Ọwọ́ NDLEA tẹ obìnrin tó gbé òògùn olóró pamọ́ sójú ara rẹ̀ lọ sí Iran

Miracle Obehi ti NDLEA

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti kede pe ọwọ oun ti ba obinrin kan, Ihensekhien Miracle Obehi, to fẹẹ kọja si orilẹede Iran pẹlu oogun oloro rẹpẹtẹ to gbe pamọ si oju ara rẹ.

Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un ọdun 2025 ni NDELA kede, pe awọn dena irinajo ọhun nigba ti wọn mu obinrin naa ni papakọ ofurufu Port Harcourt, ipinlẹ Rivers.

Atẹjade ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi, fi ṣọwọ si ẹka iroyin Channels, ṣalaye pe yatọ si oju ara ti iya naa gbe oogun oloro si, o tun ko awọn kan si ikun rẹ.

Bakan naa ni wọn lo tun ko oogun oloro ta a mọ si cocaine naa pamọ si isalẹ apo apamọwọ atọwọda rẹ pẹlu.

Bi NDLEA ṣe wi, hijaabu ti awọn obinrin Musulumi maa n wọ ni Obehi wọ lati bo aṣiri ara rẹ ki wọn ma baa mu un.

O fi kun un pe ọjọ kẹta, oṣu Karun-un 2025, ni wọn nawọ gan Miracle nigba to fẹẹ wọ ọkọ ofurufu Qatar Airline lọ si Iran.

Báwo ni òògùn olóró náà ṣe pọ to?

Ninu alaye agbẹnusọ NDLEA lori iṣẹlẹ yii, o ni nigba ti ajọ naa n yẹ ara Obehi wo, awọn ri i pe ìdì mẹta cocaine lo fi pamọ si oju ara.

Ìdì nla-nla oogun oloro naa lo si tun fi si apa kan apo atọwọda to wa nisalẹ baagi rẹ.

Ẹyọ cocaine mẹtadinlaadọrin( 67) ni wọn si ni o gbe mi.

Eyi lo jẹ ki wọn lo ilana igbọnsẹ ṣiṣẹ fun un lati ya awọn oogun naa, wọn si n ṣọ ọ to fi ya wọn.

Lẹyin igbọnsẹ to fi ọjọ meloo kan ṣe, Miracle ya cocaine 67 bi NDLEA ṣe fidi ẹ mulẹ.

Ajọ naa sọ pe Obehi ṣalaye pe aadọrin oogun oloro naa (70 pellets) lo yẹ koun gbe mi, ṣugbọn lẹyin toun gbe 67 mi tan ni agbara oun ko gbe e mọ.

O ni eyi loun ṣe fi mẹta to ku pamọ si oju ara.

Lapapọ, odiwọn cocaine ti Obehi fi hijaabu bo mọra jẹ 2.523 kilograms, bi NDLEA ṣe sọ.

Àwọn míràn tọ́wọ́ tún bà fún ẹ̀sùn kan náà

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

NDLEA ṣalaye bi ọwọ ofin ṣe ba ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan, Campell Kaizra Kofi Johannes Slifer, ẹni ọdun mejilelogun to gbe oogun oloro 'Loud' ti iwọn rẹ jẹ 37.60kg.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un 2025 yii ni wọn mu Campell ni papakọ ofurufu Murtala Mohammed International Airport, Ikeja,l'Ekoo.

Orilẹede Thailand ni wọn lo ti n bọ, o si fẹẹ ba ọkọ ofurufu Qatar gunlẹ si Naijiria pẹlu apamọwọ meji to di awọn egbogi naa si .

Marundinlogoji ni gbogbo oogun oloro naa ninu apamọwọ gẹgẹ bi alaye NDLEA.

Campell, ṣalaye pe ẹẹmeji ni wọn ti ju oun sẹwọn ni UK fun oogun oloro ati idigunjale.

O ni London ni wọn ti fun oun niṣẹ pe koun lọ si Thailand lati gbe oogun oloro wọ Naijiria.

Eyi to farapẹ ni ti awọn mẹrin kan tọwọ ajọ yii tun ba nipinlẹ Niger.

Awọn eeyan naa ni: Christopher Onyema, Benedict Etineruba Young, Chukwudi Ujue Jerry, ati Mohammed Abdullahi Danasabe.

Ọkọ tanka kan ati ọkọ mẹta mi-in ni wọn ko egbogi oloro ti wọn n pe ni 'Skunk', si.

Apo skunk naa si jẹ ọọdunrun din mẹrinla (246).

Oju ọna Suleja-Kaduna nipinlẹ Niger ni NDLEA loun ti fi ọwọ ofin mu wọn.

Yatọ si tirela to n gbe epo naa, ajọ yii tun gba bọọsi Honda Odyssey kan ti nọmba ẹ jẹ YAB 667 CZ; bọọsi akero kan to ni nọmba GWA 125 TQ, ati bọọsi Honda Odyssey toun ni nọmba ABJ 230 CN lọwọ awọn afurasi naa.