Ìgalà fa ìjàmbá fún bàálù Air Peace, ó tún ṣàkóbá fún ìrìnàjò òfurufú ní Delta

Oríṣun àwòrán, Michael Achimugu/X
Ijamba ọkọ ofurufu ṣẹlẹ nigba ti baalu Air Peace tawọn ero wa ninu rẹ kọlu ẹranko igbo nla kan ni papakọ ofurufu ilu Asaba nipinlẹ Delta.
Ijamba yii waye lọjọ Abamẹta to kọja lasiko ti baalu naa n sare lori ilẹ nigba to fẹ gbera lọ soke.
Ṣadeedee ni ẹran ẹtu naa jana mọ baalu ọhun lẹnu ti baalu naa si ṣeku pa a.
Baalu yii ko le rin mọ lẹyin to kọlu ẹranko igbẹ naa tan lopopona rẹ ni papakọ ofurufu ilu Asaba.
Iṣẹlẹ yii ni ko si jẹ ki baalu naa le rin gbogbo irinajo to yẹ ko rin mọ, to si tun ṣakoba fawọn baalu mii to fẹ gbera lopopona ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni papakọ ofurufu Asaba.
Nigba ti o n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ loju opo X rẹ, ọga agba ẹka ajọ NCAA to n ri si ọrọ to n lọ ati didaabo bo ẹtọ awọn onibaara nileeṣẹ ọkọ ofurufu Naijiria, Ọgbẹni Michael Achimugu, sọ pe baalu ọhun pa ẹranko igbo to jana mọ lẹnu naa, iṣẹlẹ ọhun si tun ṣakoba fawọn nnkan mii.

Oríṣun àwòrán, Michael Achimugu/X
''Lọjọ Abamẹta opin ọsẹ to kọja ni baalu Air Peace gba ẹtu nla kan ti o si pa ẹranko igbo naa.
Iṣẹlẹ yii ni ko si jẹ ki baalu naa le rin mọ ti o si wa loju kan naa,'' Ọgbẹni Achimugu lo sọ bẹẹ.
O ni iṣẹlẹ yii ni ko le jẹ ki baalu naa le lọ gbogbo irinajo to yẹ ko lọ mọ.
Ọgbẹni Achimugu sọ pe lẹsẹkẹsẹ lawọn akọṣẹmọṣẹ onimọ ẹrọ ti bẹrẹ iṣẹ lori ati tun baalu naa ṣe.
Ọgagba ẹka ajọ NCAA to n ri si ọrọ to n lọ ati didaabọ bo ẹtọ awọn onibaara ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria ni awọn ero inu baalu naa fa ibinu yọ tori idaduro ti iṣẹlẹ naa mu wa fun wọn.
''Irufẹ iṣẹlẹ bayii jẹ ṣababi tori kii ṣe ẹbi ileeṣẹ ọkọ ofurufu, lairo tẹlẹ ni o kan ṣẹlẹ.
Mi o sọrọ yii lati gbe lẹyin awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu bi ko ṣe lati ṣe apujuwe nnkan to le ṣẹlẹ nigba mii,'' Achimugu ṣalaye.
Ọgbẹni Achimugu fikun ọrọ rẹ pe ojuṣe ileeṣẹ ọkọ ofurufu si ni lati ṣalaye fawọn ero ọkọ baalu to gba ẹranko igbẹ yii lori bi wọn ṣe le gba owo wọn pada.
O ni ileeṣẹ ọkọ ofurufu tọrọ kan si le san faini ti wọn ko ba tete da owo awọn ero to wa niluu baalu naa pada.
Ọgbẹni Achimugu tun sọ pe iṣẹ si n lọ lori baalu naa lati ri pe o bẹrẹ iṣẹ pada laipẹ.















