Naira Marley ní àwọn tí kò fẹ́ kí òun di ààrẹ lẹ́yìn Buhari ló ń parọ́ ọkọ̀ jíjí mọ́ òun

Oríṣun àwòrán, NAira Marley/Instagram
Gbajugbaja olorin takasufe to n na igboro lọwọ, Azeez Adeyẹmi Fashọla ti ọpọ mọ si, Naira marley, ti ni bi o ti wu ki awọn alatako oun o ba oun lorukọ jẹ to, oun ni yoo jẹ aarẹ orilẹ-ede Naijiria lẹyin ti Buhari ba lo saa rẹ tan.
Naira Marley sọ eyi nigba to n fesi lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o ji mọto gbe gẹgẹ bi o ṣe n ja ranyinranyin kaakiri.
Ile ẹjọ Magistrate ipinlẹ Eko kan lo paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọ fi gbaga ofin gbe Naira Marley wa siwaju ile ẹjọ fun ẹsun jiji ọkọ.
Adajọ Majisreeti Tajudeen Elias lo gbe aṣẹ yii kalẹ fun ọlọpaa to n ṣe iwadii ẹjọ naa, Sajẹnti Sunday Idoko.,
O ni pe ni wiwọ ni dide o, oun fẹ ri Naira Marley nile ẹjọ nigba ti igbẹjọ miran baa waye.
Amọṣa, Naira Marley funra rẹ ti sọ pe ko si oun to jọọ o.

Oríṣun àwòrán, NAira marley/ instagram
Ninu ọrọ to fi soju opo twitter rẹ @officialnairam1, Naira Marley ni ki nla, ọwọn epo ni tabi airowo ra a.
O ni boya ki oun ṣe afihan fọto awọn ọkọ olowo iyebiye bii Bentley, Porsche tabi Benzo ranṣẹ ki wọn lee mọ pe ti ọrs ba di ti ọkọ oun ksja ẹni ti wọn lee ma fi ẹsun ọkọ jiji lọ.
O ni ko si ẹni to lee ba oun lorukọ jẹ ti oun ko fi ni di aarẹ to kan lorilẹede Naijiria.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Naira Marley ṣi n kawọ pọnyin jẹjọ niwaju ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Eko lori ẹsun jibiti ori ayelujara ati ayederu ike iṣuna ti ajọ EFCC n fi kan an.














