Sunday Dare to Obasanjo: Sọ nkán tóo ṣé láti pèsè iṣẹ́ f'áwọn ọ̀dọ́ kó tó máa bẹnu àtẹ lu Buhari

Aworan Minisita Sunday Dare ati aarẹ tẹ Olusegun Obasanjo

Minisita feto ọdọ lorileede Naijiria, Sunday Dare ti sọrọ tako aarẹ tẹlẹ Olusegun Obasanjo lori ọrọ to sọ pe ewu nla lọrọ aipese iṣẹ fawọn ọdọ Naijiria.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria Punch lo ti lede ọrọ yi.

Dare ni Oloye Obasanjo ko yẹ lẹni tii naka alebu si ijọba to wa lode yii lori ipese iṣẹ fawọn ọdọ.

O sọ pe ka ni ijọba Obasanjo to ṣaaju ba ti koju ipenija yi ni, ko ba ma ri bi o ti ṣe ri loni.

''Kini aarẹ Obasanjo ṣe lọdun mẹjọ to wa lori oye lati fi koju aisiṣẹ fawọn ọdọ? Bo ba ṣe pe o gbe igbesẹ lasiko ijọba rẹ ni awa naa ko ba ri nkan tẹle'.

Sunday Dare ni ipenija airiṣẹ awọn ọdọ ko bẹrẹ ni ọdun mẹfa sẹyin labẹ iṣakoso ijọba Buhari.

O ni o ṣe pataki ki eeyan wo ipenija yi pẹlu ibi ti eto ọrọ aje lagbaye n lọ.

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

''Ki ajakalẹ Covid-19 to de ba gbogbo aye, ẹ ri bi awọn orileede Yuroopu ati Amẹrika naa ṣe n tiraka. Ipenija to ba gbogbo aye yii ko yọ Naijiria lẹsẹ silẹ''.

O ni akọsilẹ wa wi pe awọn eeyan n padanu iṣẹ wọn ti iṣẹ ohun iya si n peleke kaakiri.

Dare ṣalaye awọn orisirisi ọna ti ileeṣẹ rẹ ati ijọba lapapọ ṣe n ṣagbekalẹ eto lati koju airiṣẹ ọdọ ni Naijiria.

Igba akọkọ kọ niyi ti aarẹ Obasanjo yoo ma sọrọ lori airiṣẹ laarin ọpọ ọdọ Naijiria.

Bẹẹ si ni kii ṣe lasiko ijọba to wa lori oye yi nikan lo ti mẹnu ba ipenija yi.