Kí ni ìdí abájọ tí Pásítọ̀ Chris fi sọ pé òun máa jẹ iyọ̀ tó pọ̀ nínú oúnjẹ?

Aworan Pasitọ Chris Oyakhilome

Oríṣun àwòrán, Chris Oyakhilome Online

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Laipẹ yii ni ijọba apapọ kilọ fun araalu pe ki wọn rọra maa jẹ iyọ ninu ounjẹ, lẹyin ti gbajugbaja pasitọ, Chris Oyakhilome, tako bawọn onimọ nipa eto ilera kan ṣe n sọ fawọn eeyan wi pe ki wọn rọra maa jẹ iyọ lati le ta awọn oogun kan lọja.

Fidio kan ṣafihan Pasitọ Oyakhilome nibi to ti n ṣalaye pe awọn ajọ ijọba kan lo n mọ-ọn mọ sọ fawọn eeyan pe ki wọn rọra jẹ iyọ ki wọn le ri oogun to ni iyọ ninu ta kaakiri fawọn eeyan.

Amọ, ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ilera ni Naijiria ti rọ araalu lati maa tẹle imọran awọn onimọ nipa eto ilera to fi mọ imọran ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO.

Ki ni iṣepataki iyọ ninu agọ ara?

Aworan ikoko ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Salihu Ibrahim Kwaifa to n gbe niluu Abuja ṣalaye pe iyọ maa n ṣe iranwọ fun gbogbo ẹya ara.

Dokita Kwaifa sọ pe lai si iyọ ninu agọ ara, eeyan le ma le gbe ara daadaa.

''Inu agọ ara ni iyọ ti maa n ṣiṣẹ, ''sodium'' lo wa ninu ẹjẹ eeyan.

''Potassium chloride'' lo wa ninu sẹẹli, awọn nnkan meji yii lo ṣe pataki ninu ara eeyan to n jẹ ki ara maa ṣiṣẹ daadaa,'' Dokita Kwaifa lo sọ bẹẹ.

Dokita naa fikun ọrọ rẹ pe ẹni ti ko ba ni awọn eroja iyọ yii ninu ara, awọn ẹya ara rẹ ko ni ṣiṣẹ daadaa.

O ṣalaye wi pe ooyi le maa kọ iru ẹni bẹẹ, tabi ko ma tiẹ mọ nkankan mọ gan an.

Dokita Kwaifa ni ti ko ba si iyọ ninu ara, awọn oogun to wa fun itọju ọkan ati kindinrin ko ni ṣiṣẹ.

Ajọ eleto ilera lagbaaye WHO kilọ pe kawọn eeyan rọra maa jẹ iyọ ninu ounjẹ tori eyi maa n ṣokunfa aisan ẹjẹ ruru, arun jẹjẹrẹ ikun, arun kindinrin ati ara sisan ju.

Eeyan miliọnu 1.89 ni ajọ WHO sọ pe wọn n padanu ẹmi wọn lọdun latari iyọ ajẹju.

Ki ni iwọn iyọ to yẹ ki eeyan maa jẹ lojumọ?

Aworan iṣu dindin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ilera sọ ninu esi ti wọn fun Pasitọ Chris wi pe ajẹju iyọ ni ko dara, kii ṣe iyọ gan an ni ko dara.

Ajọ WHO sọ pe iwọn 4310 mg ''sodium'' eyi to jẹ iye kan naa pẹlu iwọn iyọ 5g eyi to jẹ ṣibi kan lo yẹ ki eeyan maa jẹ lojumọ.

Amọ, ajọ WHO fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan kaakiri awọn orilẹede agbaye lo maa n jẹ 10.78g iwọn iyọ eyi ti o ju ilọpo meji odiwọn iyọ to yẹ ki wọn maa jẹ lọ lojumọ.

Ileeṣẹ ijọba to n ri eto ilera ni iwadii fidi rẹ mulẹ pe ajẹju iyọ tawọn eeyan n jẹ lo n fa oriṣiiriiṣi aisan to n pa ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lọdọọdun.

Idi niyii ti ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ilera fi ṣe agbekalẹ oriṣiiriṣii eto lati ma ṣe ilanilọyẹ lori ajẹju iyọ.

Iyatọ to wa laarin iyọ ati isebẹ

Aworan oriṣiiriṣii ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara nnkan to maa n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi ni iyatọ to wa laarin iyọ ati isebẹ bii magi.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto ilera sọ pe iyọ maa n wa ninu isebẹ naa, koda, o maa n pọ ju odiwọn iyọ ṣibi kan lọ, eyi to tumọ si pe o le ṣakoba fun agọ ara.

Dokita Kwaifa sọ pe ida 60% si 70% iyọ lo wa ninu isebẹ tawọn eeyan maa n lo.

O ni o ṣe pataki lati jẹ iyọ ni iwọ tun wọn si nitori akoba to le ṣe fun ara.