Adeleke yóò gbà isẹ lọ́wọ́ 12,000 òṣìṣẹ́ tí Oyetola ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà - PDP

- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti kede pe oun yoo gba isẹ lọwọ awọn ẹgbẹrun mejila osisẹ tuntun ti Gomina Gboyega Oyetola gba sisẹ laipẹ yii.
Igbani sisẹ naa lo waye lẹyin eto idibo gomina to waye ninu osu keje.
Atẹjade ti Alaga afunsọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun, Dokita Akindele Adekunle, fi sita fawọn akọroyin lo sisọ loju ọrọ yii.
Gẹgẹ bi Adekunle ti wi, ni kete ti wọn ba ti bura fun gomina tuntun naa ni yoo wọgile igbesẹ Gomina Oyetola to fẹ kogba wọle ni ipinlẹ Osun naa.
“Igbesẹ ti ijọba to fẹ kogba wọle gunle ni ko boju mu, ti ijọba Sẹnetọ Ademola Adeleke yoo tun ṣe atunse sawọn ofin kan, ni kete ti wọn ba bura fun ni ọjọ kẹtadinlọgbọn ọsu kejila ọdun 2022.
“Awọn igbanisẹ to waye ni awọn ẹka ijọba bi ti awọn ile ẹkọ gbogbonise Iree ati Esa Oke, ati yiyan alamojuto fun awọn isẹ banki ni yoo ni atunṣe.
Gbógbó ìgbanisíṣẹ́ Oyetola ní kó ní ẹsẹ nílẹ̀ - Adekunle
Dokita Akindele Adekunle tẹsiwaju pe gbogbo igbiyan gomina Gboyega Oyetola lati fi awọn eeyan kan ti yoo ba iṣejọba Gomina tuntun Ademola Adeleke ni awọn mọ nipa, ti wọn si ni fi aye gba wọn.
“Gbogbo igbanisisẹ to waye laarin ọsẹ diẹ sẹyin ni ko ni ẹsẹ nilẹ, ti wọn si ri owo ijọba gba. A mọ pe pupọ awọn ti wọn sisẹ ni o jẹ ọmọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ii wọn gbe sipo lati ṣe akoba fun isẹjọba Adeleke
“Iṣejọba Adeleke yoo gbe iwe lọ gbe ile rẹ fun awọn osisẹ tuntun ti ijọba Adeleke fi ọna eburu gba sisẹ lati ninu
Iléẹjọ́ wọgilé ẹ̀bẹ̀ PDP lórí ètò ìdìbò abẹ́nú APC ní Osun
Wayi o, ileẹjọ giga to joko nipinlẹ Osun ti wọgile ẹbẹ ẹgbẹ oṣelu PDP to tako eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ni ipinlẹ naa.
PDP ni ilana ti ẹgbẹ APC gbe ni ko ba ilana ofin orilẹẹdẹ Naijiria mu, ti wọn si kọwe si ileẹjọ pe ki wọn wọgile eto idibo naa.
Ẹbẹ naa lo tun da lori bi ajọ CECPC, to ṣe agbatẹru eto idibo naa ko se ni agbara lati ṣe agbatẹru eto idibo labẹ ofin ẹgbẹ oṣelu APC.
Ajọ INEC nikan lo ni anfani lati ṣe agbatẹru eto idibo gbogbo ati eto idibo abẹnu lorilẹede Naijiria.
Nigba ti o kede idajọ rẹ, Adajọ Nathaniel Aayo Emmanuel, ti ileẹjọ giga ipinlẹ Osun ni ẹbẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni ẹsẹ nilẹ rara, to si bu ẹnu atẹlu ẹbẹ ọhun, ko to wọgile kuro ni ile ẹjọ.
Adajọ ni osuwọn ẹjọ ko kun to ati pe ẹgbẹ oṣelu PDP kuna lati fa awọn nkan ti wọn nilo fun igbẹjọ naa kale fun ile ẹjọ.
Bakan naa lo ni wọn si tun kọ lati gba esi iwadi lọwọ ajọ to n risi ọrọ eto idibo lorilẹede Naijiria(INEC) lori eto idibo abẹnu naa.
















