"Ọgbẹ́ ọkàn ló jẹ́ pé Faith, ọmọ mi pa ara rẹ̀ tórí ó gba máàkì kékeré nínú èsì ìdánwò JAMB"

Faith Opesusi

Oríṣun àwòrán, Faith Opesusi/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Faith Timileyin Opesusi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

"Ọmọ mi gba maaki nla lọdun to kọja ninu idanwo Jamb, ni ọdun yii wọn fun ni maaki mẹrindinlaadọjọ, 146, ibanujẹ ọkan lo fa a, to fi gba ẹmi ara rẹ".

Eyi ni ọrọ Opesusi Oluwafemi, to jẹ Baba ọmọdebinrin to gba ẹmi ara rẹ lẹyin to wo esi idanwo Jamb to ṣe .

Faith Opesusi, ẹni ọdun mọkandinlogun lo ni erongba lati lọ ka imọ nipa Microbiology ni fasiti ṣugbọn awọn erongba yii ni ko le wa si imusẹ mọ lẹyin igbesẹ to gbe nigba to wo esi idanwo Jamb.

Oloogbe yii jẹ ọkan ninu ọpọ ọdọ to kopa ninu idanwo Jamb ti ọdun 2025.

JAMB si ti jade sita lati sọ pe otitọ ni pe awọn ṣe ọpọ aṣiṣe nipa esi idanwo naa eyi to fa ti ọpọ akẹkọọ se fidi rẹmi.

"Esi idanwo UTME ti ajọ JAMB gbe jade ni orukọ ọmọ oun, ki i ṣe esi idanwo ti ọmọ oun gba"

Opesusi, baba oloogbe ba BBC sọrọ pe esi idanwo UTME ti ajọ JAMB gbe jade ni orukọ ọmọ oun, ki i ṣe esi idanwo ti ọmọ oun gba.

"Awọn ọmọ ode isinyii ni wọn tete ma banujẹ, ọrọ naa ba ọmọ mi lọkan jẹ pupọ bi o ṣe ri esi idanwo naa" Baba sọrọ.

Gẹgẹ bii Baba naa ṣe sọ, o ni ka ni ọmọ naa sọ ẹdun ọkan rẹ sita ni, awọn yoo ti gbe igbesẹ lati bu omi tutu si lọkan.

Opesusi ni o dun oun pupọ pe ọmọ naa gba ẹmi ara rẹ.

Ẹgbọn Faith Opesusi salaye iru eeyan to jẹ nigba aye rẹ

Faith Opesusi

Oríṣun àwòrán, Faith Opesusi/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Faith Opesusi

Ẹgbọn oloogbe, Opeyemi Opesusi ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bii eeyan to fara siṣẹ, to si tun ni iwa irẹlẹ.

"Nigba to bẹrẹ si ni maa bi, mo bi i pe kin lo se e, to si sọ fun mi pe oun ti jẹ majele.

"Ile iwosan lo ti sọ fun mi, to si mi kanlẹ."

Ikorodu nipinlẹ Eko Faith n gbe pẹlu ẹgbọn rẹ, nigba ti iṣẹlẹ naa waye.

Ẹgbọn oloogbe ni Faith ri ile ẹkọ wọ ọdun to kọja ṣugbọn nitori pe ile ẹkọ naa jinna, ni ko se lọ si ile ẹkọ naa.

O ni o fẹ wa ni ile ẹkọ kan naa pẹlu awọn ẹgbọn rẹ lobinrin.

"A wa mẹjọ la wa ninu ẹbi wa ṣugbọn bayii a ti dinku si meje".

Wọn ti sin oku Faith si Ikorodu

Awọn mọlẹbi oloogbe ni awọn ti sin Faith si Ikorodu ṣugbọn inu ibanujẹ ọkan nla ni Baba, iya ati awọn mọlẹbi yoku wa lasiko yii.

Bo ti lẹ jẹ pe Ọga fun ajọ Jamb, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede ti tọrọ aforijin lọwọ awọn akẹkọọ ti ọrọ kan lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ fun aṣiṣe naa, to si tun ṣe ileri pe gbogbo ọna ni oun yoo fi ṣe atunṣe.

"Ohun to yẹ ko jẹ ohun idunnu ti yi pada nitori aṣiṣe kan tabi ikeji,"Oloyede sọrọ.

Akọwe ajọ kede pe o le akẹkọọ 379,997 ti yoo tun idanwo naa ṣe pada.

Eyi lo waye lẹyin ti ọpọ bu ẹnu atẹlu esi idanwo ti ajọ naa gbe jade lẹyin idanwo.