Russia, Ukraine Crisis: Orílẹ̀ èdè Ukraine gbàlejò awon Aláṣẹ Amẹ́ríkà

Aarẹ Zelensky pẹlu olori ajọ orilẹede Yuroopu Ursulavon der Leyen

Oríṣun àwòrán, ukranian president press service

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Ukraine, Volodymyr Zelensky ti kéde wí pé akọ̀wé ìjọba Amẹ́ríkà, Antony Blinken àti akọ̀wé ètò ààbò Amẹ́ríkà, Lloyd Austin yóò ṣe àbẹ̀wò sí Kyiv.

Zelensky ní ìrètí wà pé àwọn àlejò náà yóò kó àwọn ohun ìdẹkùn dání fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà.

Ààrẹ Zelensky ṣàlàyé pé òun yóò ṣèpàdé pẹ̀lú wọn láti mọ ìrànlọ́wọ́ tí Amẹ́ríkà yóò ṣe fún àwọn lórí gbogbo ohun tí àwọn n béèrè láti kojú ogún Russia.

Bákan náà ló kéde pé kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn tó fi mọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn ọmọdé tí wọ́n ti kó lọ sí orílẹ̀ èdè Russia.

Bẹ́ẹ̀ náà ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìpàdé tó wáyé láàárín akọ̀wé àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, Antonio Guterres àti Ààrẹ orílẹ̀ èdè Russia Vladimir Putin lọ́jọ́ ìṣẹ́gun tó kọjá.

Ó ní ó yẹ kí Guterres kọ́kọ́ wá sí Ukraine láti rí bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ kó tó lọ sí Russia.