Tí ń bà di gómìnà, ń kó ní máa sálọ Abuja láti gba owó fi ṣé ìjọba - Teslim Folarin
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ayé ìjọba Obafemi Awolowo ni àgbéga ti bá ìpínlẹ̀ Oyo kẹ́yìn - Folarin

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/officialTeslimkfolarin
Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, Oloye Teslim Folarin ti sọ awọn erongba rẹ ati awọn igbesẹ ti yoo gbe, ti wọn ba dibo yan gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo.
Folarin ni oun ko ni si ninu ẹgbẹ awọn gomina ti yoo ma lọ Abuja lati lọ gba owo oṣu fun ipinlẹ naa.
Sugbọn o ni oun yoo gbe ara le idagbasoke eto ọgbin, eyi to ni yoo ṣe afikun si ọrọ aje ipinlẹ naa.
Folarin sọ eleyi nigba to darapọ mọ ẹgbẹ awọn akọroyin ni ipinlẹ Oyo (NUJ) niluu Ibadan fun ajọdun ọlọdọọdun wọn.
O wa ṣe afikun pe igba kẹyin ti idagbasoke wa si ipinlẹ Oyo nigba aye iṣejọba Oloye Obafemi Awolowo, ẹni to mu ohun ọgbin ati eto ẹkọ lọkunkundun.
Folarin tẹsiwaju pe, ti ipinlẹ Oyo ba fẹ fi ẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu awọn ipinlẹ yoku, ijọba nilo lati pada lọ se agbelarugẹ eto ohun ọgbin ati atunṣe si eto ẹkọ.
“Ipinlẹ Oyo ni ọpọlọpọ ilẹ, ti pupọ awọn ilẹ wọnyi si wa nilẹ, a ni mu idagbasoke ba eto ọrọ aje wa layika awọn ilẹ wọnyi.
A ni lati bẹrẹ si ni wo ọjọ ọla waa.
“Igbakeji mi jẹ akọsẹmọsẹ nipa ohun ọgbin, ti a si jọ sisẹ papọ lati gbe ipinlẹ Oyo lọ si ibi giga .
Ẹyin eeyan Oyo, ẹ mase fi aye gba owo lati ṣe atọna yin - Folarin
Folarin wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati mase fi aye gba owo lati ṣe atọna wọn nigba ti wọn ba fẹ yan asoju ninu eto idibo gbogbo lọdun 2023.
O ni ipinlẹ Oyo nilo lati tẹsiwaju ninu sise dada, bakan naa ni awọn olugbe ipinlẹ Oyo ni lati wo awọn igbesẹ wọn wo finifini, ki wọn to dibo yan asoju wọn.
O wa ṣe ikilọ pe awọn ko ni fun wọn nigbe aye inira sugbọn ki wọn ṣe ara wọn ni osusu ọwọ, ki wọn si fi ọwọ sowọpọ.
O ni ti wọn ba se eyi, itẹsiwaju yoo de ba orilẹede Naijiria ati ipinlẹ Oyo.
“A nilo awọn olori to fẹran gbogbo ẹya, ti yoo si wa ojutu si gbogbo ipenija eto abo ti adojukọ, eyi ti yoo fun awọn eeyan ni anfani lati ma gbe igbe aye irọrun.
“Fun emi, ijọba to ba dara nilo olori to ni oye ati iriri to peye, ọgbọn ori lati gbe orilẹede yii lọ siwaju.
“Asiko ti to lati ri pe orilẹede Naijiria jẹ nkan ti a ni lati fi ọwọsowọpọ lati gbe de ibi giga ati lati bo ri gbogbo awọn isoro ipenija to dojukọwa.”

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/officialTeslimkfolarin















