Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ fásitì, ẹ lọ fìdí mọ́lé torí ìbò tó ń bọ̀ - Ìjoͅba àpapòͅ

Oríṣun àwòrán, U.I
Ijoͅba apapoͅ lorileͅede Naijiria ti kede pe ki gbogbo fasiti w ani titi pa saaju eto idibo ti yoo waye lorileͅede Naijiria.
Ajoͅ to n risi oͅroͅ fasiti ni Naijiria, NUC lo kede asͅeͅ tuntun naa ninu ateͅjade ti woͅn fi lede.
Woͅn ni ki gbogbo awoͅn olori ileeͅkoͅ pasͅeͅ ki fasiti wa titi lati oͅjoͅ kejilelogun, osu keji titi di oͅjoͅ keͅrinla, osu keͅta , oͅdun 2023.
Ajoͅ NUC ni eyi yoo fun awoͅn akeͅkoͅoͅ laaye lati kopa ninu eto idibo sipo aareͅ to n boͅ loͅna.

Oríṣun àwòrán, NUC
Ajoͅ NUC ni minisita fun eto eͅkoͅ, Adamu Adamu lo pasͅeͅ naa.
‘’Gbogbo adari ileeͅkoͅ patapata ni a pasͅeͅ fun lati di ileeͅkoͅ woͅn saaju idibo sipo aareͅ ti yoo waye ni oͅjoͅ karundinloͅgboͅn, osu keji, oͅdun 2023 ati awoͅn idibo miran ti yoo waye ni osͅu keͅta bakan naa.’’
‘’Nitori eto aabo awoͅn olukoͅ, akeͅkoͅoͅ ai awoͅn osͅisͅeͅ fasiti ni a sͅe pasͅeͅ naa, ki wahala tabi rogbodiyan ma baa beͅ sileͅ.’’
‘’Bakan naa ni ijiroro waye peͅlu awoͅn eleto idibo, awoͅn eͅsͅoͅ alaabo, ti gbogbo woͅn si pa ohun poͅ si pe ki ileeͅkoͅ w ani titi laarin Oͅjoͅ Kejilelogun, osu Keji, oͅdun 2023 si oͅjoͅ keͅrinla, Osu keͅta, oͅdun 2023.’’















