Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ‘ìrẹsì olóró’ tí wọ́n ló wọ ìpínlẹ̀ Ogun àti Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ere ni iroyin naa bẹrẹ si i tan kalẹ lori ayelujara, pe ki ẹnikẹni maṣe jẹ irẹsi lasiko yii, nitori raisi aṣekupani kan ti wọle si Naijiria, awọn to jẹ ẹ si ti ku.
Atẹjiṣẹ fọnran ohun ati ipe bẹrẹ si i kọlu ara wọn lori ayelujara lati kilọ nipa irẹsi oloro naa, wọn ni ounjẹ to gbajumọ naa ti pa awọn eeyan nipinlẹ Ogun ati Badagry ni Eko.
Gẹgẹ bi awọn to n pin ikilọ naa ka ṣe wi ninu awọn fọnran ohun wọn, oniṣowo kan ni wọn lo fi Ògún ṣepe nitori irẹsi rẹ ti wọn ji ko wọ Naijiria.
Wọn ni tirela apo irẹsi meji to jẹ ti oniṣowo ilẹ okeere naa lawọn kan ji, ti wọn si gba ọna ẹburu gbe e wọ Naijiria.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ẹnu ibode Idiroko ati Seme ni wọn gba gbe awọn irẹsi ọhun wọle.
Eyi ni wọn lo mu oniṣowo naa gba ilẹ Ghana lọ lati fi Ogun ṣepe fun awọn to ja a lole.
Wọn lo tun fi ẹni yoowu to ba fi owo rẹ ra irẹsi naa bu, o ni ki iku gbigbona maa pa gbogbo wọn.
Ṣe lóòótọ́ ni àwọn èèyàn tó tó àádọ́rin ti kú láìpẹ́ yìí torí wọ́n jẹ ìrẹsì?
Ọkan ninu awọn fọnran ohun to wa lori ayelujara, ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ aṣọbode kan ati ṣọja ti ku lori ọrọ yii ni Badagry, ipinlẹ Eko.
Bẹẹ ni fọnran kan sọ pe ko din ni aadọrin eeyan (70) ti wọn ti ku lẹnu asiko ti ọrọ irẹsi yii bẹrẹ.
Fọnran naa sọ pe nigba ti wọn jẹ irẹsi tan ni wọn di ero ọrun.
Bayii ni ibẹru ṣe n gbilẹ lori irẹsi, awọn ẹlomiran gan-an ko fẹẹ jẹ eyi ti wọn ni nile mọ.
Bo si tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan dide lati tako iroyin yii, paapaa awọn to n ta raisi, sibẹ, iroyin naa ko yee ran kiri bi ina inu ọyẹ.
Awọn to ni irẹsi n pa eeyan ko yee sọ bẹẹ, eyi ko si jẹ ki araalu mọ ohun to jẹ otitọ nidi ọrọ yii.
Ibẹru ọhun ti kọja ipinlẹ Eko ati Ogun nikan, o ti tàn de Ibadan ati awọn apa ibo mi-in lorilẹede yii.
Àlàyé iléeṣẹ́ Aṣọ́bodè Naijiria rèé lórí ìrẹsì olóró tí àwọn èèyàn kan ń pariwo pé ó ti wọ Nàíjíríà? Iléeṣẹ́ àṣọ́bodè fèsì
Ninu ọrọ ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa (Nigerian Customs Service), ẹka tipinlẹ Eko ati Ogun, wọn ni irọ pata ni iroyin naa.
Atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ aṣọbode, ẹka ti Seme, Isah Sulaiman; fi sita ṣalaye pe iroyin aṣinilọna, ofege ti ko si otitọ kankan nibẹ ni pe irẹsi n pa eeyan.
"Ileeṣẹ aṣọbode ilẹ Naijiria ti gbọ nipa iroyin ofege kan to ni ẹka wa gba irẹsi kan lọwọ ẹni to ni i, a si n pin i ka lai jẹ ki ẹni to ni ọja naa mọ nipa rẹ.
"Iroyin irọ naa tun sọ pe ẹni to ni ọja naa lọ ọ bẹ Ogun lọwẹ si i, awọn eeyan wa n ku, ṣọja kan tun ku ni Badagry.
"Ileeṣẹ aṣọbode n fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe irọ gbuu leyi, ẹtan ti ko ni otitọ kan ninu ni pẹlu"
Bakan naa ni ọga gba pata fun olu ileeṣẹ aṣọbode to wa ni Seme; Ben Oramalugo, sọ pe:
"Ko si iṣẹlẹ iru eyi kankan to ṣẹlẹ laaarin wa tabi lọdọ awọn oṣiṣẹ wa.
"O ba ni lọkan jẹ pe awọn kan ti wọn pe ara wọn ni akọroyin n gbe ohun ti ko ri bẹẹ jade.
Wọn si n ko ipaya ba awọn eeyan.''
O rọ araalu lati ma ṣe gba ahesọ gbọ bi iroyin tootọ, ki wọn ma si ba awọn opurọ pin ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.
"Iṣẹ wa gẹgẹ bi aṣọbode ni lati da aabo bo ẹnu ibode wa, ki ọja to le fa ijamba ma baa wọle wa. Ohun ti a si duro ṣinsin le lori naa niyẹn."
Bẹẹ ni ọga aṣọbode ẹka ẹnu ibode Seme naa wi.














