Ìjọba UK kéde ìlànà tuntun tí yóò bẹ́gi dínà àwọn tó fẹ́ kàwé, ṣiṣẹ́ tàbí gbé níbẹ̀

Ẹnu ibode orilẹede UK

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Keir Starmer, ti gbe awọn igbesẹ tuntun lati jẹ ko le koko fun awọn ọmọ ilẹ okeere lati kawe, ṣiṣẹ tabi gbe lorilẹede naa.

Lara awọn igbesẹ naa ni bi wọn ṣe sọ ọ di dandan lati ṣe idanwo ti yoo fi han pe awọn eeyan naa gbọ, wọn si le sọ ede Gẹẹsi.

Olootu ijọba naa tun ni, ijọba fẹ mu adinku ba iye awọn oṣiṣẹ olutọju alaisan, ti wọn n gba lati ilẹ okeere ati iye ọdun ti eeyan gbọdọ gbe nilẹ ọhun ko to di ọmọ oniluu.

Amọ ko mẹnuba awọn to n wọ ilẹ naa lọna ti ko ba ofin mu, bii awọn to n gba ori omi wọle.

Gẹgẹ bii atẹjade ijọba ilẹ ọhun, 728,000 ọmọ ilẹ okeere lo wọ orilẹede United Kingdom nigba ti yoo fi di inu oṣu Kẹfa ọdun 2024.

Lara awọn igbesẹ tuntun naa ni alakalẹ tuntun nipa awọn to ba fẹ kawe tabi ṣisẹ ni UK.

Starmer sọ pe igbesẹ yii yoo dina mọ eeyan bii ẹgbẹrun lọna aadota awọn ti ko ni iṣẹ kankan ninu awọn to n wọ ilẹ naa lọdọọdun.

Awọn ọmọ orilẹede Nigeria, Pakistan ati Sri Lanka wa lara awọn ti igbesẹ tuntun yii yoo pa lara julọ.

Keir Starmer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki ni igbesẹ yii n tumọ si?

Ṣaju ni awọn akẹkọọjade le duro si United Kingdom fun ọdun meji gbako lẹyin ẹkọ wọn lati ṣisẹ, ṣugbọn ni bayii, ijọba ni wọn ko ni le lo ju ọdun kan abọ pere lọ.

Bẹẹ naa ni wọn tun ti ṣatunṣe si iye ọjọ ti eeyan le fi gbe ni UK ko to di ọmọ oniluu.

Bawo ni ọro yii ṣe kan ọ gẹgẹ bii ọmọ Naijiria?

Lati mọ irufẹ ipalara ti ikede naa yo ṣe fun ọmọ Naijiira, BBC kan si agbẹjọro Audu Bulama Bukarti to sọ pe igbesẹ naa yoo ṣe akoba nla fun awọn ọmọ Naijiria kan to fẹ japa lọ UK.

Bukarti sọ fun BBC Hausa pe "nnkan ti le bayii fun awọn to ti n gbe nibẹ fun ọpọ ọdun pẹlu igbagbọ pe wọn ko ni pẹ di ọmọ oniluu.

"O ti ṣoro fun awọn to fẹ japa lati lọ maa tọju awọn arugbo, awọn to ti wa nibẹ tẹlẹ ni lati san owo gọbọi ki wọn to gba iwe igbelu, bẹẹ lo ṣoro fun awọn to n mura lati lọ."

Agbẹjọro naa to n gbe nilẹ Gẹẹsi sọ pe, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko ni ootọ lẹnu nitori bi wọn yoo ṣe lọ pẹlu erongba lati kawe amọ ti wọn yo yi ohun pada ti wọn ba debẹ pe awọn fẹ sẹ atipo latari pe wọn n ni ibalopo akọsako ati ibalopọ abosabo.

Awọn koko ayipada tuntun to de ba irinajo lọ si UK

Gẹgẹ bii alaye Agbẹjọro Burkati, iwọnyii ni awọn ipenija tuntun ti awọn alejo, paapaa awọn ọmọ Naijiria yoo koju ni UK:

  • Afikun ti de ba iye ọdun wọn ti le fi gbe ni UK ki wọn to di ọmọ onilu lati ọdun marun un si ọdun mẹwaa
  • Awọn to ba fẹ ṣiṣẹ nọoṣi tabi olutọju arugbo gbọdọ ni iwe ẹri 'bachelor degree' nipa iṣẹ naa
  • Awọn akẹkọọjade ko ni le lo ju ọdun kan abọ ki wọn to pada silẹ wọn dipo ọdun meji ti aye gba wọn lati lo tẹlẹ
  • Ko si aye lati maa gba awọn olutọju arugbo lati ilẹ okere mọ, awọn ileeṣẹ gbọdọ maa lo awọn to ti wa nilẹ naa ṣaaju
  • Awọn to ba fẹ wọle gbọdọ ṣe idanwo ti yoo fi han pe wọn gbọ, wọn le kọ, bẹẹ ni wọn le sọ ede Gẹẹsi