Sé lóòótọ́ làwọn agbégbọn kọ lẹ́tà pé àwọn tún fẹ́ kọlu ìjọ Aguda nílùú Owo? Ohun tí a mọ̀ rèé

Inu ile ijọsin St Francis Xavier, lẹyin ti awọn agbebọn naa kọluu lọdun 2022
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iroyin to n tẹ BBC Yoruba lọwọ sọ pe awọn eeyan kan ti kọ lẹta si ijọ St. Francis Xavier Catholic Church, to wa niluu Owo, nipinlẹ Ondo pe, awọn yoo ṣe ikọlu tuntun sile ijoṣin naa.

Ọkan lara awọn ọmọ ijo naa amọ ti ko fẹ fi orukọ rẹ sita sọ pe, ibẹrubojo ti ba awọn ọmọ ijọ ọhun atawọn eeyan ilu Owo bayii nitori lẹta na naa.

Ẹni naa sọ pe niṣe ni awọn sare tete pari isin laarọ ọjọ Aiku ti onikaluku si tete gba ile wọn lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọlọpaa ti yọju sile ijọsin naa fun iwadii, amọ ọkan awọn ko balẹ.

Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 lawọn agbebọn kan yabo ile ijọsin naa, nibi ti wọn ti gbẹmi eeyan to le ni ogoji ti ọpo awọn mii si farapa.

Wayi o, ṣe lootọ lawọn agbesnumọmi to gbẹmi eeyan to le ni ogoji tun n pada bọ fun akọlu tuntun tabi awọn kọlọrọsi kan lo kan mọọmọ n fi ori ọka ṣere.

Eredi ree ti BBC Yoruba ṣe kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori ọrọ ọhun.

Lootọ ni a gbọ pe wọn fẹ kọlu ilu Owo, a ti bẹrẹ iwadii - Ọlọpaa

Aworan bi ile ijọsin naa ṣe ri lẹyin ikọlu akọkọ to waye lọdun 2022

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Aworan bi ile ijọsin naa ṣe ri lẹyin ikọlu akọkọ to waye lọdun 2022

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DPS Ayanlade Olayinka Olushola, o ni lootọ ni awọn agbofinro gbọ pe awọn kan fẹ kọlu awọn agbegbe kan niluu Owo.

Ayanlade ni "Mi o ri lẹta ṣugbọn mo ri iwe apilẹkọ iroyin ti awọn ọtẹlẹmuyẹ wa kọ, ti awọn ọtẹlẹmuyẹ mii naa si fi ransẹ si wa pe awọn kan fẹ ṣe akọlu si awọn oriko kọọkan niluu Owo.

"Eyi lo jẹ ki kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Wilfred Olatokunbo Afolabi, da awọn ọlọpaa kogberegbe ati awọn ọlọpaa ti ko wọ aṣọ si ilu Owo lana, kii dẹ n ṣe ilu Owo nikan, si gbopgbo ipinlẹ Ondo ni, lati ri daju pe ko si ipayinkeke ati idaamu."

Alukoro ọlọpaa naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe ikọlu naa ko ṣẹlẹ lasiko ti awọn gbagbọ pe o le wa waye, awọn ko sinmi iṣẹ ọfintoto ti wọn n ṣe, awọn si ti ṣẹtan lati daabo bo gbogbo eeyan ipinlẹ Ondo kuro lọwọ ikọlu kankan.

O pari ọrọ rẹ pe awọn agbofinro ko ni sinmi lati jẹ ki wọn ri pe abo to peye wa lori gbogbo olugbe ipinlẹ Ondo.

Ootọ ni awọn DSS gbọ pe ikọlu fẹ waye, amọ wọn ti gbe igbesẹ lori rẹ - Ijọba ipinle Ondo

BBC Yoruba tun kan si agbẹnusọ gomina ipinlẹ Ondo, Ebenezer Adeniyan lori nnkan ti ijọba Ondo n ṣe lori ọrọ ọhun.

Adeniyan sọ pe "Awọn ọtẹmuyẹ DSS ṣawari pe irufẹ nnkan bẹẹ fẹ waye amọ wọn ti gbe igbesẹ lori rẹ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn agbofinro mii.

"Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn kọlọrọsi naa ko ṣe ikilọ kankan ki wọn to kọlu ṣọọṣi naa lakọkọ, amọ awọn agbofinro ti ṣiṣẹ takuntakun lọsẹ to kọja lati ri pe irufẹ nnkan bẹẹ ko waye mọ niluu Owo ati ipinlẹ Ondo lapapọ.

"Titi di bi a ṣe sọrọ yii, wọn ko tii dẹkun iṣẹ ọhun."

Adeniyan pari ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ Ondo ko fi ọrọ abo awọn eeyan rẹ ṣere bẹẹ ni ko ni kawọ gbera ki awọn agbebọn kọlu ilu Owo tabi ilu mii nipinlẹ ọhun.

Wayi o, ọjọ karun un, oṣu to Kẹfa, ọdun 2025 yii ni yoo pe ọdun mẹta ti awọn agbebọn gbẹmi ọpọ eeyan ninu ijọ St Francis Catholic Owoluwa, niluu Owo.

Titi di akoko yii, awọn eeyan to padanu ẹmi wọn atawọn to farapa nibẹ ko tii ri idajọ ododo gba.