Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ s'áwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí JAMB ṣe l'óun yóò ṣe àtúnyẹ̀wò èsì ìdánwo 2025?

Oríṣun àwòrán, JAMB/FACEBOOK
Latari ifidirẹmi ọpọ akẹkọọ ninu idanwo igbaniwọle sile ẹkọ giga lorilẹede yii, ajọ Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB), ti kede pe oun yoo ṣe atunyẹwo esi idanwo ọdun 2025 yii.
Esi idanwo naa ti a mọ si 'Unified Tertiary Matriculation Examination' (UTME) ni wọn fi lede lọjọ Ẹti to kọja, ti awọn to kuna si pọ lọ jara.
Ikuna yii lo fa a ti awọn obi, akẹkọọ ati awọn tọrọ naa kan ṣe n fi aidunnu wọn han, ti wọn si n beere fun ayẹwo finni-finni lori esi idanwo yii.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ JAMB, Fabian Benjamin, buwọlu ni wọn ti sọ pe ayẹwo kikun nipa idanwo naa yoo waye.
"Bi a ba ṣewadii ti a si ri i pe ẹrọ wa lo yọnu, a maa gbe ilana atunṣe kalẹ kia, gẹgẹ bi a ṣe maa n ṣe ti a ba fẹẹ ṣe idanwo gan-an.
" A n yẹ gbogbo ẹsun ti a n gba lori esi idanwo yii lọwọ finni-finni, ka le ba a yanju kudiẹ-kudiẹ to ba ṣẹlẹ lati ara ẹrọ.
"Lati ran wa lọwọ lori igbesẹ yii, a ti gba awọn akọṣẹmọṣẹ, titi kan awọn ọmọ ẹgbẹ imọ ẹrọ kọmputa, awọn alayẹwo idanwo lati ita ti wọn jẹ olori ileewe giga ati bẹẹ bẹẹ lọ."
Bayii ni apa kan atẹjade naa wi.
JAMB fi kun un pe awọn aroye to n wa lati awọn ipinlẹ kan lorilẹede yii ko dun mọ oun ninu rara.
Èhónú àwọn èèyàn lórí ayélujára
Awọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn ti esi idanwo naa kan gbọngbọn, ti n bọ sori ayelujara lati fi ẹdun ọkan wọn han.
Ọpọ akẹkọọ lo ni esi idanwo tawọn gba kọja gan-an ko buru to ti 2025 yii.
Akọle kan ti i ṣe #thisisnotmyresult, ni awọn eeyan naa n lo lati fi aidunnu wọn han, ti wọn si n pe fun atunyẹwo esi idanwo yii.
Esi ti JAMB fi sita kede pe bii miliọnu kan aabọ akẹkọọ (1.5 million candidates), ni ko gba to maaki igba (200) ninu idanwo naa.
Itumọ eyi ni pe ida ọgọrin (80%) akẹkọọ ni ko gba maaki igba ninu irinwo (400).
Iṣẹ mẹrin ti maaki ọkọọkan jẹ ọgọrun-un (100) ni awọn akẹkọọ naa jokoo ṣe ninu UTME, apapọ rẹ lo jẹ irinwo (400).
JAMB ṣalaye pe akẹkọọ yoo kọkọ fi orukọ silẹ, yoo jokoo ṣedanwo, esi yoo si jade. Igbesẹ mẹta naa ko ju bẹẹ lọ.
Àwíjàre àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Ekeh Favour
BBC fi ọrọ wa diẹ ninu awọn akẹkọọ to n koro oju si esi idanwo naa lẹnu wo lati mọ ohun to ṣẹlẹ nibi idanwo gan-an.
Akẹkọọ kan, Ekeh Favour, ṣalaye pe awọn ibeere kan ko tilẹ han rara lori ẹrọ kọmputa toun fi ṣe idanwo.
O ni iṣoro aisi intanẹẹti koju awọn miran ninu idanwo yii pẹlu.
Favour ṣalaye pe igba kẹta ree toun n kọ JAMB, ibudo idanwo kan to wa ni Maitama, l'Abuja, lo ni oun ti ṣedanwo yii.
Akẹkọọbinrin naa tẹsiwaju pe awọn ibeere ko pe iye to yẹ ko pe, bẹẹ ni awọn kan wa ti ko tilẹ si ibeere nibẹ rara, idahun si wa nibẹ.
"Nigba ti idanwo yẹn bẹrẹ, mo ṣakiyesi pe awọn ibeere ede oyinbo ko han daadaa, awọn kan ko si tilẹ si nibẹ rara.
"Idi niyẹn ti mo fi pe awọn to n ṣọ wa ninu idanwo naa si akiyesi, ṣugbọn wọn sọ fun mi pe ki n fi i silẹ, ki n maa ṣe eyi to ba han lọ."
"Mo tun kiyesi pe 165 lo yẹ ki gbogbo ibeere jẹ, 145 lo wa nibẹ"
''Ibeere ede oyinbo ati Physics ko han''
Akẹkọọ miran, Anion Mmesoma, to ṣe idanwo tiẹ n'Ijegun, ipinlẹ Eko, sọ pe ibeere ede oyinbo ati Physics ko han rara.
O ni idaamu toun koju ree, ṣugbọn awọn alabojuto ninu yara idanwo naa sọ pe koun fi eyi ti ko ba han silẹ, koun maa ṣe eyi to han lọ.
Mmesoma sọ pe awọn alabojuto naa sọ fawọn pe lati JAMB ni iṣoro naa ti wa, ko kan awọn.
"Bi mo ṣe bẹrẹ si i kọ ohun to wu mi sibi awọn ibeere ti wọn o bi mi niyẹn."
Ǹjẹ́ báyìí ni èsì JAMB ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀?
Ninu idanwo UTME ti wọn ṣe ni ọdun 2022, JAMB kede pe akẹkọọ 378,639 gba maaki to ju igba lọ. Awọn akẹkọọ ogun-le- ni ẹẹdẹgbẹta (520) ni wọn gba 190 soke, nigba ti 704,991 gba 180 soke.
Ni 2024, akẹkọọ 1,904,189 lo ṣedanwo naa, 1,989,668 lo fi orukọ silẹ, eyi to fi ida 24.7% ju ti ọdun 2023 lọ.
Bi JAMB ṣe wi, ninu esi idanwo1,842,464 ti wọn fi sita, ida mẹrin pere lo gba maaki to ju 300 lọ, nigba ti ida mẹrinlelogun (24 percent) gba 200 ninu 400.
Ọdun 2019 ni wọn ti ri iru esi idanwo to buru bii eyi gbẹyin, nigba naa ni JAMB ati awọn ile ẹkọ giga si fẹnuko lati din maaki to kere ju ti akẹkọọ le gba ko too wọ ile ẹkọ giga si 160 (ọgọjọ).
Bakan naa, ni saa ẹkọ 2022/2023, ajọ JAMB gbe maaki yunifasiti si ogoje (140) soke, nitori wọn ni awọn akẹkọọ ko ṣe daadaa to lọdun naa.
Ni bayii ti ajọ JAMB ti pe fun atunyẹwo esi to buru yii, abajade rẹ ni awọn akẹkọọ, obi ati gbogbo ẹni tọrọ naa kan n reti.














