Ìdí rèé tí iṣẹ́ ìtọ́jú èèyàn táwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ń ṣe ní UK yóò fi dópin láìpẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba orilẹede UK ti ṣetan lati fopin si gbigba awọn eeyan lati ilẹ okeere fun ṣiṣe itọju eeyan lorilẹede naa.
Akọwe ijọba Uk labẹle, Yvette Cooper, lo fidi ọrọ yii mulẹ nigba to sọ fun BBC wi pe eyi wa lara igbesẹ ijọba lati mu adinku ba fifun awọn ọmọ ilẹ okeere ni fisa lati wa maa ṣiṣẹ ti ko nilo iwe ẹri nla ni UK.
''Asiko ti to lati fopin si gbigba awọn oṣiṣẹ to n ṣetọju awọn eeyan lati ilẹ okeere, ayipada yoo ba eleyii lọdun to n bọ.
Ohun ti yoo ṣẹlẹ ni pe awọn ileeṣẹ to ba nilo iru awọn oṣiṣẹ bẹẹ yoo maa gbawọn eeyan to n gbe ni UK siṣẹ, tabi ki wọn maa lo awọn eeyan to ti n ṣe iru iṣẹ yii ni UK tẹlẹ,'' Cooper lo sọ bẹẹ.
Ijọba UK n gbero lati kede oniruuru atunṣe ati ayipada lori gbigba fisa wa si UK ati ofin to ni ṣe pẹlu igbanisiṣẹ lọjọ Aje ọjọ kejila oṣu Karun un yii.
Ijọba gbe igbesẹ yii lati mu adinku ba iye eeyan to wọle si Uk.
Ijọba n gbero lati sọ awọn oṣiṣẹ ti ko nilo iwe ẹri nla lati ṣiṣẹ ni UK di ẹgbẹrun lọna aadọta titi ọdun to n bọ.
Ẹwẹ, Chris Phlip to jẹ akọwe abẹnu to n tọpinpin nnkan ti ijọba n ṣe ni UK sọ pe o yẹ ki ijọba ṣe kọja nnkan ti wọn kede lọ.
Eeyan 906,000 ni akọsilẹ fi han pe o wọle si UK lọdun 2023,
Oriṣiiriṣii ijọba to ti wa lori aleefa sẹyin lo ti gbiyanju lati mu adinku ba iye eeyan to n wọle si UK lọdun, amọ, ti ko kẹsẹ jari.
Eeyan ti ko din ni 906,000 ni akọsilẹ fi han pe o wọle si UK lọdun 2023, nigba ti 728,000 wọ orilẹede naa lọdun 2024.
Akọwe ijọba abẹnu ko tii sọ gbedeke iye eeyan ti yoo maa wọ UK lọdun ninu ikede ti wọn fẹ ṣe lọjọ Aje ọjọ kejila oṣu yii.
Ṣugbọn Cooper sọ fun BBC wi pe ayipada orin lori awọn ọmọ ilẹ okeere ti wọn n ṣiṣẹ itọju eeyan ni UK yoo bẹrẹ diẹdiẹ laarin ọdun yii.
Cooper fikun ọrọ rẹ pe ijọba ko ni sọ gbedeke iye eeyan ti yoo maa wọle si UK lọdun.
Amọ, Ọgbẹni Philip ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu Conservatives yoo dabaa wi pe ki ile igbimọ aṣofin fẹnuko lori gbedeke iye eeyan ti yoo maa wọ UK lọdun.
Cooper tun sọ pe ayipada yoo tun ba ofin to de awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere atawọn ti wọn ti kẹkọọ gboye.
''A o tẹsiwaju lati maa jẹ kawọn eeyan maa wa kawe ni UK ati ṣiṣẹ lẹyin ti wọn ba kawe gboye tan,'' Cooper ṣalaye.
Ijọba ti ṣe ayipada ofin to de awọn ọmọ ilẹ okeere to n wa si UK lati ṣiṣẹ itọju eeyan.
Lati ọjọ kẹsan an oṣu Kẹrin to lọ, ẹnikẹni to ba fẹ gba oṣiṣẹ itọju eeyan gbọdọ kọkọ wa eeyan fun iru isẹ bẹẹ ni UK na.
Ofin tuntun sọ wi pe awọn ileeṣẹ to ba fẹ gbawọn oṣiṣẹ lati okeere siṣẹ awọn to n tọju eeyan gbọdọ kọkọ wa ninu awọn 10,000 iru awọn oṣiṣẹ bẹẹ to wa ni UK, ki wọn to le gbe igbesẹ lati gba oṣisẹ kankan lati ilẹ okeere.
Cooper tun fikun ọrọ rẹ pe ijọba yoo ṣe alekun owo oṣu awọn to n ṣiṣẹ itọju eeyan yii ki iṣẹ naa le wu awọn to n gbe UK lati ṣe.















