Ọkùnrin tí Salawa ń fẹ́ báyìí ń yá a lò ni, ìyàwó mi ni títí ayé - Kollington Ayinla

Aworan Alaaji Kollington Ayinla ati Alaaja Salawa Abeni

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Yoruba bọ, wọn ni ẹ ku atijọ mọ ara wọn ri, ẹni ti a si ti bimọ fun ti kuro ni alẹ ẹni.

Eyi ni alaye ti agba ọjẹ onifuji, Jẹnẹra Kollington Ayinla Ilori, ṣe nipa iyawo rẹ to bimọ mẹta fun un, Alaaja Salawatu Ibiwumi Abeni.

Lori eto kan, 'Tejubabyface show', ni Kollington ti sọ laipẹ yii nipa Salawa, pe iyawo oun ni titi aye.

Baba olorin Fuji lati ilu Ilota, ipinlẹ Kwara naa sọ pe ẹni ti Salawa n fẹ bayii n ya a lo ni.

" Bi Ọlọun ṣe fẹ ko ri niyẹn ni, ẹni to bimọ mẹta fun eeyan, o ti kuro ni ale, iyawo mi ṣi ni titi opin aye."

"Ko sibi to maa ko awọn ọmọ yẹn si, o kan jẹ pe ọrọ ọkunrin ati obinrin, bi Ọlọun ṣe kọ naa ni.

''Ki lo le mu un kuro lọdọ mi, amọ mi o ba a wi, nitori gbajumọ loun naa, bawọn obinrin ṣe n du awa ọkunrin ni awọn ọkunrin n du awọn naa, ohun to n fa tiwọn niyẹn

''Amọ o nibi ti ọgbọn obinrin mọ. Ko si nnkan ti mo le maa ṣe nisinyi, lẹsẹkẹsẹ lo maa de. Pe o wa lọdọ ẹnikan, iyẹn kan n ya a lo ni, iyawo mi ni.

''Ko bimọ fun un, emi lo bimọ odidi gbangba mẹta fun. Iyawo mi ṣi ni. Ẹni to n fẹ bayii n ya a lo ni."

Bẹẹ ni Jẹnẹra Kollignton Ayinla wi.

Aworan Alaaji Kollington Ayinla ati Alaaja Salawa Abeni ti wọn di mọra wọn

Oríṣun àwòrán, Others

Kí ló pín Kollington àti Salawa niya?

Ẹni ọdun marundinlọgọrin (75) ni Alaaji Kollington Ayinla bayii, nigba ti Alaaja Salawa ṣẹṣẹ pe ọdun mẹrinlelọgọta (64) laipẹ yii.

Ki awọn olorin meji yii too ṣegbeyawo ni 1986, Oloogbe Alaaji Lateef Adepoju ni Ibiwumi kekere igba naa n fẹ.

Ọmọkunrin kan, Idris Olanrewaju Adefolajuwon Akanji Adepoju, ni wọn bi funra wọn.

Ija de laaarin Salawa ati Adepoju to n ba a gbe orin rẹ jade, obinrin naa si pada sọdọ Kollington Ayinla ti wọn ti n fẹra tẹlẹ.

Wọn ṣegbeyawo ni ọdun 1986.

Ọmọ ọkunrin meji, obinrin kan lo tibi ajọṣepọ yii wa ko too di pe awọn ọrọ kan tun di wahala, ti Salawa si kọ Kollington silẹ ni 1994.

Latigba naa ni awọn olorin mejeeji ti pinya, ti wọn ko jọ gbe mọ.

Ọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin ni Idris Adepoju to jẹ akọbi Alaaja Salawa jade laye ninu ijamba ọkọ.

O si ṣẹku awọn mẹta to bi fun Kollington Ayinla nikan.

''Ọrọ emi ati Barrister pẹlu Wasiu Ayinde''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lori eto naa ni Alaaji Kollington Ayinla ti sọrọ nipa bi oun ati Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ṣe wọ iṣẹ ṣọja.

Jẹnẹra Ayinla sọ pe Barrister ṣiwaju oun gbe awo orin jade nigba tawọn bẹrẹ si i kọrin.

Ṣugbọn nipa ija to wa laaarin oun ati Oloogbe Barrister, Kollignton sọ pe:

''Nigba ti mama mi ku, Wasiu beere lọwọ mi pe ṣe mo ti pe Barrister, mo si sọ fun un pe mi o pe e, nitori a n ja lọwọ.

''O ni ẹ maa pe e ni, nitori nigba ti mama tiẹ naa ku, a ra maaluu.

''Emi ati Sikiru lọ si abẹ igi kan nilee wa nibẹ, a jokoo, mo si sọ fun un pe mo ti darii gbogbo ẹṣẹ to ṣẹ mi ji-in.

''A sunmọ ara wa gan-an o. Gbogbo ohun ta a ṣe nigba yẹn naa la jọ pada wo.

''Awa naa ba a lọwọ awọn baba wa ni, awọn bii S. Aka, Baba l'Ẹgbaa, baba wa n'Ijebu Igbo; Haruna Isola, Oloogbe Ayinla Omowura, awọn naa ba ara wọn ja bẹẹ, wọn tun pari ẹ funra wọn, titi kan Sunny Ade ati Ebenezer Obey

''Gbogbo awọn nnkan ta a ṣe nigba yẹn, ta o ba ṣe e, ko ni i dun.

'' Awọn eeyan wa n sọ pe Alaaji Kollington Ayinla ati K1 De-Ultimate n ja, iru ija wo ni mo fẹẹ maa ba ọmọ mi ja, Ọlọun ma ṣe eeyan lagbaya.

'' Bo lowo to ju ti Karuna lọ, emi ṣi ni baba ẹ.

''Bi ọba kan ko ba ku, omi-in ki i jẹ.

''Igba ti Sikiru gbesẹ lo kan mi. Ta a wa ni onifuji naa ti yoo dide nisinyi, ti yoo ni toun bakan niwaju mi''

"Mo rí Barrister nígbà tí mo wọ 'Coma'"

Lori aisan to ṣe e laipẹ yii to lagbara pupọ, Alaaji Kollington Ayinla ṣalaye ohun ti oju rẹ ri.

Agba onifuji naa sọ pe ọjọ meje ni oun ko fi laju si aye.

O ni oun ko le jẹun tabi mumi, oun si ri ikeji oun, Oloogbe Sikiriu Ayinde Barrister.

''Mo ri ikeji mi, o ni Kola, ki lo wa ṣe nibi.

O ni ki n pada ki n lọ ọ maa mojuto Fuji. Mo ni mo fẹ ẹ jẹun, o ni ko si ounjẹ nibi, ki n ṣaa pada,ki n lọọ mojuto Fuji.

'' igba ti mo waa ji, mo waa n beere pe ki ni mo n ṣe nibi, wọn ni ileewosan ni mo wa.

''Lẹyin ọjọ meje ti mi o le jẹ, ti mi o le mu. Mo dupẹ f'Ọlọun.''