"Ojú ọ̀nà Ikare sí Ogbagi di pàkúté ikú, ẹ̀mí arìnrìnàjò ń bọ́ púpọ̀ torí ìjàmbá ọkọ̀, ìkọlù adigunjalè àtàwọn ajínigbé"

Àkọlé fídíò, "Ìjọba ẹ gbà wá lójú ọ̀nà Akure sí Ogbagi tó di pàkúté ikú, ẹ̀mí arìnrìnàjò ń bọ́ lọ́wọ́ ìjàmbá ọkọ̀ àtàwọn ajínigbé púpọ̀"
"Ojú ọ̀nà Ikare sí Ogbagi di pàkúté ikú, ẹ̀mí arìnrìnàjò ń bọ́ púpọ̀ torí ìjàmbá ọkọ̀, ìkọlù adigunjalè àtàwọn ajínigbé"

Lara ilu to se pataki nilẹ Yoruba ni ilu Ikare si Ogbagi nipinlẹ Ondo jẹ nitori oju opopona yii ni ọpọ eeyan lati ẹkun iwọ oorun Naijiria maa n gba lọ si olu ilu ilẹ wa, Abuja.

Amọ bi ọna yii, to jẹ opopona to jẹ tijọba apapọ yii ti se pataki to, naa lo tun lewu to tori ipo buruku ti oju ọna naa wa.

Ti awọn koto giriwo to wa loju ọna naa ni ka sọ ni eyi to jẹ pakute iku fun awọn onimọto ati ero inu wọn.

Abi ti ọpọ ijamba ọkọ to maa n waye loju ọna yii eyi to n mu ẹmi ọpọ eeyan lọ.

Koda, tori ipo to buru jai ti opopona yii wa, se ni awọn ajinigbe n sọsẹ lọpọ igba nibẹ, ti wọn si n ji awọn eeyan gbe lọ.

Yatọ si eyi, aarin igbo jigun-jigun ni ọna naa la kọja, eyi to mu ko rọrun fun awọn ajinigbe ati adigunjale lati han awọn arinrinajo ni eemọ.

Oju ọna Akure silu Ogbagi

Araalu n rawọ ẹbẹ si ijọba fun atunse oju ọna Ikare si Ogbagi, ki eto aabo ibẹ to mẹhẹ tẹlẹ, to dẹnu kọlẹ patapata

Bakan naa, kii se awọn arinrinajo nikan ni oju ọna yii ti gba ẹmi wọn lọsan gangan, koda, awọn araalu to n rin ẹsẹ tabi gun ọkada gan n sọ ẹmi wọn nu loju ọna iku yii.

Idi ree ti BBC Yoruba fi se abẹwo soju ọna Ikare silu Ogbagi yii lati mọ ipo aidaa ti opopna naa wa ati idi ti amojuto ati atunse kiamọsa fi gbọdọ bẹrẹ loju ọna ọhun.

Nigba ti a se abẹwo airotẹlẹ soju ọna Ikare re si Ogbagi, ọpọ awọn ọlọkọ ati araalu lo b awa sọrọ nipa ipenija ti wọn n koju loju ọna naa.

Koda, wọn tun sọ bi ijamba ọkọ, ijinigbe ati idiogunjale se n waye lemọ lemọ loju ọna naa eyi to n mu ọpọ ẹmi ati ofo dukia lọ.

Awọn eeyan yii wa rawọ ẹbẹ si ẹka ijọba ti atunse oju ọna yii gberu lati tete gbe igbesẹ to jẹ nidi atunse oju ọna yii, ki eto aabo ibẹ to mẹhẹ, to dẹnu kọlẹ patapata.

Oju ọna Akure silu Ogbagi