Wo ìrànlọ́wọ́ tó yẹ kí o ṣe fún ẹni tí rọpárọsẹ̀ bá kọlù lójijì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Rọparọsẹ le ṣẹlẹ si ẹnikẹni nibikibi, nigbakugba. Nile, nibi iṣẹ, lojuu popo, koda nigba ti eeyan ba n sọrọ lọwọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ.
Aisan rọparọsẹ ti oyinbo n pe ni 'Stroke', maa n ṣẹlẹ lai fi apẹẹrẹ han nigba mi-in, ko si ni i kilọ ko too ṣẹlẹ si ẹnikẹni.
Bo ṣe waa jẹ ohun ti ki i sọ tẹlẹ naa lo tun jẹ ohun ti eeyan ko gbọdọ fi akoko ṣofo le lori.
Bo ti wu ko kere to, akoko diẹ ti eeyan ba fi ṣofo ko too bẹrẹ itọju rọparọsẹ le di isọro nla, o si le fa iku ẹni ti aisan naa kọlu.
Ṣugbọn ọpọ eeyan ni ko mọ awọn ohun to yẹ ki wọn sare ṣe bi rọparọsẹ ba kọlu ẹnikan, ko too di pe dokita yoo de lati tọju rẹ.
Eyi lo mu BBC tọ Dokita Salihu Ibrahim Kwaifa, lọ. Onimọ nipa aisan rọparọsẹ niluu Abuja ni ọkunrin naa, lati ṣalaye ohun to yẹ ki o mọ nipa itọju aisan yii lati ran ẹni to ba ṣẹlẹ si lọwọ.
Ìtọ́jú àkọ́kọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi Dokita Kwalifa ṣe ṣalaye, rọparọsẹ maa n waye nigba ti ẹjẹ ba dì, ti opo to n gbe ẹjẹ lọ sinu ọpọlọ ko ba le gbe ẹjẹ lọ sibẹ mọ, tabi ti opo ẹjẹ ba bẹ, ti ẹjẹ ko raye denu ọpọlọ mọ.
Nigba to si jẹ pe ọkọ̀ pajawiri (ambulance) to n gbe oku ati alaye ki i tete de ni Naijiria, tabi ko ma tete de ọdọ ẹni ti rọparọsẹ kọlu, awọn to ba wa nitosi ẹni bẹẹ gbọdọ mọ itọju akọkọ yii lati ṣe:
- Fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún tàbí ti òsì ẹni náè lélẹ̀:Bi rọparọsẹ ba ṣẹṣẹ kọlu ẹnikan, ma ṣe fi ẹyin ẹni naa lelẹ lori ibusun pẹlu ahọn rẹ to yọ sita. Ahọn to yọ sita naa le di ọna ti yoo gba mí, eyi si le fa iku fun un.Ẹgbẹ ọtun tabi ti osi ẹni naa ni ko o fi lelẹ lori ibusun.
- *Rí i dájú pé ẹni náà ń mí dáadáa :Dokita Kwaifa ṣalaye, pe, "Ti o ba fẹẹ ri i daju pe ẹni naa n mi, fi ọwọ kan apa rẹ tabi ibi ọrun rẹ nibi ti mimi ti maa n han, wa a ri i pe o n mi.
- Mu aṣọ tabi ohunkohun to le di mimi rẹ lọwọ kuro lọrun ati aya rẹ, ki ẹni naa le mi daadaa.
- Mu ohunkohun to ba le pa a lara kuro pẹlu.
- Ma ṣe fun ẹni naa ni ounjẹ, omi tabi oogun kankan lo.
Àpẹẹrẹ rọpárọsẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọna meji ni rọparọsẹ pin si, bi Dokita Kwalifa ṣe ṣalaye.
Akọkọ ni rọparọsẹ to waye latari aito ẹjẹ to n lọ sinu ọkan.
Ikeji ni eyi to ṣẹlẹ latari ẹjẹ to di to si tuka sinu ọpọlọ tabi si itosi rẹ.
Awọn apẹẹrẹ ti ẹni ti rọparọsẹ kọlu yoo maa ri ni
- Yoo jọ pe ara rẹ n wuwo
- Ẹni naa yoo ri i pe oju oun kan ko riran mọ.
- Oju rẹ yoo yi si ẹgbẹ kan.
- Ara rẹ yoo maa da bii ẹni ti pajapaja mu.
- Ko ni i le sọrọ.
Lẹyin wakati kan ṣa, Dokita sọ pe awọn apẹẹrẹ yii yoo poora.
"Ẹni to ba koju apẹerẹ wọnyi ni ida aaọrin si ọgọrin (70 to 80 percent), bi ko ba tọju ara rẹ daadaa, rọparọsẹ yoo kọlu u laaarin oṣu kan si oṣu meji."
Dokita Kwalifa lo ṣalaye bẹẹ.
O ni rọparọsẹ naa yoo ṣẹlẹ nigba ti ẹni naa ko ba mọ nnkan to n ṣẹlẹ layika rẹ mọ, ori ko si ni i fọ ọ ti yoo fi ri i pe ọwọ ati ẹsẹ ti rọ.
Fun ti rọparọsẹ ti ẹjẹ di sinu ọpọlọ tabi itosi rẹ, Dokita Kwalifa sọ pe:
"Bi iru rọparọsẹ yii ba waye, ẹni naa yoo ṣubu lulẹ, ko ni i mọ nnkan kan mọ.
Ṣugbọn ṣiwaju akoko naa, ori yoo maa fọ ọ, yoo si rẹ ẹ.
Kí ló ń fa rọpárọsẹ̀?

Oríṣun àwòrán, SPL
Awọn ohun to n fa rọparọsẹ ni Naijiria ati ilẹ Africa lapapọ pọ, bi Dokita Kwaifa ṣe ṣalaye, lara wọn ni:
Ẹjẹ riru: Eyi jẹ idi kan pataki tawọn eeyan maa fi n ni aisan ọkan, awọn to ba si ti ni i le lugbadi rọparọsẹ.
Itọ ṣuga: Nnkan keji to tun n fa rọparọsẹ ju lẹyin ẹjẹ riru ni aisan itọ ṣuga(Diabetes).
Awọn eeyan to ba ni itọ ṣuga wa ninu ewu ati ni rọparọsẹ.
Aisan ọkan: Dokita Kwaifa ṣalaye pe aisan ọkan naa le fa rọparọsẹ.
Arun ko-gboogun (HIV)
Bí o ṣe lè dènà rọpárọsẹ̀
Dokita ka awọn ọna yii:
- Jijẹ ounjẹ to dara to si n ṣe ara loore.
- Ṣiṣe ere idaraya deede.
- Yago fun mimu siga ati ọti.
- Ṣe itọju itọ ṣuga ti o ba ni.
- Maa yẹ ifunpa rẹ wo deede.
- Din wahala ṣiṣe ku
- Kan si dokita rẹ deede.
" Ai ki i lọ sileewosan lati ṣalaye nigba tawọn eeyan ba kọkọ ri awọn apẹẹrẹ yii lo n fa a to fi n di rọparọsẹ mọ wọn lọwọ. "
" Iṣẹ aye kọ leyi, gba ileewosan lọ lasiko to yẹ"
Dokita Kwalifa lo wi bẹẹ.














