Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìlera Medipool tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù fún aráàlú

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/X
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti buwọlu eto ilera tuntun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Medipool.
Eto ilera Medipool yii ni gbọ pe o le mu adinku ba owo oogun rira atawọn nnkan mii ti eeyan le nilo fun itọju ara.
Eyii wa lara awọn igbesẹ ti igbimọ alaṣẹ ijọba Aarẹ Bola Tinubu fẹnu ko le lori nibi ipade wọn to waye niluu Abuja lọjọ Aje ọjọ kejila oṣu Karun-un yii.
Minisita eto ilera ni Naijiria, Ọjọgbọn Ali Pate, ṣalaye pe eto Medipool da lori agbarijọpọ ileeṣẹ to n ṣe kata-kara to si n ta oogun atawọn ohun elo itọju eeyan kaakiri orilẹede Naijiria.
Minisita eto ilera ṣalaye pe ijọba ṣagbekalẹ eto yii lati maa ra oogun ni kiṣi lowo ti ko gara si oniruuru ile iwosan ni Naijiria.
''Eto Medipool yoo jẹ kawọn ọmọ Naijiria jẹ anfaani oogun to peye to si dinwo''
''Pẹlu eto Medipool, ijọba yoo maa ṣeranwọ lati ra oogun ni kiṣi sawọn ile iwosan ijọba kaakiri orilẹede Naijiria.
Eto Medipool yii ni ṣe pẹlu agbarijọpọ ileeṣẹ to n ta oogun ni kiṣi, eyi yoo si fun ijọba lanfaani lati le yọwo rẹ daadaa ki a le ba a ri r ani ẹdinwo,'' Ọjọgbọn Pate ṣalaye.
Minisita fi kun un pe ko pin sibẹ, o tun kan ipese awọn nnkan elo, pinpin wọn sibi to yẹ, riri i daju pe ojulowo ni gbogbo agbekalẹ naa.
Iṣakoso owo to nilo, ipesẹ ilaniloye, riri i daju pe awọn ogun to yẹ wa nilẹ fun araalu niye ti ko gara pẹlu ajọṣepọ ijọba ati awọn aladani ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O tẹsiwaju pe ilana Medipool yii wa ni ibamu pẹlu ohun ti wọn n lo ni Kenya, South Africa, Singapore, ati Saudi Arabia.
Gẹgẹ bo ṣe wi, eto naa wa fun lati ran awọn ileeṣẹ kereje lọwọ, yoo si din bi a ṣe n gba oogun lati ilẹ okeere ku.
O ni yoo jẹ kawọn ọmọ Naijiria ni anfaani oogun to peye to si dinwo.
Igbimọ FEC tun kede N2.3 billion, fun rira ẹrọ kan to wa fun itọju aisan ọkan ni Yunifasiti ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo Usmanu Danfodiyo (UDUTH) to wa nipinlẹ Sokoto.
Eyi yoo ran ileewosan naa lọwọ lati ṣetọju awọn aisan to ba jẹ mọ ọkan.
"Ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo ipinlẹ Sokoto yii yoo le tọju isọro aisan ọkan nipinlẹ naa ati ẹkun Ariwa-Iwọ-Oorun orilẹede yii, ati gbogbo Naijiria lapapọ.
"Yoo gba ọpọ ẹmi la, yoo si tun din bawọn eeyan ṣe n lọ soke okun lati gba itọju ku, nitori awọn ọmọ Naijiria yoo ni anfaani lati ri itọju ti wọn ki i ti tẹlẹ gba,'' Minisita lo ṣalaye bẹẹ.















