Naira Marley gba àṣẹ onídúró nílé ẹjọ́ pẹ̀lú mílíọ́nù méjì náírà

Oríṣun àwòrán, Efcc
Ile ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ si Ikoyi nilu Eko ti da akọrin taka-sufe ni Naira Marley ti wọn fi ẹsun jibiti ori ayelujara kan laipẹ yii silẹ.
Nibi igbẹjọ to waye ni ọjọbọ, onidajọ Nicholas Oweibo to gbọ ẹjọ ati gba oniduro rẹ gba ki wọn gba oniduro akọrin naa pẹlu milliọnu meji naira ati oniduroi meji.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Onidajọ Oweibo gbe idajs yii kalẹ lẹyin to gbọ awijare awọn agbẹjọro rẹ ati ti ajọ EFCC to n pe e lẹjọ.
Bi o tilẹ jẹ pe agbẹjọro fun ajọ EFCC, Rotimi Oyedepo rọ ile ẹjọ lati gbọ ẹjọ ti wọn fi kan an ni wara-n-ṣeṣa, agbẹjọro fun Naira Marley ni akọrin naa lẹtọ si beeli labẹ abala ofin orilẹede Naijiria.
Onidajọ Oweibo wa sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, ọjọ kẹtalelogun ati kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2019.
Agbẹjọro fun olupẹjọ ni niwọn igba ti agbẹjọro rẹ ti fi idi rẹ mulẹ pe ilumọọka ni Naira Marley, iwa ati iṣe rẹ yoo jẹ awokọṣe fun ọpọ awọn ọdọ lorilẹ-ede Naijiria eyii to lee ni ipa ti ko kere laarin wọn.











