Ọwọ́ tẹ Nọ́ọ̀sì ọmọ Nàìjíríà 20 tó ń fi ayédèrú ìwé ẹ̀rí ṣiṣẹ́ ní US, bàa ṣe rí wọn mú rèé - Ìjọba

Nọọsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àjọ to n ri si iṣẹ awọn nọọsi ni iluTexas ti ilẹ Amẹrika ti fi ẹsun kan nọọsi mẹtalelogun pe wọn lo ọna alumọkọrọyi fi gba iwe ẹri ẹ̀kọ́ wọn.

Gẹgẹ bi ọrọ ti àjọ naa fi sita, ifi ẹsun kan naa wa lati ọdọ ikọ alabojuto to n jẹ "Operation Nightingale".

Bakan naa ni wọn gbe orúkọ awọn afurasi ayederu nọọsi naa jade ti o kere tan mẹtadinlogun si wa lati orileede Naijiria.

Ikọ Operation Nightingale yii pawọ pọ pẹlu ẹ̀ka eleto ilera United States, ẹ̀ka to n ri si ọrọ ọmọniyan ati ọfiisi Ọga agba awọn Ọlọpaa.

Ni ọjọ Kẹ́ẹdọgbọ́n Oṣù Kínní Ọdún 2023 lati wa awọn eniyan ti wọn fẹ̀sùn kan pe wọn n ta ayederu iwe ẹri ikẹkọgboye imọ ẹ̀kọ́ nọọsi.

Wo boo ṣe lè di nọọsi ni Texas

- Ohun too nilo bi o ba fẹ di nọọsi ni Ìpínlẹ̀ Texas gẹgẹ bo ṣe wa ninu alakalẹ àjọ to n boju to iṣẹ́ àwọn noosi ni Texas ni pe ẹni to ba fẹ gba iwe ẹri lati maa ṣiṣẹ́ gẹgẹ bii nọọsi gbudọ kọ́kọ́ pari ẹ̀kọ́ noosi ni Fasiti ti ijọba fọwọ́ si.

- Ẹni naa yoo wa lọ gba afara jọ iwe ẹri nibi ti wọn n pe ni BON, yala ki ilé ẹ̀kọ́ wọn fi ránṣẹ́ tabi ki wọn tẹ ẹ jade ki adari ẹ̀ka kilaasi wọn lee bù ọwọ lù ú kí wọn to dáa pada.

-Ki wọn to ṣe idanwo ati gba iwe àṣẹ lati ṣiṣẹ́ eyi ti wọn n pe ni National Licensure Examination (NCLEX), wọn yóò kọ́kọ́ ṣe idanwo lori ayélujára eyi ti yoo fun wọn ni àṣẹ lati ṣe idanwo ti ojukoroju.

- Bí ẹni naa ba wa ni Amẹrika, àjọ to n boju to iṣẹ́ àwọn nọọsi nibẹ yoo bere fún:

Iwe lati ọwọ rẹ, owo ti waa san lati gba a, ayẹwo iwa ipa tabi idigunjale nipa rẹ, ìwé àṣeyege ninu idanwo lati di noosi ati afara jọ iwe ẹri lati fihan pe o kẹ́kọ̀ọ́ pari.

Laarin ọjọ isẹ marun ni ajo naa yoo fi gba iwe àṣeyege ti wọn yoo si fun ẹni naa ni iwe ẹri.

- Nọọsi naa yoo wa lanfani ati lọ si oju opo àjọ naa lori ayélujára lati tẹ iwe aridaju pe o ti gba iwe àṣẹ jade.

Fun awọn ara ilẹ̀ okere:

-Wọn yóò nilo fọ́ọ̀mù idanwo NCLEX

- Owo ti waa san

- Ìwé yiyege idanwo nipa iwa ipa ati idigunjale

- Iwe yiyege idanwo èdè Gẹ̀ẹ́sì TOEFL

-Awọn iwe ẹri eto ẹ̀kọ́ ati iṣẹ

- Aridaju ìwé àṣẹ iṣẹ nọọsi lati orílẹ̀èdè ti asedanwo naa ti gba a tẹ́lẹ̀.

-Ọdún mẹrin ni ẹni naa yoo fi ṣiṣẹ́ ko to le kọ iwe lati gba iwe àṣẹ ti Texas.