Oluwo Divorce: Yàtọ̀ sí Olúwó, wo àwọn Ọba alayé tó ti kọ ìyàwó láìpẹ́

Ooni Ogunwusi pẹlu Olori ana, Wuraola Otiti

Oríṣun àwòrán, oonirisa - ooni of ife adeyeye enitan ogunwusi oja

Àkọlé àwòrán, Yàtọ̀ sí Olúwó, wo àwọn Ọba alayé tó ti kọ ìyàwó láìpẹ́

Ni ọjọ Aiku ni iroyin kan to ba ọpọ lẹjafuu jade lati akata oluwo ti ilu iwo.

Ko fẹrẹ sii ọmọ Yoruba nile loko ti ko tii gbọ ohun kan tabi omiran nipa Ọbalaye ilu Iwo, Alayeluwa Abdulrasheed Akanbi yala ni daadaa tabi idakeji rẹ iyẹn bo ba ṣe kọju si wọnỌ̀rọ̀ èmi àti Olorì Chanel Chin kò yé ara wa mọ́ nínú ilé- Oluwo .

Lootọ, ohun ti kii saaba waye ni ilẹ Yoruba ni ki Ọbalaye kọ iyawo rẹ silẹ Èèwọ! Ọba aláde o gbọdọ kọ iyàwó rẹ̀ sílẹ̀- Bakare, Iba àṣà Yorùbá.

Idi ni pe ọla ati iyi ti Yoruba so pọ mọ awọn Ọba kii ṣe kekere rara. Ọpọ tilẹ tun rii pe ko si ọkunrin miran to lee sàba le obinrin ti Kabiyesi ba ti gun ori rẹ kọja ni ilẹ Yoruba.

Amọṣa, Kabiyesi Oluwo kọ ni Ọba akọkọ ti yoo ni wahala pẹlu Iyawo rẹ.

Ọọni ile Ifẹ, Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja II

Ni ọdun 2015 ni Ọọni Adeyẹye Ogunwusi de ori oye,

Ko si si ẹni to ri i ni igba naa pẹlu ti kii kan sara si Eleduwa fun ẹwa ti Oba Oke fun un.

Àkọlé fídíò, Ọ̀rọ̀ Imam yìí ṣe kòńgẹ́ bó ti ń rí láàrin lọ́kọ láya

Ọpọ obinrin ni yoo si maa gbadura pé bí ele yii o tilẹ jọkọ ẹni ko jale ẹni.

Lẹyin o rẹyin, Wuraola Zaynab Otiti Obanor ni Ọọni Adeyẹye ja mọ lọwọ lọjọ naa lọhun loṣu kẹta, ọdun 2016 nigba ti awọn igbimọ Ọba Ile ifẹ gba ilu Benin lọ lati lọ tọrọ Wuraọla gẹgẹ bii olori tuntun fun Ọọni ile ifẹ.

Àkọlé fídíò, Iná PHCN tó dé lójijì ṣàkóbá ńlá ní Ibadan

Nnkan n dun fun awọn mejeeji ti ọpọlọpọ si n woye pe gbogbo nnkan bii ẹwa, iyi ati ẹyẹ ni awọn mejeeji fi yẹ ara wọn.

Ati pe ayọ lo ku ki o to di pe iroyin asọ nihin lọhun lagbo ile Kabiyesi naa to bẹrẹ sii jade sita faraye gbọn.

Ni oṣu kẹjọ, ọdun 2017 ni ipinya de laarin Kabiyesi Ọọni ati olori Wuraọla.

Oluwo ilu Iwo, Abdulrasheed Akanbi

Olori ana, Chanel Chin ati Oluwo ti ilu Iwo
Àkọlé àwòrán, Yàtọ̀ sí Olúwó, wo àwọn Ọba alayé tó ti kọ ìyàwó láìpẹ́

Iroyin ikọsilẹ iyawo rẹ, Chanel Chin jẹ eyi ti ọpọ awọn eeyan ko tilẹ lero rara paapaa bi a ba ni ka wo bi awọn mejeeji ṣe maa n ṣe ni gbangba.

Ọmọ ilẹ Jamaika ni Chanel Chin, Kabiyesi Oluwo kii sii fi ifẹ to ni sii pamọ nigbakugba ti awọn mejeeji ba wa ni gbangba .

Àkọlé fídíò, Oluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya

Eyii gan an lo jẹ ki iroyin ipinya wọn o jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan.

Oluwo ni aawọ ti ko ṣee yanju lo ṣokunfa ikọsilẹ wọn.

Olori ana, Chanel Chin ati Oluwo ti ilu Iwo
Àkọlé àwòrán, Amọṣa, Kabiyesi Oluwo kọ ni Ọba akọkọ ti yoo ni wahala pẹlu Iyawo rẹ.

Deji ana ni ilu Akurẹ, Oluwadare Adepọju

Deji ana, Oluwadare Adepoju ati olori tẹlẹ Ọmọbọlanle

Oríṣun àwòrán, OláShùpò Mábínúorí

Ọba Oluwadare Adepọju ni kabiyesi Deji ti ilu Akurẹ ti ijba ipinlẹ naa rọ loye lọdun 2010 lẹyin to ko awọn eeyan kan sodi lọ lu olori rẹ, Bọlanle Adesina to ko ẹru kuro nile lọ si ọdọ baba rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'

Bakan naa ni iroyin sọ ọ ni igba naa pe wọn tun da eroja abanilawọjẹ kan si Olori naa lara to n mu ki ara rẹ maa ṣi bi epo.

Koda, ọga ọlọpaa nigba naa, Ogbonna Onovo pẹlu tilẹ ṣeleri niwaju ile aṣofin apapọ pe Kabiyesi naa yoo jẹjọ.

Àkọlé fídíò, Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú