Ilé-ẹjọ́ ju ọmọge tó pé 'Bàbá Aláàánú' rẹ̀ lẹ́jọ́ sẹ́wọ̀n

Oríṣun àwòrán, EYEAMDHAT/INSTAGRAM
Arabinrin kan to n ṣiṣẹ ni banki kan ni Ghana ni ile-ẹjọ ni ko lọ ma a gba atẹgun lọgba ẹwọn.
Ile-ẹjọ giga lo gbe idajọ kalẹ fun Deborah Seyram Adablah lẹyin ti iwadii fihan pe o "kọlu adajọ" ti o joko lori ẹjọ kan to pe lati fi ẹsun kan ọga naa pe "o rufin ileri ati ifipabanilopo".
Seyram lo pe ẹjọ tako Baba alaanu rẹ, ti wọn n pe ni Sugar Daddy , Ernest Kwasi Nimako pe o kuna lati mu awọn ileri to ṣe fun wa si imuṣẹ.
Gẹgẹ bi Seyram ṣe sọ, ọkunrin naa to jẹ ọga ni ẹka eto inawo ni banki ṣeleri pe oun yoo maa tọju oun.
O tun tọ ka si ninu awọn iwe ile-ẹjọ to pe , pe 'sugar daddy' ọhun ṣe ileri lati fun ni owo lati dokowo, owo ile ọdun mẹta, ọkọ ayọkẹlẹ kan, alawansi oṣooṣu ati owo itọju nile iwosan.
Sugbon Sugar Daddy yii kuna lati mu gbogbo awọn ileri yii sẹ lẹyin ti opin de si ifẹ aarin wọn
Nitori idi eyi, Seyram sọ pe oun ko ni da ọkọ ayọkẹlẹ ti Sugar Daddy ra fun pada, ti wọn si morile ile ẹjọ
Ni ọjọ kẹrindinlogun, osu karun-un ọdun 2023, ile-ẹjọ giga palaṣẹ fun Seyram ko fi ọkọ ayọkẹlẹ to n ba 'sugar-daddy' rẹ ja le lori, ranṣẹ si akọwe ile-ẹjọ.
Adajọ ile ẹjọ, Olivia Obeng Owusu ni ki olupẹjọ gbe ọkọ naa kalẹ titi igbẹjọ yoo fi pari.
Ki lo ṣẹlẹ ni ile-ẹjọ?
Lara idajo ile-ẹjọ naa tun ni pe ki Sugar Daddy ọhun, to tun jẹ diakoni ninu ijọ, Ọgbẹni Ernest Nimako, pe ki o fi iwe ọkọ silẹ fun ile-ẹjọ.
Ile-ẹjọ tun paṣẹ pe ki olufisun dẹkun sisọ ọrọ naa lori ayelujara.
Ni Oṣu Keje ọdun 2023, ile-ẹjọ yọ orukọ banki kuro ninu ẹjọ naa lẹyin ti awọn agbẹjọro gbe ọrọ kalẹ.
Ile-ẹjọ tun paṣẹ fun Seyram pe ki o 6,000 Ghc nitori o darukọ orukọ banki ninu ẹjọ to ni ṣe pẹlu oṣiṣẹ wọn.
Ṣugbọn ni ọjọ kejidinlọgbọn Oṣu kọkanla ọdun 2023, ile-ẹjọ labẹ adajọ John Bosco Nabarese wagile ẹjọ ti wọn pe tako oṣiṣẹ banki naa.
Ile ẹjọ sọ pe bo ti ẹ jẹ́ pe ajọṣe to wa laarin Seyram ati ọga eka inawo banki jẹ "ìwà palapala to lodì si awujọ, ko sí ohun to fa a tí wọ́n fi gbe igbesẹ."
Ki lo fa ti ile ẹjọ fi ran obinrin naa lọ si ẹwọn?
Bi igbẹjọ naa ṣe n tẹsiwaju ni Deborah Seyram Adablah, di ilumọka lori ayelujara, to si n lo oju opo TikTok lati sọrọ nipa igbẹjọ naa.
Ninu fọnran ti wọn gbe wa si ile - ẹjọ, olupẹjọ naa sọ pe adajọ n fi sibi kan lori igbẹjọ.
O bẹrẹ sini pariwo ni ilẹ-ẹjọ, to si fẹsun kan ẹka idajọ pe ti eeyan ko ba ni agbara, ko le ri idajọ ododo gba.
O fẹsun kan adajọ kan, John Bosco pe ko ṣe ohun to tọ.
O ni "adajọ ni gbọdọ ṣetan lati foju wina wahala, ti ko ba ṣe ohun to tọ nipa idajọ rẹ". O sọ loju opo Tiktok.
Eyi lo fa ti ile-ẹjọ fi palaṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn mu olupẹjọ.
Adajọ wa paṣẹ pe ki wọn fi olupẹjọ si ọgba ẹwọn fun ogoji ọjọ.















