Abeokuta Leme ritual murder: Adájọ́ ní kí wọ́n fi Tọkọtayà tí wọ́n ka ẹ̀yà ara mọ́ lọ́wọ́ sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n ní Obafemi Owode

Adajọ ni ki wọn fi ololufẹ meji ti wọn ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ l'Abẹokuta pamọ s'ọgba ẹwọnỌwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
Saaju leyin ti ọwọ́ agbofinro ti tẹ́ awọn Tokotaya yii ni ọ̀rọ̀ naa ti se ọ̀pọ̀ ni kayeefi.
Onidajọ I. O. Abudu paṣẹ pe ki Kẹhinde Ọladimeji to jẹ́ ẹni ọdun mẹtalelogoji ati Adejumọkẹ Raji ti oun naa jẹ́ ẹni ọdun marundinlọgbọn lọ maa gbadun ara wọn ni atimọ́le to wa ni Obafemi Owode nipinle Ogun titi igbẹjọ miran yoo fi waye.
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Ẹ sọ́ra fún wíwá owó òjijì ẹ̀yin ọ̀dọ́, ìgbẹ̀yìn rẹ kìí dára- Alake Egba
- Ará àdúgbò dáná sun afurasí méji tí wọ́n bá orí èèyàn lọ́wọ́ wọn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní ọjà ọ̀dàn
- Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
- Wo àwòràn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Abeokuta lásìkò ikú Rofiat tí Soliu àti Mustaqim pa
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọkùnrin mẹ́rin tó fi olólùfẹ́ ọ̀kan lára wọn ṣe òògùn owó sí ẹ̀wọ̀n

Kini o sele nile ẹjọ́ bayii?
Adajọ ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Ogun to wa lagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokuta ti paṣẹ pe ki wọn fi ọkọ at'iyawo naa si ahamo.
Awon Tokotaya naa ni wọn ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ lagbegbe Lẹmẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun pamọ si ọgba ẹwọn to wa ni Ọba, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode.
Ki loun to ṣẹlẹ gan-an?
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii ni aṣiri Kẹhinde ati Adejumọkẹ tu sita pẹlu ẹya ara oku ni ojule kejilelaadọrin, opopona MKO Abiọla, Lẹmẹ.
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe awọ ara agbegbe Lẹmẹ yii ṣakiyesi ageku oku kan leti odo, ti wọn ko si mọ bo ṣe debẹ, eyi lo jẹ ki wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa agbegbe Kemta, Idi Aba, ti wọn si bẹrẹ iwadii lori ẹ.
Lẹyin ọsẹ meji la gbọ pe aṣiri awọn ọkọ at'iyawo yii tu pẹlu ẹya ara oku ti wọn gbe pamọ sinu ike omi nla ninu yara wọn. Lẹyin o rẹyin la gbọ pe Ifẹoluwa Adeh, ọmọ ọdun mejilelogun ni wọn tan lati pa danu.
Adajo Abudu sọ̀rọ̀ ilẹ́ kun lori idi ti ileejọ́ ko fi ni gba beeli wọ́n:
Adajọ ile-ẹjọ naa, Onidajọ I. O Abudu kọ lati gba ẹbẹ awọn t'ọkọ-t'iyawo naa.
O salaye idi ti ile ejo ko se ni fi oju aanu wo wọn.
Eyi lo fi so pe ki wọn lọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn to wa ni Obafemi Owode ni ipinle Ogun.
.Kini awọn agbejọ́rò sọ?
Ṣaaju asiko yii ni agbẹjọro fawọn ọlọpaa, Oluwatosin Jacson ṣalaye fun ile-ẹjọ pe ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii lawọn mejeeji ṣe ẹṣẹ naa.
O ni ṣe ni awọn mejeeji pawọpọ lati tan Ifẹoluwa Adeh, ẹni to jẹ ọrẹ timọtimọ si Adejumọkẹ wa sile wọn.
Agbehoro naa ni pe nigba ti wọn tan Ifẹoluwa de ile wọn, wọn dana fun, wọn si fi oogun orun sinu ounjẹ naa, lẹyin eyi ni wọn dumbu ẹ, ti wọn si ta ori rẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun babalawo kan niluu Ibadan.
Esun wo ni wọ́n fi kan Tokotaya naa bayii nile ẹjọ́?
Ẹsun ti wọn ka si awọn mejeeji yii lẹsẹ la gbọ pe o tako iwe ofin ọdaran t'ipinlẹ Ogun, t'ọdun 2006, aba;a 324 ati 319(1).
Onidajọ Abudu wa sun igbẹjọ miran si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun ti a wa yii.
- Kíni àjọ ECOWAS ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń sọ báyìí lórí ìjà Russia àti Ukraine?
- 416 àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine ló ti dé sílé báyìí-Abike Dabiri tó ń mójútó ọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè
- Sé Nàìjíríà le fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú bó ṣe ń kojú ìgbẹ́jọ́ àjọ NDLEA? – Àlàyé rèé
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Bàbá Adesola Adedeji, ọ̀kan lára àwọn afurasí méje ń fẹ́ rọ́pò ọmọ rẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke

















