Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ olùfẹ̀hónúhàn 30 lórí ìwọ́de tí wọ́n ti sọ iná sí báǹkì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaafia ti pada siluu Sagamu, nipinlẹ Ogun bayii lẹyin ifẹhonuhan to waye nibẹ lọjọ Aje, nibi ti awọn araalu ti sọ ina si awọn banki kan.
Yatọ si awọn banki atawọn ileeṣẹ ti wọn sọ ina si, awọn olufẹhonuhan ọhun tun ji dukia awọn araalu ko, ti wọn si tun sọ ina si awọn ọkọ kan.
Ẹwẹ, gẹgẹ bii ohun ti kọmiṣọna ọlopaa ipinlẹ ọhun, Frank Mba sọ, wọn ti fi ṣikun ofin mu ọgbọn eeyan ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu ifẹhonuhan naa.
Awọn araalu Sagamu sọ fun awọn akọroyin pe nnkan bii aago marun un abọ idaji ni ifẹhonuhan naa bẹrẹ, lasiko ti ọpọ araalu ṣi n sun lọwọ.
Awọn agbegbe ti iwọde naa ti milẹ julọ ni agbegbe Oba Erinwole, nibi ti awọn eeyan ti kọlu nnkan bii banki meje, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ.
Awọn janduku tun fọ ogiri banki kan lọna ati wọ inu yara ti wọn n ko owo si.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, inu awọn ile ifowopamọ ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn ti wọn mu.
Frank Mba ti wa kilọ fun awọn araalu lati ṣọra fun ifẹhonuhan to ni jagidijagan ninu.
Bo tilẹ jẹ alafia ti pada si ilu naa bayii, wọn ti fi awọn ọlọpaa ṣọwọ sanwọ agbegbe to ṣe koko niluu naa lati tete pana rogbodiyan mii to ba fẹ gberi.
Ki lo ti sẹlẹ ṣaaju?
Àwọn olùfẹ́hónúhàn sọ iná sí báǹkí mẹ́ta ní ìpínlẹ́ Ogun nítorí àìrí owó naira tuntun gbà

Oríṣun àwòrán, @LeadershipNGA
O kere tan, ile ifowopamọ mẹta lawọn eeyan ti sọ ina si nipinlẹ Ogun lasiko ifẹhonuhan aisi owo naira tuntun to waye nibẹ.
Ilu Shagamu, ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun, Abimbola Oyeyemi lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ile ifowopamọ Union Bank, First Bank ati Keystone Bank lawọn olufẹhonunan naa kọlu.

Oríṣun àwòrán, @LeadershipNGA
O fi kun pe awọn ọlọpaa to lọ sagbegbe naa lati pana rogbodiyan ọhun.
O ni “A ti wa niluu shagamu bayii, ina n jo nibẹ gidi.”
“Wọn ṣakọlu sile ifowopamọ Union Bank, First Bank ati Keystone... a wa nibẹ bayii.”
Yatọ si Shagamu yii, irufẹ iwọde bayii ti kọkọ bẹ silẹ lawọn ilu nla nla ni Naijiria latari iṣoro airi owo naira tuntun gba.
Bi awọn olufẹhonuhan naa ṣe n sọ ina si banki lawọn mii n kọlu ẹrọ ATM lati ko owo inu rẹ.
Ẹwẹ, lọjọbọ to kọja, ni Aarẹ Muhammadu Buhari fofin de owo ₦500 ati ₦1000 atijọ, nigba to ni awọn eeyan ṣi le maa na ₦200 atijọ titi di ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin ọdun yii.
Amọ, ko din ni awọn gomina ipinlẹ mẹwaa to ti pe Aarẹ lẹjọ lori ọrọ owo naira tuntun naa.
Bẹẹ si ni ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP, ti gbe Aarẹ Buhari ati CBN lọ sile ẹjọ lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn tapa si aṣẹ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria eyii to ni awọn araalu ṣi le maa na owo atijọ lọ titi ti oun yoo fi gbe idajọ kalẹ lori rẹ.












