Ìjàmbá tírélà ré kọ̀nténà lu ''dispatch rider' méjì l'Eko, wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lójú ẹsẹ̀

Aworan awọn tirela naa.

Oríṣun àwòrán, Channels TV. com

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla oṣu Karun-un ọdun 2025 yii ni awọn ọkunrin ọlọkada meji kan pade iku ojiji, nigba ti tirela meji fori kọlu ara wọn lori Eko bridge, ipinlẹ Eko.

Ẹka to n ri si ilanilọye nileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ l'Ekoo, (LASTMA) fidi iṣẹlẹ ijamba naa mulẹ.

Adebayo Taofiq, Adari ẹka naa ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe, ọkan ninu awọn dẹrẹba to wa tirela lo n sare asapajude.

O ni bo ṣe n sare naa lo si tun n toogbe. Oorun to n kun awakọ naa lo ni o jẹ ko padanu ijanu ọkọ to si lọọ kọlu tirela miran to n lọ niwaju rẹ.

Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí?

Gẹgẹ bi atẹjade LASTMA, ikọlu naa fa ijamba miran, o mu ki kọntena to wa lori ọkan lara awọn tirela naa wo lu awọn ọlọkada abanifẹru ranṣẹ ti a mọ si dispatch rider, to n kọja lọ lasiko naa.

Ẹsẹkeṣẹ ni awọn ọkunrin ọlọkada mejeeji ku, gẹgẹ bi alaye LASTMA.

Adari ẹka ilaniloye ajọ naa fi kun un pe awọn tete debẹ, awọn si gbe dẹrẹba kan ti oun naa farapa pupọ ninu ijamba ọhun lọ sile iwosan.

Ṣugbọn awọn dẹrẹba to wa tirela mejeeji sa lọ ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, LASTMA fidi eyi mulẹ.

Ọga agba pata fun ajọ naa, Olalekan Bakare-Oki, ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi awọn to padanu ẹmi, bẹẹ lo rọ awọn awakọ lati fi ọmọluabi kun wiwa mọto wọn.

O ni ki ẹni to fẹẹ wakọ ri i daju pe oorun ko kun oun, o si gbọdọ fi gbogbo ọkan wa ọkọ.

Mọto to fẹẹ gbe sọna gbọdọ wa laaye to yẹ fun pópó pẹlu, lati dena iku ijamba ati iku ojiji.