Oyo: Ilé ẹjọ́ tó ga jù dá Seyi Makinde láre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ

Akinlade ati Abiodun

Oríṣun àwòrán, Akinlade/Abiodun/twitter

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti kede pe ki Abiodun APC tesiwaju ni ipinlẹ Ogun

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria joko lori ẹjọ kotẹmilọrun ti oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ogun latinu ẹgbẹ oṣelu Allied People's Movement, APM, Abdulkabir Adekunle Akinlade pe tako alatako rẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Dapo Abiodun.

Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu APM lo pe ẹjọ n kotẹmilọrun tako Dapo Abiodun to jawe olubori ninu idibo sipo gomina loṣu Kẹta ọdun yii.

Akinlade ati ẹgbẹ rẹ, APM, n fẹ ki ile ẹjọ fagile idajọ igbimọ to gbọ ẹsun to ṣuyọ lori idibo naa, ati ti ile ẹjọ kotẹmilọrun, to fi idi rẹ mulẹ pe Dapọ Abiọdun lo wọle.

Kini o n ṣẹlẹ lori igbẹjọ eto idibo ipinlẹ Ọyọ?

Ilé ẹjọ́ tó ga jù dá Seyi Makinde láre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹ-ede Naijiria ti fi idi iyansipo Seyi Makinde, gẹgẹ bi pe Gomina ipinlẹ Ọyọ mulẹÌjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC leè fi àṣẹ iléẹjọ́ lé dànù - Seyi Makinde

Eyi waye lẹyin ti oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu ÀPC, Adebayo Adelabu pe ẹjọ nile ẹjọ naa pe, ki wọn o fagile idajọ igbimọ to gbọ ẹsun to ṣuyọ lori eto idibo gomina, ati idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Awọn mejeeji lo dajọ pe Makinde ni gomina to wọle nipinlẹ ỌyọAjimọbi kí Seyi Makinde kú oríire .

Seyi Makinde lori ẹṣin

Oríṣun àwòrán, @pdpoyostate

Awọn miran ti ile ẹjọ giga julọ tun ni ki wọn tẹsiwaju ninu iṣẹ ilu ti wọn n ṣe ni ipinlẹ wọn ni:

Gomina El Rufai ti ipinlẹ Kaduna, Gomina Masari ti ipinlẹ Katsina ati Gomina Sanwo Olu ti ipinlẹ Eko ati Gomina ipinlẹ Nasarawa.

Àkọlé fídíò, Sola allyson, olori Ẹmi ni aala gbọdọ wa lori ohun ti awọn ololufẹ̀ olorin lee ṣe si wọn.