Àtúnṣe ìdánwò JAMB dàpọ̀ mọ́ ti WAEC, àwọn òbí figbe ta lórí ìpòrúru ọ̀kàn fáwọn mọ wọn

Awọn obi ti ọmọ wọn yoo tun idanwo UTME ṣe gẹgẹ bi aṣẹ JAMB, ti ni ki ajọ naa sun atunse idanwo naa siwaju di oṣu Kẹfa ọdun 2025.
Oni, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un ọdun 2025 ni JAMB kede pe atunṣe idanwo naa yoo bẹrẹ, wọn si ti fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si awọn akẹkọọ ti atunse idanwo naa kan.
Ẹ o ranti pe ajọ naa kede atunṣe idanwo yii l'Ọjọruu ọsẹ yii, lasiko ti Ọjọgbọn Isaq Oloyede, to n dari JAMB tọrọ aforiji, fun ifidirẹmi ọpọ akẹkọọ ninu idanwo naa.
Ọjọgbọn Oloyede ṣalaye pe atunṣe UTME fun awọn to kan yoo bẹrẹ lonii ọjọ kẹrindinlogun, yoo si pari lọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun oṣu Karun-un ọdun 2025.
Lasiko yii, idanwo oniwe mẹwaa; WAEC n lọ lọwọ.
Eyi lo fa a ti awọn akẹkọọ to fẹẹ tun JAMB ṣe yoo ṣe tun ni lati maa kawe ọna meji.
Wọn yoo ni lati wa bi wọn yoo ṣe de ibudo idanwo JAMB pẹlu, bo ti wu ko ma ba ibi ti WAEC ti n waye mu to.
Ohun to mu awọn obi awọn ọmọ naa pe fun isunsiwaju atunṣe idanwo naa ree.
Wọn ni JAMB ko le maa ko idaamu ba awọn ọmọ ti ko mọ nnkan kan, nipa odo ti ajọ naa fun wọn lakọọkọ.

Ẹhónú àwọn òbí
Ọpọ obi lo ti n fi ẹhonu wọn han lori asiko perete ti JAMB la kalẹ fun atunṣe idanwo naa .
Akanbi Azeez, ọkan lara awọn obi naa,sọ pe WAEC to papọ mọ atunṣe JAMB yii ti ko idaamu ba ọmọ oun.
O ni ọmọ naa ti ṣe UTME l'Ekoo, o si ti pada s'Ilorin to ti n ṣe WAEC lọ.
Akanbi sọ pe bi yoo sẹ tun sare pada s'Ekoo laaarin ọsẹ kan naa ko le rọrun rara.
O ni o tun ṣee ṣe ki ọmọ naa ni iṣẹ ti yoo ṣe ninu idanwo oniwe mẹwaa lasiko ti JAMB n pe e l'Ekoo yii.
Ewu ọna, ijinigbe ati idigunjale to kun awọn oju ọna tun pẹlu awijare baba naa.
Bakan naa ni obinrin kan, Ijeoma James, fi aidunnu rẹ han si JAMB lori atunṣe yii.
O ni ajọ naa ni ki ọmọ oun waa tun idanwo ṣe l'Owerri, ọmọ to ti pada s'Ekoo, bawo ni yoo ṣe rọrun laarin asiko perete yii.
Yatọ si awọn obi, awọn akẹkọọ naa fi aidunnu wọn han.
Loju opo X, akẹkọọ kan n bẹ ajọ JAMB lati jẹ koun tun idanwo naa ṣe l'Ekoo.
Ọmọdebinrin naa sọ pe aago mẹsan-an owurọ ni JAMB fi idanwo si l'Enugu ti wọn ti ni koun tun idawno ṣe, bẹẹ Eko loun wa.
O ni ko rọrun lati bọ sọna laaarin asiko ti atẹjiṣẹ naa wọle lọ si Enugu.
Eyi ati awọn mii bẹẹ lo fa a ti wọn fi ni ki JAMB fi awọn akẹkọọ naa lara balẹ titi di oṣu Kẹfa lati tun idanwo wọn ṣe.
''Ẹ fọwọ sowọpọ pẹlu JAMB, ki atunṣe idanwo naa waye lọwọ kan''
Bi ọrọ yii ṣe n ja ran-in lọwọ, Ẹgbẹ ipade obi ati awọn olukọ ni Naijiria, 'National Parent Teacher Association of Nigeria', (PTA) ti rọ awọn obi lati sowọpọ pẹlu JAMB.
Aarẹ apapọ PTA, Haruna Danjuma, rọ awọn obi lati jẹ ki atunṣe naa waye lọwọ kan, fun aṣeyọri.
Ninu ifọrọwerọ kan ti Haruna ṣe pẹlu iwe iroyin Punch l'Abuja lo ti ni ohun to ṣẹlẹ yii ko dun mọ ẹnikẹni.
O ni ṣugbọn ohun to ṣe pataki ni pe JAMB gba aṣiṣe rẹ, o si ṣetan lati ṣe atunṣe.
Ki awọn obi fọwọ wọnu, ki wọn si jẹ kawọn ọmọ naa lọọ ṣe atunṣe idanwo.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú pín sí méjì lórí ọ̀rọ̀ yìí
L'Ọjọbọ, ile igbimọ aṣoju jokoo lori aṣiṣe JAMB lori idanwo naa
Aṣofin Adewale Adebayo lati ipinlẹ Osun, sọ fun ile naa pe ọpọ ọmọ Naijiria ni esi idanwo naa ko idaamu ọkan ba
O ni ijamba ti ko si jọ ara wọn ni awọn akẹkọọ maa n ba pade loju ọna nigba ti wọn ba n rin irinajo, o si yẹ ki ile boju to o.
Ninu ọrọ tirẹ, aṣoju Jibia/Kaita nipinlẹ Katsina, Sada Soli, rọ ile igbimọ lati gboriyin fun ọga agba JAMB to gba pe oun ṣe aṣiṣe to si tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria.
O ni JAMB ti fi apẹrẹ ọmọluabi han, o si ti pawo wọle funjọba apapọ daadaa lati igba to ti bẹrẹ .
Abẹnugan ile naa, Tajudeen Abbas, sọ pe igbimọ to n wadii iṣẹlẹ yii ni yoo pinnu boya oriyin lo yẹ ọga JAMB tabi bẹẹ kọ.














