Ọdún Egúngún àgbáyé sọkutu wọ̀wọ̀ nílùú Ibadan, àlàyé rèé lórí ìsesí egúngún pàtàkì mẹ́wàá tó pitú

Aworan egungun niluu Ibadan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Akanṣe ọdun Egungun agbaye, ẹlẹẹkeji iruẹ ẹ waye l‘Ọjọbọ ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un yii ni papa iṣere 'Liberty Stadium' to n bẹ niluu Ibadan.

Jakejado orilẹede Naijiria ati ilẹ okere si ni ọpọlọpọ aṣoju awọn ile ti wọn ti n gbe Egungun ti peju pesẹ fun ajọyọ t'ọdun yii.

Kọmisana fun irinajo afẹ ati igbelarugẹ aṣa n'ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun ba akọroyin wa sọrọ nibi ipejọpọ naa.

Olatunbọsun ṣalaye wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe agbekalẹ ipejọpọ ọlọdọọdun yii fun awọn Egungun l'agbaye, ki aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba le di itẹwọgba kaakiri orilẹ aye.

"A fẹ ki UNESCO to n ri si agbega aṣa ati iṣẹlẹ manigbagbe l'agbaye tẹwọ gba ọdun Egungun"

Ọlatunbọsun ni awọn fẹ ki ajọ UNESCO to n ri si ọrọ ibudo aṣa ati iṣẹlẹ manigbagbe l'agbaye tẹwọ gba ọdun Egungun naa gẹẹ bi wọn ṣe fi ontẹ lu ọdun Ṣango ti wọn maa n ṣe lọdọọdun niluu Ọyọ.

Egungun mẹwaa ọtọọtọ, Ọba mẹwaa ọtọọtọ ati awọn aṣoju ijọba mẹwaa lo fi ara han nibi ọdun Egungun naa lati orilẹede Benin. Awọn Egungun lati ọkanojọkan idile ọjẹ lorilẹede Naijira naa ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.

Lara awọn ipinlẹ ti awọn Egungun naa ti wa niipinlẹ Ọyọ, Eko, Ogun, Ọṣun, Ekiti, Ẹkun Ila-oorun orilẹede Naijiria ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Aworan egungun n'Ibadan
Aworan egungun n'Ibadan
Aworan egungun n'Ibadan

Lara awọn alejo pataki to darapọ mọ ọdn Egungun naa ni igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayo Lawal, aṣoju Ooni Ifẹ ati Olubadan ilẹ Ibadan, Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, ti o tun jẹ agba Oye nilẹ Ibadan, Oloye Rashidi Ladọja, Baba Ẹlẹbuibọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọkanojọkan ẹgbẹ awujọ ti wọn wọ aṣọ alaranbara ko gbẹyin nibi ọdun Egungun naa.