Jumoke George tí mọ ibi tí ọmọ rẹ̀ àmọ́ nǹkan kò fara rọ fún-un níbẹ̀ - Biola Bayo

Oríṣun àwòrán, Jumoke George
Gbajugbaja oṣere tiata, Biola Bayo to ṣe ifọrọwerọ pẹlu agba oṣerebinrin Jumoke George, ti kede pe awọn ti ṣawari ọmọ agba oṣere naa, ti wọn ni wọn n wa fun ọdun mẹrin bayii.
Bẹẹ ba gbagbe, Jumoke George pẹlu omije loju ṣalaye pe, ọdun kẹrin ree ti ọmọ rẹ obinrin ti di awati, to si tun da ọmọ meji silẹ fun oun lati maa tọju wọn.
Biola Bayo tun se ṣafihan ọrọ to ba ọmọ Jumoke George, ẹni ti wọn pe ni Adeola sọ.
Ninu ọrọ Adeola pẹlu Biola Bayo, o ṣalaye pe orilẹede Mali ni oun wa bayii.
Biola wa rọ Adeola pe ko wa sile lati wa ri iya rẹ nitori pe on saaro rẹ, to si n jẹ ẹ lẹnu pupọ.
Ọdun mẹrin ni Jumoke George ko ti fi oju kan ni ọmọ rẹ, ti ọmọ ọhun si tun da awọn ọmọ to bi si abẹ iya naa.
Bayo ni Adeola ko ki n gbe ipe iya naa, eyi to fa ọpọ ironu fun agba oṣere naa.
Bakan naa, ijọ Cele naa kede iwadii nipa Adeola, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn kan si awọn eeyan ni Mali lati se awari Adeola.
Adeola si jẹ ko di mimọ pe, oun kuro ni ile lati wa igbaye gbadun aye oun lọ ni, to si ni oun ko ku, oun wa laaye.
Bayo sọ fun Adeola pe inu iya rẹ, to wa ni ile iwosan bayii, yoo dun pupọ lati ba a sọrọ.
Adeola fun Bayo lesi pe oun ko ni siimu ipe ninu foonu oun, ni oun ko fi ri aye pe iya oun fun igba pipẹ.
Adeola tẹsiwaju pe "Mi o dagbere fun ẹnikẹni pe ibi ti mo n lọ ree, mo kan ṣadede kuro ni ile ni.
"Ni ibi ti mo wa, ogun n waye laarin ikọ Boko Haram ati awọn Ologun, Ọlọrun gan lo yọ mi nitori wọn n pa awọn eeyan gan nibẹ.
"Mo wa ni kolobo nibi ti mo wa bayii."
Adeola tun tẹnubọ ọrọ pe, ko si bi oun ṣe fẹ waye pada wa si ile nitori oun ko ni iwe asẹ irinna.
"Lọwọ yii, n ko ni iwe asẹ ti maa fi rin lọna, koda ko si owo ti maa fi wa si ile bayii.
"Iya mi o ṣẹ mi, bẹẹ ni a ko si fi igba kankan ja ṣugbọn n ko lee ba iya mi sọrọ fun ọdun mẹrin nitori n ko ni nọmba wọn lọwọ."
"Ti mo ba ki n ma rin irinajo lai ni iwe irinna, o ṣeeṣe ki wọn gbe mi si ahamọ.
"Ọpọ ọmọ Naijiria lo wa ni ahamọ awọn agbofinro nibi bayii nitori wọn ko ni iwe irinna.
"Mo mọ iya mi, ti mo ba pe e, wọn yoo kan maa ṣunkun ni, mo kan fẹ yọ si wọn ati awọn ọmọ mi lojiji ni."
Adeola wa rọ Biola Bayo pe gbogbo agbara to ba le sa fun oun lati kuro orilẹede Mali ni ko sa, nitori ilu naa ti su oun gan an.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post

Oríṣun àwòrán, BIOLA BAYO/FACEBOOK/JUMOKE GEORGE/INSTAGRAM
Bi wọn ba n pe gbajumọ oṣere, ti wọn n ka awọn eeyan ti aye n foju wo pe ọkan wọn balẹ lagbo tiata Yoruba, Margaret Amoke Olatunde Olajumoke George jẹ ọkan ninu wọn.
Idi ni pe ọjọ iya naa ti pẹ gidi ninu tiata, awọ ọla han lara rẹ, bẹẹ ni aye ṣi n ri i wo ninu awọn ere agbelewo kiri.
Ọkan lara awọn eeyan to dantọ tawọn eeyan n gbadun rẹ ninu ere Yoruba ati ti ede oyinbo si tun ni pẹlu.
Iyalẹnu nla ati ibanujẹ ọkan lo wa jẹ fun ọpọ eeyan to ri Jumoke George lori ayelujara to n sunkun kikoro, to si n bẹbẹ pe ki awọn abiamọ ati gbogbo ọmọ Naijiria saanu oun.
Ki ló ṣẹlẹ̀ si Jumoke George?

Oríṣun àwòrán, Biola Bayo/Facebook
Ninu fidio kan ti Biola Bayo, oṣere tiata bii ti Jumoke George fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un ọdun 2025 yii, Jumoke wọ aṣọ Sutana, o si n sunkun kikoro pẹlu alaye pe:
"Ẹyin abiamọ ẹ gbadura fun mi, ẹyin abiamọ, ẹ fadura ran mi lọwọ, teeyan o bajẹ lọwọ mi ri o, ẹmi mi o gbe e mọ.
Ko sile ko si nnkankan, odidi ọmọ, mi o tun ri i, ko si alaafia. O ti su mi, ipa mi ti pin.
" Akọbi mi, Deola, mi o ri i, lati ọdun mẹrin sẹyin ni mo ti n wa a ti mi o ri i, o pe ẹni ọdun mọkanlelogoji lọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un yii, ọdọ mi naa lawọn ọmọ ẹ wa.
"Lati ọjọ keji oṣu Kin-in-ni ọdun yii ni ara temi naa ko ti ya. Mo ti gbiyanju gẹgẹ bi eniyan, gẹgẹ bii onigbagbọ.
"Gbogbo ayẹwo ni mo ti ṣe. Ayẹwo to tun ku ti mo fẹẹ ṣe bayii ni ti ọpọlọ ati ọkan, o le ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira (400,000) ti wọn pe e, nibo ni mo ti fẹẹ ri i.
"Mi o le sun, gbogbo ara maa n ni ọta mi ni, gbogbo nnkan lo n ṣe mi, ko ye mi mọ.''
Mama onitiata naa ṣalaye pe ẹnikan lo n ba oun yawo toun n na, gbese naa si ti wọ miliọnu meji naira.
O fi kun un pe oun ko tilẹ nile lori, o ni o ti n sun mọ ọdun mẹfa lọ bayii to jẹ pe ṣọọṣi loun n gbe, iya ṣọọṣi loun n foun lounjẹ lọpọ igba.
Níbo ló dé dúró?
Lati irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ti Biola Bayo ti ju fidio naa sita ni ọlọkan-o-jọkan ọrọ ti n jẹyọ lori ẹ.
Awọn eeyan n sọ pe ki lo n ṣẹlẹ lagbo tiata ti iṣoro bayii n kan wọn, ti ko si jọ pe wọn n dide iranlọwọ sira wọn.
Ninu alaye to ṣe nipa ọrọ Jumoke Geoge, Biola Bayo sọ pe oun ko le duro de ọjọ toun maa n gbe eto jade mọ nigba toun gbọ ohun to ṣe agba oṣere yii.
O ni kia loun dide toun wa a lọ sibi to wa, nibẹ loun si ti sare ṣe fidio to wa nita naa, nitori iranlọwọ kiakia ni iya naa nilo.
O rawọ ẹbẹ si gbogbo ẹlẹyinju aanu lati dide iranwọ fun Jumoke George, laipẹ rara.
Bakan naa ni Rotimi Salami toun naa jẹ onitiata, bẹbẹ lorukọ agba oṣere ti ọkan rẹ gbọgbẹ yii.
O ni gbogbo bo ba ṣe fẹẹ jẹ, awujọ tiata gbọdọ ran Jumoke George lọwọ.
Ta a ni Jumoke George?

Oríṣun àwòrán, Jumoke George/INSTAGRAM
Margaret Amoke Olatunde tawọn eeyan mọ si Jumoke George, lo wa nipo kẹta ninu ọmọ ti awọn obi rẹ bi.
Ṣọja ni baba rẹ, iya rẹ si jẹ olukọ.
Jumoke George lọ sileewe alakọọbẹrẹ Command Children School, Yaba, l'Ekoo ati Anglican Grammar School, Orita Mefa, Ibadan.
Bakan naa lo lọ sileewe ẹkọṣẹ ọwọ l'Osogbo.
Nipa ere ori itage, ọdun 2024 lo pe aadọta ọdun ti Jumoke George ti n ṣe ere tiata.
Iya naa ṣalaye ninu ifọwerọ kan, pe ileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba apapọ (NTA) ni wọn ti ṣawari oun.
O loun fẹran ere ori itage toun yoo maa ri awọn eeyan to n wo o, ju fiimu agbelewo lọ, nitori ori itage gan-an ni idan wa, ti oṣere yoo le fi ipa rẹ han gidi.
Jumoke George ṣalaye nigba naa pe asiko kan wa ti wọn ko pe oun si fiimu fun ọdun mẹrinla, nitori oun kọ lati ba awọn kan to fẹẹ ba oun sun ṣe.
O loun fẹran lati maa kopa iya, tabi iya-iya ninu ere, oun fẹran koun wọṣọ ti yoo foun ni alaafia, oun si korira ariwo.














