Davido: Lọ́jọ́ ìbí bàbá mi ni aàrùn ọkàn ṣekúpa màmá mi lójijì

Oríṣun àwòrán, @davidoofficial/instagram
Ọjọ́ ìbí bàbá mi ni aàrùn ọkàn ṣekúpa màmá mi lójijì- Davido
Onikaluku abi tiẹ lara lọrọ ile aye yii lootọọ. Gbajugbaja olorin takasufe, Davido ti ṣiṣọ loju eegun ohun to ṣekupa pa mama rẹ.
Davido ni aarun ọkan to ma n mu eeyan lojiji lo sọ iya oun dero ọrun aremọbọ, ati pe lọjọ ibi baba oun gan an ni iṣẹlẹ manigbagbe yii ṣẹlẹ.
- Ilé ẹjọ́ gíga ní kí òsìsẹ́ First Bank tẹ́lẹ̀ lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 98 lórí ẹ̀sùn pé o jí mílíọnù 49 àti $368, 000 níbẹ̀
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
- Ọ̀pọ̀ aráàlú Owo wà nílé ìwòsàn, síbẹ̀ APC àti PDP kò gba ẹ̀bi
- Obabinrin Elizabeth kejì kí Nàìjíríà kú oríire òmìnira ọgọ́ta ọdún
Lori eto redio kan ni Davido ti ṣalaye ọrọ yìi.
O ni oun ko ju ọmọ ọdun mẹwaa lọ nigba ti mama oun dagbere f'aye pe o digbose.
Davido ṣalaye pe mama oun ko wa ni idubulẹ aisan ki ọlọjọ to de lai ro tẹlẹ.
"Ni gbogbo igba ni mo máa n sọ pe mo ri Chioma gẹgẹ bi mama mi, nitori ọmọde si ni mo wa nigba ti mo padanu iya mi," Davido lo sọ bẹẹ.
Davido ni to ba jẹ pe mama oun si wa laye ni, oun ko ba ti ra ile nla nla ati oríṣìíríṣìí okuta iyebiye "diamond" fun un.
"Mama mi ran ọpọlọpọ eeyan lọwọ, ẹsẹ Mama mi ni emi naa n tọ," Davido lo woye bẹẹ.
Davido sọ pe oun sun mọ mama oun gan an, nitori lọpọlọpọ igba ni baba oun máa n rinrin ajo kaakiri agbaye.
Eyi gan an lo jẹ ki iku mama mi ba mi lọkan jẹ pupọ nitori oun ni mo maa n ri ni gbogbo igba.
- Ẹ́ yé parọ́ mọ́ mi kiri, n kò múra ìgbéyàwó, ọ̀rẹ́ lásán ni Halima - Femi Fani-Kayode fọnmú
- Ìbò 900m làwọn èèyàn di lórí ètò BBNaija tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí - MultiChoice
- Ọ̀fẹ́ ni ohun eèlò àyẹ̀wò Covid-19 tí a ṣẹ̀sẹ̀ gbé jáde bá dé - NIMR
- Makinde gba àwọn òṣìṣẹ́ LAUTECH 41 tí ìjọba Ajimobi dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ padà















