Agbébọn kọlu ibùdó ọmọ ogun Naijiria, wọ́n jí ọ̀pọ̀ sọ́jà gbé lọ

Ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Borno ti sọ pe awọn ọmọ ikọ agbebọn ti kọlu ibudo awọn ologun ti wọn si ji awọn ọmọ ogun kan gbe lọ.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe awọn alakatakiti ẹsin naa kọlu ibudo Forward Operation Base ti ẹka 153 Task Force Battalion, nibi ti wọn to gbẹmi awọn ọmọ ogun kan.

A gbọ pe nnkan bii aago mẹta afẹmọju ọjọ Aje lawọn agbebọn naa kọlu ibudo ọhun lori alupupu ati oniruru ọkọ ogun ti wọn si ṣọṣẹ.

Lẹyin ikọlu naa lawọn ọmọ ogun salọ si ibudo 24 Task Force Brigade nibi ti wọn ti ko ara wọn jọ lati pada lọ gba ibudo wọn pada lọwọ awọn agbesunmọmi naa.

Ija ọhun le to bẹẹ, bi iro ibọn ṣe n dun lakọlakọ naa ni ọta ibọn n fo sọtun ati osi.

Oṣojumi koro kan sọ fun awọn akọroyin pe "Awọn agbesunmọmi naa dana sun ọkọ ayẹta ileeṣẹ ọmọ ogun, wọn si ko ọpọ ohun ija oloro lọ nibẹ pẹlu."

Titi di asiko ti a ko iroyin yi jọ, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ko tii sọ nnkankan lori ikọlu naa.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni oniruru ikọlu ti n waye ni Naijiria eyii ti wọn fi ori rẹ sọ ikọ Boko Haram ati ojugba rẹ ni iwọ oorun Afrika, ISWAP.

Ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti da ipaya sọkan ọpọ araalu paapaa ni bayii ti wọn ti n lo oniruru imọ ẹrọ drone atawọn ohun ija igbalode mii.