Budget 2020: Wo àwọn kókó tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ nípa àbá ìṣúná 2020 tí Buhari buwọ́lu

Ami idanimọ ile aṣofin Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile aṣofin Naijiria ti sọ pe ko si nkan to buru lati naa biliọnu mẹtadinlogoji ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi ọwọ si pe ki wọn o fi tun ile aṣofin ṣe.

Agbẹnusọ fun ile asọfin, Rawlings Agada sọ fun BBC Pidgin pe, wọn ko tun ile naa ṣe lati ogun ọdun ti wọn ti kọ ọ. O fi kun un pe àjà ile naa ti n jo, ti ko si jẹ ki o ṣeeṣe fun awọn eniyan lati maa duro nibẹ.

"O ko le sọ pe nitori pe ko fi bẹ ẹsi owó, ko fi ile rẹ silẹ ko wo."

BBC fi ọrọ wa a l'ẹnu wo nitori iha ti awọn eniyan kọ si ikede naa, pe owo ti wsn fẹ ẹ na ti pọ ju.

Kókó maarun ti ile aṣofin sọ

  • Ile naa ti n jò lati oke.
  • Gbogbo inu ile naa lo n rùn, nitori pe awọn ọpa omi ti fọ.
  • Koda, wọn ko ti i pari kikọ ile naa - awọn bi yaara ikawe, ile ounjẹ ati awọn ibi pataki miran.
  • Awọn abal kan lara awọn ile naa ti jẹra.
  • Ko si itura ninu ile naa fun awọn to ṣiṣẹ nibẹ.

Buhari buwọ́lu àbá ìṣúná 2020, kí ni àwọn kókó tó wà nínú rẹ̀?

Ni ọjọ Iṣẹgun ni Aarẹ Muhammadu Buhari buwọlu abadofin eto iṣuna orilẹede Naijiria funọdun 2020.

Aarẹ Buhari n kawe

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán, Wo àwọn kókó tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ nípa àbá ìṣúná 2020 tí Buhari buwọ́lu

Ni oṣu Kẹwaa ni Aarẹ Buhari gbe aba iṣuna naa to jẹ oni tiriliọnu mẹwaa ati ọọdunrun miliọnu o le diẹ naira, N10.33trn ka iwaju apapọ ijọko ile aṣofin apapọ.

O ṣe eyi lẹyin ti ẹka ile aṣofin mejeeji si joko jiroro lee lori ki wọn to fi abajade aba iṣuna oni tiriliọnu mẹwaa o le ẹẹdẹgbẹta miliọnu ati diẹ N10.59trn ranṣẹ pada si ọdọ aarẹ lẹyin ti wọn buwọlu ni ọjọ karun un, oṣu kejila, ọdun 2019.

Nibayii ti aarẹ ti buwọlu abadofin iṣuna naa, eyi ni awọn ohun marun un to tan bi itanṣan nipa abadofin naa.

Owo iyasọtọ fun atunṣe ilegbimọ aṣofin apapọ

Aworan lori diẹ lara agbekalẹ iṣuna ọdun 2020

Oríṣun àwòrán, Budgit

Àkọlé àwòrán, Wo àwọn kókó tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ nípa àbá ìṣúná 2020 tí Buhari buwọ́lu

Lati igba ti Aarẹ ti buwọlu abadofin yii, ohun kan pataki ti awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria nile ati loke okun ko yee pariwo le lori ni biliọnu mẹtadinlogoji naira, N37bn ti awọn aṣofin apapọ ya sọtọ fun atunṣe ileegbimọ asofin apapọ.

Ohun ti ọpọ n sọ ni pe iye owo naa ti pọju niwọn igba ti kii ṣe pe wọn fẹ tun ileegbimọ naa kọ.

Koda, ọpọ lo fi n ṣe akawe pẹlu bilisnu mejidinlogun naira, N48bn ti wọn ya sọtọ fun ipese awọn ohun elo to tọ lẹka eto Ẹkọ.

Aarẹ n buwọlu iṣuna ọdun 2020 niwaju awọn adari ẹka iṣejọba gbogbo lorilẹede NAijiria

Oríṣun àwòrán, @NigeriaGov

Afikun igba o le ọgọta ati mẹta biliọnu naira, N263.946

Aba iṣuna oni tiriliọnu mẹwaa o le ẹẹdẹgbẹta miliọnu ati diẹ N10.59trn ni aarẹ gbe ka iwaju awọn aṣofin apapọ, ṣugbọn aba iṣuna oni tiriliọnu mẹwaa o le ẹẹdẹgbẹta miliọnu ati diẹ N10.59trn.

Afikun igba o le ọgọta ati mẹta biliọnu naira, N263.946 lo gun owo naa. Ki ni awọn nnkan ti awọn aṣofin bu owo le lori?

Àkọlé fídíò, Sola allyson, olori Ẹmi ni aala gbọdọ wa lori ohun ti awọn ololufẹ̀ olorin lee ṣe si wọn.

Owoona atigbadegba ti ko si fun sisan gbese Recurrent (Non-Debt expenditure) gba afikun to to irinwo miliọnu naira lati tiriliọnu mẹrin naira o le ẹgbẹrin miliọnu naira si tiriliọnu mẹrin o le ẹgbẹrin miliọnu ati irinwo miliọnu naira.

Owoona fun gbese sisan, (Debt servicing) gba afikun lati tiriliọnu meji o le irinwo biliọnu ati ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira, N2.45trn si tiriliọnu meji o le ẹẹdẹgbẹrin biliọnu ati igba miliọnu naira, N2.72trn.

Àkọlé fídíò, Ondo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

Owoona fun ipese ohun elo amayedẹrun (Capital expenditure) naa gba afikun lati tiriliọnu meji o le ọgọrun biliọnu ati irinwo miliọnu naira, N2.14trn si tiriliọnu meji o le irinwo biliọnu ati ẹgbẹta miliọnu naira, N2.46trn.

Owoona fun gbese sisan pọ ju owoona fun ipese oun elo amayedẹrun

Ọpọ igba ti ọrọ gbese ba ti yọ ninu iṣuna Naijiria ni ariyanjiyan maa n waye ṣugbọn lọdun yii ohun ti awọn eeyan n jẹ lẹnu ni pe ṣe o yẹ ki ijọba apapọ tun maa gbimọran ati ya owo to to biliọnu mejidinlọgbọn Dọla owo ilẹ Amẹrika nigba ti iye to fẹ fi san lara gbese ti orilẹ-ede yii jẹ lọwọ gan an fun ọdun 2020 ti n pọju owo to ya sọtọ fun idagbasoke ilu lọ.

Àkọlé fídíò, Mike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Ninu iṣuna ọdun 2020, tiriliọnu meji o le ẹẹdẹgbẹrin biliọnu ati igba miliọnu naira, N2.72trn lo wa fun owoona sisan gbese ati Owoona fun ipese ohun eelo amayedẹrun (Capital expenditure) si jẹ tiriliọnu meji o le irinwo biliọnu ati ẹgbẹta miliọnu naira, N2.46trn.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'