Àlàyé rèé lórí ohun tó fa aáwọ̀ láàrin èmi àti Dapo Abiodun - Amosun
Kii se nnkan asiri mọ pe ajọsepọ ti mẹhẹ laarin gomina ana nipinlẹ Ogun, Sẹnatọ Ibikunle Amosun ati gomina Dapo Abiodun.
Gomina Abiodun si lo gba akoso ipinlẹ Ogun lọwọ Amosun lẹyin ti onitọun lo ọdun mẹjọ nipo gomina, to si wọle di asofin agba nilu Abuja.
Ọpọ eeyan lo si fẹ mọ ohun to waye laarin awọn mejeeji ti ọfọn fi tọ si gbẹgiri, ti ẹlẹkọ si ko ẹkọ rẹ lọwọ.
Ẹla lọrọ, ti a ko ba laa, kii tete ye ni, eyi lo mu ki Sẹnatọ Ibikunle Amosun ba BBC Yoruba sọrọ nipa hulẹhulẹ ohun to fa aawọ naa ninu ifọrọwerọ kan.
Lọdun 2019, Kunle Akinlade lo wọle ibo gomina nipinlẹ Ogun, kii se Dapo Abiodun – Amosun
Nigba to n tọpasẹ ibẹrẹ aawọ wọn naa, Ibikunle Amosun ni oun ko le fẹ oju fun ẹni to n wa ipalara fun oun.
O ni lọdun 2019 ni aawọ naa ti bẹrẹ, to si jẹ pe wọn wa ipalara fun ẹmi oun amọ ti Ọlọrun ko fi le wọn lọwọ.
O ni oun ko se atilẹyin rara fun idije Dapo Abiodun nigba naa, ẹyin oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu ADM, Adekunle Akinlade si ni oun to si.
“Nigba naa, Akinlade lo wọle ibo gomina nipinlẹ Ogun, to si ye gbogbo awọn ti wọn dijọ sisẹ naa nipa ohun ti wọn se si esi ibo naa.
Amọ iyẹn ti lọ, lasiko yii, Biyi Otegbeye, tii se oludije fun ẹgbẹ oselu ADC ni emi atawọn alatilẹyin mi n tẹle.
Oun si ni maa sọ fun awọn eeyan ipinlẹ Ogun pe ki wọn ba mi tẹle, ti yoo si wọle.
Ni ti ipo aarẹ, Bola Tinubu ni awa yoo to lẹyin rẹ fẹgbẹ oselu APC ta wa amọ ni ti ipo gomina, n ko ni ba APC lọ, ADC ni mo n tẹle.”
“Amosun faake kọri lati fun igun wa nipo mẹtadinlogun ninu ipo bii ogoji to wa nilẹ”
Amosun ni kii se tori tara oun ni oun ko fi se atilẹyin fun gomina Dapo Abiodun, bikose nitori ọpọ awọn alatilẹyin oun, ti ko ri ọwọ mu ninu isejọba rẹ.
O ni ọpọ eeyan mii to sisẹ tẹlẹ fun ijọba APC nipinlẹ Ogun lo ti gba inu ẹgbẹ oselu miran lọ bayii, ko to pẹ ju fun wọn lati dije.
Lara wọn si lo lọ di igbakeji oludije gomina fun ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ogun bayii, Kunle Akinlade nigba ti wọn ko le se suuru bii ti oun.
O ni awọn eeyan naa lo se wahala fun agbekalẹ ijọba ọhun awọn ti wọn fi oju wọn gbolẹ gbẹyin.
Bakan naa lo fikun pe awọn alaga APC loke ati nisalẹ ti pe awọn pọ lati pari ija bii igba mẹjọ amọ ti ijoko naa n fi ori sọnpọn.
“Nibi gbogbo ipade ti wọn pe wa si lati ti sọ pe ki igun tiwọn fun igun tiwa ni ipo mẹtadinlogun ninu ipo bii ogoji to wa nilẹ amọ ti wọn fi aake kọri.






