ifipabanilopọ ti wọpọ.
Ọpọ eeyan lo sọrọ lori igbẹjọ naa ti wọn si fẹẹ mọ iru idajọ ti ileẹjọ yoo gbe kalẹ.
Orilẹede South Africa wa lara awọn orilẹede ti iwa ipa sawọn obinrin ti wọpọ julọ lagbaaye.
Laarin ọdun 2023 si 2024, akọsilẹ fi han pe ẹsun ifipabanilopọ 42,500 lawọn eeyan mu lọ sile iṣẹ ọlọpaa ni South Africa, eyi to tumọ si pe iṣẹlẹ ifipabanilopọ 116 lo n ṣẹlẹ lojumọ lorilẹede naa.















