N kò sọ pé ìwà ìkà ni bílẹ̀ òkèèrè ṣe ń fọ́mọ́ Nàíjíríà ní Físà – Amosun

Amosun

Oríṣun àwòrán, @saveursavage14

Gomina ana ni ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti ni oun ko sọ pe iwa ika lawọn ijọba ilẹ okeere n ṣe, bi wọn ṣe n fun awọn ọmọ Naijiria ni iwe irinna lọ silẹ wọn.

Ṣaaju ni Amosun ti kọkọ sọ erongba rẹ ninu ifọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba nipa bi awọn ọdọ ṣe n ‘japa’ lati fi orilẹ-ede Naijiria silẹ, ti ifọrọwerọ naa si milẹ titi.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Bola Adeyemi buwọlu, Amosun ni oun ko sọ pe eeyan bururu lawọn ijọba ilẹ okeere to n fun awọn ọmọ Naijiria ni fisa.

Amọ awọn akọroyin kan mọọmọ lo ọrọ naa lati tẹ ifẹ ara wọn lọrun ni ni.

Atẹjade naa ni “Awọn iwe iroyin kan sọ pe, Amosun ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, bu ẹnu atẹ lu awọn ijọba ilẹ okere ti wọn n ti awọn ọmọ Naijiria lẹyin lati sa kuro lorilẹ-ede wọn, pe ika ni wọn n ṣe.”

“Sẹnetọ naa, to n ṣoju aringbungbun ipinlẹ Ogun sọ pe ohun to n ba oun ninu jẹ ni awọn akọṣemọṣẹ ọlọpọlọ pipe bii dokita, agbẹjọro, amojuẹrọ ati oluṣiro to n kuro ni Naijiria pẹlu awọn ẹbi wọn.

O ni igbesẹ naa le ṣe ipalara nla fun Naijiria.”

“Bo tilẹ jẹ pe gomina ana ọhun sọ pe ko bojumu bi awọn orilẹ-ede naa ṣe n ti awọn araalu lẹyin lati fi Naijiria silẹ, ko sọ pe aburu ni wọn n ṣe.”

Amosun ṣalaye pe ọtọ ni ohun ti oun sọ amọ awọn akọroyin kan mọọmọ yi ọrọ naa pada nitori oun funra oun gan ti ran ọpọ eeyan lọ silẹ okeere.

Ki ni ohun pato ti Amosun sọ fun BBC Yoruba?

Ninu ifọrọwerọ naa Amosun sọ pe ko si ẹnikẹni to fi Najiria silẹ to le fi gbogbo mọlẹbi rẹ silẹ.

O ni “Ibi ti wọn n lọhun, ṣebi a ti lọ sibẹ.”

“Amọṣa awọn to n lọ yii, ẹẹ ri pe awọn orilẹ-ede to n fun wọn ni iwe pe ki wọn maa gbe ilu naa, emi wo pe bii ika paapaa ni wọn fi ṣe fun wa ni.”

“Nitori bi ẹ ṣe wo lonii n dokita gan ti fẹẹ lọ tan, agbẹjọro ti lọ, oluṣiro ti lọ... gbogbo wọn nisin, iṣẹ nọọsi ni wọn n lọ kọ.”

Amosun sọ pe ko rọrun ki eeyan fi ile rẹ silẹ lati lọ si ilu ẹlomiran lati lọ ṣowo, ati pe ko dara fun orilẹ-ede Naijiria nitori ọjọ ọla.

Aṣofin naa ni awọn mii ti wọn ba ti lọ kii fẹ pada si Naijiria mọ, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

O pari ọrọ rẹ pe ti ijọba Naijiria ba da awọn ileeṣẹ nla-nla silẹ amọ ti ọpọ awọn ọdọ to yẹ ṣiṣẹ nibẹ ti salọ tan, iṣoro nla ni yoo jẹ fun Naijiria.

Lẹyin naa lo gbadura pe naijiria ṣi maa dara.