Wọ́n ti sin àgékù ara Hafsot Lawal tí afurasí Abdulrahman gé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ n'Ilorin

Bi igbẹjọ iku ọdọbirin Hasfot Yetunde Lawal ti awọn afurasi kan sekupa ni ilu Ilọrin ipinlẹ Kwara ti n lọ lọwọ, awọn ẹbi ọmọbinrin naa ti ṣin eyi to ku ninu ẹya ara rẹ ti wọn ri.
Ti ẹ o ba gbagbe, afurasi Abdurahman Bello ati awọn mẹrin mii, Ahmed Abdulwasiu, Suleiman Muyideen, Jamiu Uthman ati Abdurahman Jamiu, ni wọn n jẹjọ lori ẹsun pe wọn ṣeku pa Hafsot l'osu Kini ọdun 2025 yii, ti wọn si kun un wẹlẹwẹlẹ.
Nnkan bi aago mẹrin irọlẹ ọjọ isẹgun ni wọn ṣin oku oloogbe naa ni itẹ́ isinku awọn musulumi to wa ni agbegbe Sango niluu Ilọrin.
Lasiko to n sadura nibi eto isinku naa, Alfa Mujitaba Mamonsa, ni iku lopin irinajo ẹda laye.
O rọ awọn ọdọ lati yago fun iwa ọdaran, ki wọn si tun yago fun ọrọ̀ ojiji ti wọn n wa kiri.
Baba ọmọ naa, Ọgbẹni Lawal Adefalu, sọ pe wọn fi iku ọmọ oun da oun loro ni.
O wa kesi ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ naa lọwọ lati jẹ ki igbejọ ọhun ya kiakia.
Bakan naa ni Ọgbẹni Lawal tun pe fun idajọ ododo lori ọrọ naa.
Ileesẹ ọlọpaa sọ fun ile ẹjọ pe Abdurahman ti jẹwọ pe oun lo pa Hasfot, ti oun si ge oku rẹ wẹlẹwẹlẹ
Ẹwẹ, saaju ni Kọmisona feto idajọ ni ipinlẹ Kwara, Senior Ibrahim, lo ko awọn agbẹjọro ijọba ipinlẹ Kwara sodi wa si ile ẹjọ lọjọ Aje.
Lasiko igbẹjọ naa ni kọmisona ọhun rawọ ẹbẹ si adajọ lati fun awọn mọlẹbi oloogbe naa laye lati lọ sin awọn ẹya ọmọbinrin naa ti wọn ri.
Adajọ Christiana Ajayi ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara si fọwọsi i pe ki ẹbi oloogbe naa lọ ṣin oku rẹ.
Lati ile iwosan ẹkọṣẹ isegun UITH Ilọrin ni wọn ti gbe ẹya ara oloogbe naa to ku wa si ile ẹjọ.
Dokita Ọlaleke lo si jẹri niwaju ile ẹjọ pẹlu agbekalẹ abọ iwadii oku ọmọbinrin naa.
Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba ipinlẹ Kwara fẹsun ipaniyan ati ifipabanilopo kan Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin ti wọn jọ n jẹjọ.
Ẹwẹ, ajọ ọlọpaa ti fidiẹ múlẹ̀ ni ile ẹjọ pe Abdurahman ti jẹwọ pe oun loun pa Hasfot toun si ge oku rẹ wẹlẹwẹlẹ.
Ọjọru ọjọ kọkanlelogun osu yii ni igbẹjọ naa yoo tun tẹsiwaju.
Bí ìgbẹ́jọ́ Abdulrahman, afurasí tó pa Hafsot Lawal, ṣe lọ ní Ilorin lọ́jọ́ Ajé rèé

Igbẹjọ Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mi ti wọn fẹsun ipaniyan ati ifipabanilopo kan tẹsiwaju lọjọ Aje ọjọ kejila oṣu Karun-un yii ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ kwara ni ilu Ilọrin.
Igbẹjọ naa waye labẹ adajọ Christiana Ajayi.
Ọsẹ to kọja ni ile-ẹjọ da awọn afurasi naa pada si ihamọ ọgba ẹwọn Okekura ni ilu Ilọrin.
Nibi igbẹjọ naa to waye ni nnkan bi aago mẹsan an owurọ ni ẹlẹri akọkọ, Dokita Olaleke Olaleye lati ẹka to n sayewo oku ni ile iwosan UITH Ilọrin ti jẹri pe awọn ri iwe gba lọjọ kẹsan, oṣu Kẹrin ọdun 2025 lati yẹ ẹya ara oloogbe wo.
"Lẹyin ayẹwo naa, Insepctor Muhammad gba esi ayewo naa."
Lẹyin ti ile ẹjọ bi i lere pe ti o ba ri awọn ẹya ara to sayewo rẹ ṣe o da wọn mọ, Oseni ni bẹẹ ni.
Wọn si fi abajade ayẹwo naa le e lọwọ lati jẹ ri si, eyi ti adajọ gba wọle gẹgẹ bi ẹri.
Agbẹjọro olujẹjọ kinni tako akọsilẹ esi ayewo naa, sugbon adajọ ko gba ọrọ rẹ wọle.
Olujeri sọ pe ọwọ meji ati awọn ẹya ara to ku ni wọn se ayẹwo rẹ.
Awọn agbẹjọro olujẹjọ gba iwe ayẹwo naa, pe awọn yoo lọ fun akọsẹmosẹ lati ṣalaye rẹ daadaa fun awọn.
Ẹlẹrii keji lati ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ṣalaye fun ile-ẹjọ pe lọjọ kẹsan oṣu keji ọdun 2025 ni ọkunrin kan ti wọn pe ni Adefalu Lawal wa fi to awọn leti lagọ ọlọpaa ọja ọba niluu Ilọrin pe, oun n wa ọmọ oun Hasfot Lawal to jade ti kosi wọle pada mọ.
O fikun pe, awọn si tọpaṣẹ ẹrọ ibanisọrọ Hasfot de ọdọ Abdurahman nitori oun lo pe e gbẹyin lọjọ naa.
Lọjọ kẹrinla oṣu keji lọwọ tẹ ọkunrin kan ti wọn pe ni Abdurahman Bello lagbegbe isalẹ koto ni ilu Ilọrin.
Abdurahman Bello mu awọn ọlọpaa lọ ile rẹ lọjọ kẹẹdogun oṣu Keji.
O fikun pe oju ọna Ọffa Garage lawọn de ti Abdurahman Bello fi jẹwo fun awọn pe oun ti sekupa Hasfot Yetunde Lawal ṣugbọn ki ma se sọ fun ẹnikẹni, ti oun si ṣetan lati fun awọn ọlọpaa lowo riba.
O si tun jẹwo fun ọga olopaa DPO. Lẹyin naa ni wọn lọ si ile rẹ nibi ti wọn ri bata Yetunde ati ẹrọ ibanisọrọ meji.
"Nigba ti a wọ yara la ri ada to ni ẹjẹ lara, ọbẹ, rọba ti o rọ ẹjẹ si, ati ike ọda nibi ti ọwọ mejeji ti wọn da ogogoro si wa. O si jẹwọ pe oun pa a lati fi ṣe ogun owo ni."
Ọlọpaa ni Abdurahman yii kan naa lo mu awọn lọ agbegbe Oko-Olowo ni ibi ti o ju ẹya ara to ku si.
















