Lateef Adedimeji, Mercy Aigbe, àti àwọn mìí bá BBC sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ̀ AMVCA

Àkọlé fídíò,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Awọn gbajumọ oṣere bii Mercy Aigbe, Femi Adebayo ati Lateef Adedimeji ati iyawo rẹ, Adebimpe Oyebade, jawe olubori nibi ami ẹyẹ AMVCA.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun un ọdun 2025, ni eto naa waye niluu Eko.

Orisirisi ara lo waye nibi ami ẹyẹ African Magic Video Choice Awards ti ọdun 2025.

Bi aṣọ ṣe n pe aṣọ ran niṣẹ, ni awọn irun ati awọn nnkan iṣaraloge naa ko gbẹhin laarin awọn olukuluku eeyan to kopa nibi eto naa to waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹwaa oṣu Karun-un.

Ami ẹyẹ naa ni wọn fi n mọ riri awọn oṣere, olukọtan, adari ere, ati awọn iṣẹ miran ni ẹ̀ka amuludun fiimu ati sinima, nilẹ Africa.

Lateef Adedimeji

Fiimu ti Femi Adebayo gbe jade, Seven Doors, ni wọn fi orukọ rẹ silẹ fun ami ẹyẹ to pọ julọ - ami ẹyẹ mọkanla.

Lisabi (The Uprising) fiimu Lateef ati Bimpe Adedimeji, lo wa ni ipo keji gẹgẹ bi fiimu ti wọn fi orukọ rẹ silẹ julọ - ami ẹyẹ mẹwaa ni tiẹ, amọ mẹta ninu rẹ lo ti jawe olubori.