Wo bí àwọn obìnrin ṣe ń rí ikú he láti ọwọ́ àwọn ọkùnrin ní Naijiria

Aworan awọn obinrin meji ti wọn gbe asia to n beere idajọ ododo fun Bamise
Àkọlé àwòrán, Awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ni Naijiria sọ pe ọpọlọpọ obinrin lo ti ku lọwọ akọ ti nnkan kan ko si ti ẹyin rẹ yọ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lọsẹ to kọja, awọn ọkunrin meji lo gba idajọ iku ni Naijiria, fun pe wọn pa obinrin.

Adajọ ọtọọtọ lo gbe idajọ naa kalẹ, lẹyin ọdun mẹta ti wọn si ti pa awọn obinrin naa ni idajọ too waye.

Ọkan lara awọn to gba idajọ iku naa ni Peter Nwachukwu, ọkọ gbajumọ olorin ẹmi nni, Oloogbe Osinachi Nwachukwu.

Wọn ni Peter jẹbi iku iyawo rẹ, lẹyin awọn ẹri to foju han pe lilu lo n lu obinrin naa lalubami.

Ọkunrin keji to gba idajọ iku ni Andrew Ominikoron, awakọ BRT ti wọn fẹsun kan pe o pa Bamishe Ayanwole, ẹni ọdun mejilelogun to pade iku nitori ọkọ ijọba to wọ.

Awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ati ẹbi awọn to di oloogbe yii sọ pe ireti awọn ni pe idajọ yii yoo jẹ ibẹrẹ iru rẹ fun awọn obinrin to ti pade iku lati ọwọ akọ.

Wọn ni ọpọ ẹjọ iku obinrin bayii lo wa ni kootu ni Naijiria, ti wọn ko yanju rẹ titi doni.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ́ ikú abo ní Naijiria

Ọrẹbinrin Killaboi ati ọmọkunrin naa,

Oríṣun àwòrán, @AUSTA_XXO @KILLABOIGRAM/INSTAGRAM

Àkọlé àwòrán, "Killaboi" ree ọtun. O jẹwọ loju opo Instgram rẹ pe oun pa ọrẹbinrin oun. Ọmọbinrin naa lo wa lapa osi.

Lara iku awọn obinrin to ti ọwọ ọkunrin ti wọn pe ni ololufẹ waye, ni ti ọmọbinrin kan, Onuwabuagbe Augusta Osedion, ẹni ọdun mọkanlelogun ( 21).

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Akẹkọọ ni Augusta ni Lead City University, Ibadan. Ọmọbinrin to ni ọyaya to si ja fafa pẹlu erongba lati da ileeṣẹ aṣọ tirẹ silẹ ni.

Ṣugbọn loṣu Keje ọdun 2023, wọn ri oku rẹ to ti n jẹra nile ọrẹkunrin rẹ nipinlẹ Eko.

Ọrẹkunrin Augusta ni wọn pe orukọ rẹ ni Benjamin Best Nnanyereugo, inagije tawọn eeyan si mọ ọn si ni "Killaboi",

O jẹwọ loju opo Instgram rẹ, nibi to ti sọ ọlọkan-o-jọkan ọrọ, pe oun loun pa Augusta.

Iya Augusta, Cordelia Okonye lo mọ pe ina ọmọ jo oun. Iya naa sunkun kikoro pẹlu alaye pe titi toun yoo fi ku ni iku Augusta yoo maa ba oun lọkan jẹ.

"Ọmọ to ṣeleri fun mi lati ṣiṣẹ owo ko si tọju mi daadaa ni." Iya Augusta lo sọ bẹẹ nipa ọmọ rẹ lẹyin iṣẹlẹ naa.

Lẹyin ọjọ diẹ tawọn ọlọpaa mu Killaboi, o sa mọ wọn lọwọ. Sierra Leone lo gba lọ, nibi to ti n yan fanda ki wọn too ri i mu pada logunjọ oṣu Kẹwaa, ọdun 2023.

O ti paarọ orukọ lọhun-un, 'Kanu Princeton Samuel' lo n jẹ nibẹ.

Ṣugbọn o tun sa mọ wọn lọwọ lọgba ẹwọn ni Freetown, nigba ti awọn ẹlẹwọn sa jade lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2023.

Gẹgẹ bawọn ọlọpaa Naijiria ṣe ṣalaye, wọn ni ọpọ ọna lo gba rin irin ajo rẹ naa laaarin Iwọ-Oorun Africa, East Asia ati Middle East.

Wọn lo paarọ orukọ titi ko too fikalẹ si Doha, Qatar, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Ni Qatar, orukọ inagije to yan funra rẹ ni 'Toure Abdoulaye', pẹlu iwe irinna ayederu kan to jẹ ti orilẹede Guinea to n lo, ki wọn too mu un loṣu Keji, ti wọn si fi i ranṣẹ si Naijiria loṣu Kẹrin 2025, fun igbẹjọ.

Ṣugbọn Iya Augusta sọ fun BBC pe mimu ti wọn mu Killaboi ko yi nnkan kan pada. O ni mimu rẹ ko le mu ibanujẹ iku ọmọ kuro lọkan oun.

Aworan to kede pe wọn n wa Benjamin Best.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police

Àkọlé àwòrán, Aworan ti awọn ọlọpaa Naijiria fi kede pe awọn n wa Benjamin Best ree.

Àkọsílẹ̀ ikú àwọn obìnrin tó ti ọwọ́ ọkùnrin wá ní Naijiria

Ni 2023, ẹgbẹrun marundinlaadọrun-un obinrin (85,000) ni akọsilẹ sọ pe wọn mọ-ọn-mọ pa lagbaaye. Gẹgẹ bi ajọ Iṣọkan agbaye , UN, ẹka awọn obinrin ṣe sọ.

Eyi tumọ si pe obinrin mẹfa ni wọn n pa ni wakati kan.

Ninu apapọ onka yii, ilẹ Africa ni iku obinrin ti pọ ju, ẹgbẹrun mọkanlelogun (21,000) obinrin ni wọn pade iku lọwọ ọkunrin.

Pupọ ninu awọn obinrin yii, ka sọ pe ida ọgọta ( 60%) ni wọn riku he lati ọwọ ọkunrin ti wọn n fẹ tabi mọlẹbi wọn.

Ni Naijiria ni 2024, obinrin 133 lo ku nibi ija ọkunrin-si obinrin, gẹgẹ bi akọsilẹ DOHS Cares Foundation, ajọ kan ti ki i ṣe tijọba ṣe wi ninu akọsilẹ wọn.

Wọn ni awọn mi-in tilẹ ku gbe bẹẹ ti ko si akọsilẹ kankan fun.

Ajayi Ololade, ajafẹtọọ awọn obinrin to jẹ oludasilẹ DOHS Care Foundation, sọ pe o jọ pe iṣẹlẹ iku awọn obinrin n pọ si i ni.

O ni eyi jọ bẹẹ pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹsun mejilelọgbọn (32) iru rẹ ni awọn ṣe akọsilẹ rẹ laaarin oṣu Kin-in-ni si Ikẹta ọdun yii.

Ọkan ninu rẹ ni ti ọmọbinrin agunbanirọ, Salome Adaidu, ẹni ọdun mẹrinlelogun ti iku rẹ gba igboro loṣu Kin-in-ni ọdun 2025, lẹyin ti wọn ri ori rẹ ti wọn ti ge ninu apo ni Karu, ilu kan ti ko jinna si olu ilu Naijiria, Abuja.

Olorin ẹmi , Timileyin Ajayi, ni wọn mu fun iku Salome. Awọn ọlọpaa pada ri awọn ageku ara Salome nile Timileyin, alaye to si ṣe fun wọn ni pe ọrẹbinrin oun ni, ṣugbọn o n ṣe oju meji loun.

Timileyn ṣi n jẹjọ ipaniyan lọwọ, o si loun o jẹbi.

"Nigbakigba ti a ba ranti bi wọn ṣe pa aburo mi, o maa n ba wa lọkan jẹ gan-an ni" Ẹgbọn Salome; Patience Adaidu, lo sọ bẹẹ fun BBC lọjọ keji ọjọ ti wọn kọkọ gbọ ẹjọ naa ni kootu.

"Pẹlu iranlọwọ Ọlọrun ati awọn eeyan ti ọrọ yii kan, o yẹ ka ri idajọ ododo." Ẹgbọn Salome lo sọ bẹẹ.

Augusta ati Salome lo jọ pe ọwọ ololufẹ ni wọn ti pade iku, Bamise Ayanwole ko tiẹ lọdọ ajoji ọkunrin ni.

Ayanwole kuro nibi iṣẹ rẹ ni Ajah, ipinlẹ Eko, o n lọ sile ẹgbọn rẹ ọkunrin lọjọ naa loṣu Keji ọdun 2022, ṣugbọn ko debẹ to fi pade iku.

Ọrọ to sọ gbẹyin ni atẹjiṣẹ ohùn to fi ranṣẹ si ọrẹ rẹ kan nigba to wa ninu mọto BRT, nibi to ti n sọ fun ọrẹ naa pe bi awakọ ọhun ṣe n ṣe ko ye oun.

Ọjọ kẹsan-an ni wọn ri oku rẹ lẹyin ọrọ naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti dajọ iku fun Andrew Ominikoron, awakọ BRT naa, awọn ẹbi oloogbe Bamise sọ pe idajọ naa ko dun mọ awọn.

Wọn ni awọn ti wọn jọ pa Bamise ko ti i jẹjọ, wọn tun ni ki lo de ti wọn ko gbe esi ayẹwo awọn DNA kan ti wọn ṣe sita.

Onaopemipo Damilola to jẹ ẹgbọn fun Bamise, bu ẹnu atẹ lu bi ile ẹjọ ṣe mu ọrọ naa. O ni wọn ko yara si i rara.

"O n bi eeyan ninu gan-an, ka maa lọ si kootu ni gbogbo igba ki nnkan gidi kan ma si tibẹ wa."

Ẹgbọn Bamise lo sọ bẹẹ loṣu Keji ọdun yii.

"Ọpọ igba, agbẹjọro olujẹjọ ko ni i yọju, eyi to si mu ẹjọ naa pẹ nilẹ."

Aworan obinrin ati awọn ọkunrin meji ti wọn n beere idajọ ododo fun Bamise.

Ìdájọ́ òdodo ṣoro

Ko si ofin kan pato ninu alakalẹ ofin Naijiria to sọrọ nipa pipa obinrin lati ọwọ ọkunrin. Eyi lo fi jẹ pe ọpọ eeyan to ba padanu ọmọ wọn siru nnkan bayii ki i saba ri idajọ ododo.

"Ko si ẹnikẹni ninu awọn ẹjọ iku obinrin ta a n gbọ ni DOHS to ti ri idajọ ododo gba. Ajayi Ololade,oludasilẹ ajọ naa lo ṣalaye eyi.

O ni ẹjọ pipẹ, ki afurasi sa lọ ati idajọ ti ko kun to si jẹ idi ti idajọ ododo fi ṣoro lati ri.

O fi kun un pe niṣe lawọn kan tiẹ tun maa n bu obinrin to di oloogbe naa, eyi si maa n jẹ kawọn ẹbi wọn kuku jawọ ninu ẹjọ naa.

"Ọpọ eeyan lo bu mi, wọn ni mi o kọ ọmọbinrin mi daadaa, ohun to jẹ ki ọmọ yahoo lo o fun oogun owo niyẹn.

Iya Augusta lo fi eyi kun ọrọ rẹ.

Iru rẹ naa ni awọn kan ṣafihan rẹ loju opo X, nigba ti Salome Adaidu ku loṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Bi wọn ṣe n bu ẹbi awọn obinrin to ku yii n jẹ ẹdun ọkan fawọn ajafẹtọọ obinrin, wọn ni o ṣee ṣe kawọn ẹbi ma fẹẹ gbe igbesẹ lori iku naa mọ, eyi to le fa ki ẹlẹṣẹ lọ lai jiya ẹṣẹ.

"Kaka ka maa gbogun ti iku obinrin lati ọwọ ọkunrin, ohun ti obinrin ti wọn pa wọ lawọn mi-in yoo maa sọrọ nipa rẹ. Ẹlomi-in yoo sọ pe ẹni ti wọn pa lo munu bi ẹni to pa. "

Bẹẹ ni Ajayi Ololade, wi.