Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà dá Fred Ajudua padà sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn jìbìtì $1.43m

Fred Ajudua

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ìyẹn Supreme Court ti yí ìpinnu ilé ẹjọ́ tó fún gbajúmọ̀ ìlú Eko kan, Fred Ajudua ní béèlì lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu $1.43m tó wọ́n fi kàn án.

Gbogbo àwọn adájọ́ márùn-ún ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ náà fẹnukò, tí wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n dá Ajudua padà sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún ní kí ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, Economic and Financial Crime Commission, EFCC fi kan Ajudua tẹ̀síwájú.

Ẹ ó rántí pé ni ilé iṣẹ́ Palestine, nínú lẹ́tà kan tí wọ́n kọ lọ́jọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, ọdún 1993 sí Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè àti ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìgbà náà ni wọ́n ti fẹ̀sùn kan Ajudua pé ó fi ọ̀nà èrú gba owó $1.43m lọ́wọ́ Ziad Abu Zalaf, ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine tó ń gbé ní Germany.

EFCC ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn ọ̀hún tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn méjìlá kan Ajudua ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko.

EFCC ní Ajudua lẹ́dì àpòpọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joseph Ochunor, tó ti na pápá bora, láti fi ọ̀nà èèrú gba owó lọ́wọ́ Ziad Abu Zalaf ti iléeṣẹ́ Technical International Ltd, ẹ̀ka iléeṣẹ́ Mystic Company Ltd, tó fi Germany ṣe ibùjókòó.

Wọ́n fẹ̀sùn kàn pé Ajudua àti Ochunor kọ́kọ́ gba $268,000 lọ́jọ́ Kejì, oṣù Kẹrin àti $225,000 lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù Karùn-ún, ọdún 1993 lọ́wọ́ Ziad pẹ̀lú àníyàn láti lù ú ní jìbìtì.

EFCC fi kun pé Ajudua àti Ochunor ṣe ayédèrú ìwé ẹ̀rí ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà àti ti àjọ NNPC, tí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí Ziad gẹ́gẹ́ bí ojúlówó lójùnà àti fẹ́ bo ìwà jìbìtì wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹ́yìn tí EFCC wọ́ Ajudua lọ sílé ẹjọ́, agbẹjọ́rò Ajudua, Olalekan Ojo ní kí ilé ẹjọ́ fún Ajudua ní béèlì láti máa jẹ́jọ́ láti ilé nítorí ìlera rẹ̀.

Àmọ́ ilé ẹjọ́ gíga lábẹ́ ìdarí Adájọ́ Mojisola Dada kọ̀ láti fún Ajudua ní béèlì tó sì kó wà ní àhámọ́ tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ fi máa parí.

Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga yìí kò tẹ́ Ajudua lọ́rùn tó sì gba ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ níbi tí wọ́n ti fun ní béèlì.

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lábẹ́ ìdárí Adájọ́ Mohammed Garba ní ẹ̀tọ́ olùjẹ́jọ́ ni láti gba béèlì, tí wọ́n sì yí ìdájọ́ Adájọ́ Mojisola Dada padà.

Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn kò tẹ́ àjọ EFCC lọ́rùn tí wọ́n sì gba ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lọ láti pe ìdájọ́ náà lẹ́jọ́.

Supreme Court da ìdájọ́ tó fún Ajudua ní béèlì lọ́jọ́ Kẹwàá, oṣù Kejìlá, ọdún 2018 nù, tí wọ́n sì ní kó wà ní àhámọ́ láti máa jẹ́jọ́ rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ sọ pé ilé ẹjọ́ gíga tí kò fún Ajudua ní béèlì tẹ̀lé ìlànà òfin tó yẹ àti pé ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn kò láṣẹ láti fún olùjẹ́jọ́ náà ní béèlì.

Adájọ́ Chioma Nwosu-Iheme tó ṣáájú ìgbìmọ̀ àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ náà sọ pé ilé ẹjọ́ gíga ti paná gbogbo ìbéèrè tí Ajudua ń bèèrè fún, tí kò sì sí ohun kankan tí wọ́n nílò láti gbé yẹ̀wò lórí ẹjọ́ náà mọ́.

Bákan náà ni wọ́n ní kí adajọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Eko da ẹjọ́ náà padà fún Adájọ́ Mojisola Dada láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbẹ́jọ́ náà, kí wọ́n sì rip é ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún yá ní kíákíá, kí olùjẹ́jọ́ sì wà ní àhámọ́ láti máa jẹ́jọ́ rẹ̀.

Ta ni Fred Ajudua?

Agbẹjọ́rò ọmọ Nàìjíríà tó ń kojú ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn jìbìtì lílù ni Fred Ajudua.

Ọmọ bíbí ìlú Ibusa ní ìpínlẹ̀ Delta ni Fred Ajudua àmọ́ ìlú Eko ló fi ṣe ibùjókòó.

Onírúurú ẹ̀sùn jìbìtì ló wà lọ́rùn Fred Ajudua tó ń kojú.

Láti ọdún 1993 ló ti ń kojú ìgbẹ́jọ́ pé ó lu ọmọ ilẹ̀ Palestine kan ní jìbìtì.