Ohun márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìrìnàjò mímọ́ sí Saudi Arabia lọ̀dún yìí

Saudi

Oríṣun àwòrán, NAHCON/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ana, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan an, oṣu Karun un, ọdun 2025 yii ni awọn Musulumi ni Naijiria yoo bẹrẹ irinajo silẹ mimọ Saudi Arabia.

Irinajo Hajj jẹ ọkan pataki lara awọn opo ẹsin Islam, paapaa fun ẹni to ba lagbara lati rinrinajo naa.

Awọn ohun marun un to yẹ ki o mọ nipa irinajo ti ọdun yii ree.

1. Ilu Owerri ni baalu akọkọ yoo ti gbera

Ajọ to n ri si irinajọ awọn Musulumi ni Naijiria silẹ mimọ Nigerian Hajj Commission, ti kede pe papakọ ofurufu to wa niluu Oweri ni abala akọkọ awọn arinrinajo naa yoo ti gbera.

Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima ati gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma ni yoo lewaju awọn arinrinajo 315 naa lọ si Saudi.

Baalu ileeṣẹ Air Peace ni yoo ko abala akọkọ awọn arinriajo ọhun.

2. Baalu mẹta mii yoo tun gbera lọjọ naa

Max Air

Oríṣun àwòrán, NAHCON/X

Lara awọn baluu mii ti yoo tun gbera lọjọ naa ni ọkọ ofurufu Max Air ti yoo gbera ni Bauchi.

Yatọ si eyii, Baalu FlyNas yoo tun ko awọn eeyan ni Kebbi, Osun ati ilu Eko lọjọ akọkọ ọhun.

Arinrinajo 2,528 ni igbagbọ wa pe yoo gbera lọjọ akọkọ naa.

3. Ajọ to n ri si irinajo naa ko ni gba owo lọwọ awọn to ba pẹ lẹyin

Awọn Musulumi

Oríṣun àwòrán, NAHCON/X

Ajọ to n ri si irinajo ilẹ mimọ, NAHCON, sọ pe ọjọ keji, oṣu Karun un loun yoo tilẹkun gbigba owo iforuklọsilẹ irinajo naa lọdun yii.

Ajọ ọhun ni eyikeyi arinrinajo naa to ba san owo lẹyin ọjọ naa ni awọn yoo da owo rẹ pada fun.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ kede oṣu Kẹta, ọdun yii gẹgẹ bii gbedeke ki adari ajọ naa, Ọjọgbọn Abdullahi Saleh to sun siwaju.

4. O le ni 40,000 Musulumi to n rinrinajo naa lati Naijiria

Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Atẹjade kan lati ọdọ ajọ NAHCON sọ pe lọjọ ti iforukọsilẹ pari, eeyan 40,671 lo forukọsilẹ lati rinrinajo mimọ ọhun.

5. Ọjọ ti irinajo naa yoo pari

Ninu atẹjade NAHCON, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun un ti a wa yii ni abala to kẹyin ninu awọn arinrinajo naa yoo gbera lọ si Saudi.

O fi kun pe lati ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa si ọjọ keji, oṣu Keje, ni wọn yoo ko awọn arinrinajo naa paa wale.